ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 3/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣàtúnṣe Àwọn Àṣìṣe Inú Bíbélì
  • Àwọn Ọlọ́pàá Tí Ń Lọ Káàkiri
  • Ẹja Atọ́ka
  • Ìwà Ipá Nínú Eré Bọ́ọ̀lù
  • Ọwọ́ Rẹ àti Ìlera
  • Fáírọ́ọ̀sì Tuntun Nínú Ẹ̀jẹ̀
  • ‘Ìmìtìtì Oòrùn’ Àkọ́kọ́ Tí A Díwọ̀n
  • Ìdùnnú Ṣubú Layọ̀ —Àti Iṣẹ́ Púpọ̀ Sí i!
  • Tẹlifíṣọ̀n àti Jàǹbá
  • Àwọn Ọmọdé àti Kaféènì
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Ààbò Táwọn Ọlọ́pàá Ń Pèsè—Ìrètí àti Ìbẹ̀rù Táwọn Èèyàn Ní Nípa Rẹ̀
    Jí!—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 3/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ṣíṣàtúnṣe Àwọn Àṣìṣe Inú Bíbélì

Ìwé ìròyìn Bible Review sọ pé: “Àwọn àṣìṣe tí a ṣe nínú àwọn Bíbélì tí a tẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, àmọ́, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé a kò kà wọ́n sí.” Fún àpẹẹrẹ, ohun tí a mọ̀ sí Bíbélì Òpònú ni èyí tí a tẹ̀ jáde ní àkókò tí Charles Kìíní wà lórí oyè. Ní Sáàmù kẹrìnlá, òǹtẹ̀wé náà ṣèèsì yí ọ̀rọ̀ kan padà. Àbájáde rẹ̀ mú kí ẹsẹ kìíní kà pé: “Òpònú sọ nínú ara rẹ̀ pé Ọlọ́run wà.” Èyí sì fa sísan ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] pọ́n-ùn owó ìtanràn. Ilé iṣẹ́ mìíràn tí a ń pè ní Barker àti Lucas ni wọ́n bu owó ìtanràn tí iye rẹ̀ jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún [300] pọ́n-ùn fún ní ọdún 1631 nítorí pé wọ́n yọ ọ̀rọ̀ kan kúrò nínú ẹ̀dà tí a ń pè ní Bíbélì Panṣágà. Èyí mú kí ilé iṣẹ́ wọn kógbá sílé. Ẹ̀dà tiwọn kà pé: “Kí ìwọ máa ṣe panṣágà.” Bákan náà ni Bíbélì Máa Dẹ́ṣẹ̀, ti 1716. Níbi tí Jésù ti sọ fún ọkùnrin tó mú lára dá pé kí ó “máà dẹ́ṣẹ̀ mọ́,” wọ́n ní ó sọ pé kí ó “máa dẹ́ṣẹ̀ sí i.” Èyí tí a kò tún ní gbójú fò dá ni Bíbélì Ọtí Kíkan, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1717. Àkòrí tó wà lókè Lúùkù orí ogún sọ pé, “Àkàwé Ọtí Kíkan,” dípò tí ì bá fi kà pé, “Àkàwé Ọgbà Àjàrà.”

Àwọn Ọlọ́pàá Tí Ń Lọ Káàkiri

Àwọn ọlọ́pàá kan ní Ilẹ̀ Àríwá Amẹ́ríkà ti ń lo bàtà onítáyà lábẹ́, kí wọ́n lè túbọ̀ máa kàn sí àwọn aládùúgbò wọn. Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé, fífi ẹsẹ̀, ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ rìn káàkiri tún ti di èyí tí ó wọ́pọ̀ pẹ̀lú. Àwọn ọlọ́pàá ń lo bàtà onítáyà lábẹ́ ní àwọn ìlú ńlá bíi Chicago, Miami, àti Montreal. Sájẹ́ǹtì Bill Johnston, ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá Fort Lauderdale, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tó kọ́kọ́ lo bàtà onítáyà lábẹ́, sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ni àwọn ènìyàn ti tẹ́wọ́ gbà á tọkàntọkàn. Bí o bá ti wọ bàtà onítáyà yìí, o ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí àwọn aráàlú tán, o sì ti di ẹni tí wọ́n lè túbọ̀ súnmọ́ sí i.” Ìwé ìròyìn The Toronto Star tún mú kókó kan jáde pé, “lílo bàtà onítáyà jẹ́ àǹfààní ńlá—fún àpẹẹrẹ, ó máa ń bá àwọn olè ajímọ́tògbé ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí lójijì.”

