Ìrètí Tí Ìsìn Tòótọ́ Fúnni
ÌWÀ ẹ̀dá ni pé kí a fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó kàn wá tàbí tó ń mú inú wa dùn. Èyí jẹ́ ìdí kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ sí sísọ nípa ohun àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. Ìsọfúnni náà, tí ó jẹ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ní ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa àwọn ohun tó kan àwọn ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n lónìí, bí ọjọ́ ọ̀la, ààbò, ìlera, àti ayọ̀.—Lúùkù 4:43.
Àmọ́, lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ìrètí Amúniláyọ̀
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí Ọmọ rẹ̀, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” ń darí. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.”—Aísáyà 9:6, 7.
Lótìítọ́, ní wíwo ọjọ́ ọ̀la, àkókò wa àti àwọn tó ti ṣàkóso wa nínú ìtàn, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìjọba Ọlọ́run yìí, tí Kristi, Ọmọ Aládé Àlàáfíà, ń ṣàkóso rẹ̀ yóò mú àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbà ṣẹ, pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run . . . , kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Kí ni yóò túmọ̀ sí fún ilẹ̀ ayé àti fún àwa nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé? Gbé àwọn ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe yẹ̀ wò, bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì. Díẹ̀ lára wọn la ṣàpèjúwe sí àwọn ojú ewé wọ̀nyí.
Ìsọfúnni Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run
A kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ìlérí àgbàyanu tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa mọ́, èyí yóò sì gbé wa padà sórí ọ̀ràn sísọ̀rọ̀ nípa ìsìn. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, kí òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó dé, àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò lo ìdánúṣe láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó wí pé: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 1:8.
Ìsọfúnni yìí nípa Ìjọba Ọlọ́run ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pòkìkí rẹ̀ jákèjádò ayé. A ń tẹ èkejì ìwé ìròyìn yìí, Ilé Ìṣọ́, ní àádóje èdè, ọ̀rọ̀ náà, “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà,” sì máa ń wà lára èèpo ẹ̀yìn ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtẹ̀jáde tí ó lé ní mílíọ̀nù méjìlélógún tí a ń tẹ̀ nínú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan.
Gẹ́gẹ́ bí ọlọgbọ́n ènìyàn, ó yẹ kí o ṣe ìpinnu tó lọ́gbọ́n nínú nípa ìwàláàyè rẹ. (Òwe 18:13) Nítorí náà, a ké sí ọ láti wá mọ púpọ̀ sí i nípa Ìjọba ológo ti Ọlọ́run náà àti ohun tí ó lè túmọ̀ sí fún ọ. Láti ṣe èyí, má ṣe kọ̀ láti báni jíròrò Bíbélì. Kò sí ìjíròrò tí ó lè kún fún ẹ̀kọ́, tí ó lè gbádùn mọ́ni, tí ó sì lè ṣe pàtàkì ju èyí lọ.—Jòhánù 17:3.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn Ìlérí Nípa Párádísè Orí Ilẹ̀ Ayé
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà yóò gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.”—Sáàmù 72:7, 8.
Kódà, a óò jí àwọn òkú dìde pàápàá. “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” —Ìṣe 24:15.
A óò gbádùn ìlera pípé títí láé. “[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Àwọn ènìyàn yóò gbé inú ilé tí wọ́n kọ́ fúnra wọn. “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” —Aísáyà 65:21.
Oúnjẹ yóò pọ̀ rẹpẹtẹ. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” —Sáàmù 72:16.