Ẹja Atọ́ka

Báwo ni ẹja rainbow trout ṣe ń mọ ibi tí wọ́n ń lọ? Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé, àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè ní New Zealand ti rí i pé wọ́n ní “òòfà kan tí ń tọ́ka ọ̀nà ní imú wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn ẹyẹ àti àwọn ẹranko afàyàfà àti àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú kan lè máa lo òòfà agbègbè ilẹ̀ ayé láti darí ara wọn. Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tí ì fìgbà kan rí mọ sẹ́ẹ̀lì tí ń fi agbára ìmọ̀lára tọ́ka sí ìhà àríwá, àwọn sẹ́ẹ̀lì tí a gbà gbọ́ pé wọ́n ní èròjà magnetite tó ní agbára òòfà nínú. Ní ti ẹja trout, àwọn olùwádìí ní Yunifásítì Auckland ṣàwárí fọ́nrán iṣan kan ní ojú ẹja náà tí ó máa ń ṣáná nígbà tí ó bá bọ́ sí àgbègbè agbára òòfà. Títọpa fọ́nrán náà ni ó ṣamọ̀nà wọn padà sí imú ẹja náà, níbi tí wọ́n ti rí iṣan sẹ́ẹ̀lì tó ní èròjà magnetite nínú.

Ìwà Ipá Nínú Eré Bọ́ọ̀lù

Ìbánidíje lílágbára láàárín onírúurú ẹgbẹ́ tó kópa nínú eré bọ́ọ̀lù Ife-Ẹ̀yẹ Àgbáyé ní ọdún tó kọjá ló ṣokùnfà àwọn ayẹyẹ tó sábà máa ń parí pẹ̀lú ìwà ipá. Ní Mexico, ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] àwọn ọlọ́pàá tí a pè láti ṣàkóso àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ti Mexico. Ìwé ìròyìn El Universal ti Mexico ròyìn pé, ó lé ní igba ènìyàn tí àwọn ọlọ́pàá kó. Bọ́ǹbù kékeré kan tí wọ́n jù ní àkókò rúkèrúdò náà bú gbàù lu ojú ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ olólùfẹ́ àwọn agbábọ́ọ̀lù, ó sì ba apá kan agbárí rẹ̀ jẹ́. Bákan náà ni àwọn ayẹyẹ tó burú jáì, nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti fara pa gan-an, tí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn tún wáyé ní Ajẹntínà, Belgium, àti Brazil. Ní ilẹ̀ Faransé, ìwé ìròyìn Excelsior ti Ìlú Mexico ròyìn pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ènìyàn ni wọ́n kó nítorí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdíje bọ́ọ̀lù Ife-Ẹ̀yẹ Àgbáyé náà, àwọn ọ̀rìnlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àti mẹ́fà [1,586] ni wọ́n lé jáde pé wọn kò gbọ́dọ̀ padà sí orílẹ̀-èdè náà mọ́.

Ọwọ́ Rẹ àti Ìlera

Ìwé ìròyìn The Medical Post ti Kánádà sọ pé: “Nígbà tí ènìyàn bá sín, tí ó sì fọwọ́ bo ẹnu rẹ̀ tàbí tí ó bá fun imú rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ náà kí ó tó fọwọ́ kan tẹlifóònù tàbí ohun tí a fi ń ṣí ilẹ̀kùn.” Ìwé ìròyìn Post náà ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Ẹgbẹ́ Àwọn Amọṣẹ́dunjú Lórí Ìdènà Àkóràn àti Àjàkálẹ̀ Àrùn, tó sọ pé, “ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àkóràn àrùn ni kì í ṣe inú afẹ́fẹ́ ni a ti ń kó wọn bí kò ṣe ní ọwọ́ àti lára àwọn ohun tí a ń fọwọ́ kàn.” Dókítà Audrey Karlinsky ti Yunifásítì Toronto dámọ̀ràn fífọwọ́ ní gbogbo ìgbà, kí a sì máa fi ọṣẹ pa ọwọ́ “fún ìṣẹ́jú àáyá mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, kí a rí i dájú pé ọṣẹ dé àárín gbogbo ọmọ-ìka àti abẹ́ èékánná pẹ̀lú.” Lẹ́yìn ìyẹn, ó wá dábàá pé, kí o wá fi omi gbígbóná ṣan ọwọ́ rẹ kí o sì fi ìnuwọ́ nù ún gbẹ. Báwo ni o ṣe lè mú kí àwọn ọmọdé lo àkókò tí ó pọ̀ tó lórí ọwọ́ fífọ̀? Dókítà Karlinsky dábàá pé, jẹ́ kí wọ́n máa ka ABD láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ní àkókò tí wọ́n bá ń fọṣẹ fọwọ́ wọn.

Fáírọ́ọ̀sì Tuntun Nínú Ẹ̀jẹ̀

Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Le Monde, ròyìn pé, lẹ́yìn ṣíṣàwárí fáírọ́ọ̀sì tuntun kan nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn afẹ̀jẹ̀tọrẹ ní Yúróòpù, àwọn aláṣẹ lórí ètò ìlera ní ilẹ̀ Faransé ti pinnu láti ṣàgbékalẹ̀ “ẹgbẹ́ kan tí yóò máa bójútó àwọn ohun tó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu títí lọ.” Ọdún 1997 ni a kọ́kọ́ mọ̀ nípa aṣokùnfà àkóràn náà, tí a mọ̀ sí fáírọ́ọ̀sì tí a ń kó nínú ẹ̀jẹ̀ tí a gbà sára (TTV), ní ilẹ̀ Japan, níbi tí ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún àwọn afẹ̀jẹ̀tọrẹ ti ní fáírọ́ọ̀sì náà lára. Àwọn dókítà kò tí ì mọ àìsàn tí fáírọ́ọ̀sì náà ń fà ní pàtó, àmọ́, àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lára àwùjọ àwọn aláìsàn kan, tí àrùn ẹ̀dọ̀ki tí a kò mọ orírun rẹ̀ ń yọ lẹ́nu, ló ní TTV lára. Ìwé ìròyìn Le Monde sọ pé, ní báyìí, kò tí ì sí ọ̀nà kan tí ó ṣe gúnmọ́ fún ṣíṣàyẹ̀wò fáírọ́ọ̀sì yìí.

‘Ìmìtìtì Oòrùn’ Àkọ́kọ́ Tí A Díwọ̀n

Ní ṣíṣàyẹ̀wò àwọn àwòrán tí ilé iṣẹ́ Gbalaṣa Òfuurufú Tí Ń Ṣojú fún ọkọ̀ àgbéresánmà ti Soho ní ilẹ̀ Yúróòpù yà, àwọn olùwádìí, Valentina Zharkova ti Yunifásítì Glasgow ti Scotland àti Alexander Kosovichev ti Yunifásítì Stanford, ní California, ti ṣàwárí ‘ìmìtìtì oòrùn’ fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti London ròyìn pé: “Ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣàwárí ipá alágbára kan tí ó mọ níwọ̀n, tó tú jáde láti Oòrùn, ó jẹ́ lára gáàsì hydrogen àti helium—ní July 1996.” Ìwọ̀n rẹ́ jẹ́ mọ́kànlá àti ẹ̀sún mẹ́ta [11.3], ó ní ìgbì tó ga ní kìlómítà mẹ́ta sókè, ó sì tú ohun kan tí ó jọ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ tí ń ta sókè nígbà tí a bá ju òkúta sínú ọ̀gọ̀dọ̀ jáde. Ohun tó tú jáde yìí rìn jìnnà sókè tó ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] kìlómítà rékọjá ojú oòrùn, ní ìwọ̀n ìyára tí ó tó ogún ọ̀kẹ́ [400,000] kìlómítà ní wákàtí kan. Agbára tí ‘ìmìtìtì oòrùn’ yìí tú jáde jẹ́ nǹkan bí iye kan náà pẹ̀lú èyí tí wọ́n lò ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní ogún ọdún, ó sì jẹ́ ìlọ́po lọ́nà ọ̀kẹ́ méjì [40,000] agbára ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní San Francisco ní ọdún 1906, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ mẹ́jọ àti ẹ̀sún mẹ́ta 8.3 lórí òṣùwọ̀n Richter.

Ìdùnnú Ṣubú Layọ̀ —Àti Iṣẹ́ Púpọ̀ Sí i!

Ìwé ìròyìn Nassauische Neue Presse ti ilẹ̀ Germany kọ ọ́ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ tọkọtaya ni wọ́n máa ń fojú kéré àfikún ẹrù iṣẹ́ tí ó máa ń bá ọmọ títọ́jú rìn. Èyí sì sábà máa ń fa ìjà láàárín tọkọtaya lẹ́yìn ìbímọ.” Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Yunifásítì Groningen, ní Netherlands, fi hàn pé àwọn ìyípadà lílékenkà tí ń dé nígbà tí a bá bímọ kì í sábà tẹ́ àwọn ìyá kéékèèké lọ́rùn. Ní ìpíndọ́gba, àwọn ìyá nílò àfikún ogójì wákàtí fún àwọn ọmọ wọn lọ́sẹ̀—nínú èyí tí wọ́n ti ń lo mẹ́fà fún àfikún ilé pípamọ́, aṣọ fífọ̀, àti fún oúnjẹ tí ó yẹ ní sísè, tí wọ́n sì ya mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n sọ́tọ̀ fún ọmọ wọn ní tààràtà. Ní ti àwọn bàbá, wákàtí mẹ́tàdínlógún tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ọmọ ní tààràtà nìkan ni àfikún ìgbòkègbodò wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn náà, másùnmáwo náà “kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ẹni tí yóò yí aṣọ ìlédìí ọmọ padà tàbí ẹni tí yóò jí lóru láti fọ́mọ lóúnjẹ, bí kò ṣe ti pípín iṣẹ́ ilé ṣe.”

Tẹlifíṣọ̀n àti Jàǹbá

Àwọn ọmọ tí wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ nídìí tẹlifíṣọ̀n wíwò lè ní ìsúnniṣe láti fẹ́ ṣàfarawé àwọn nǹkan eléwu tí wọ́n ń rí. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí olùwádìí ara Sípéènì náà, Ọ̀mọ̀wé José Umberos Fernández, ṣe, wákàtí kọ̀ọ̀kan tí ọmọ kan bá lò níwájú ẹ̀rọ tẹlifíṣọ̀n ń mú kí àtifarapa rẹ̀ nígbà ọmọdé túbọ̀ pọ̀ sí i. Fernández dámọ̀ràn pé, èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé tẹlifíṣọ̀n máa ń fúnni ní ojú ìwòye tí ó lòdì sí òtítọ́. Àmọ́, kí ni àwọn òbí lè ṣe láti yí ìyọrísí yìí padà? Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn èdè Gíríìkì náà, To Vima, sọ, àwọn òbí gbọ́dọ̀ nípìn-ín nínú yíyan àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àwọn ọmọ wọn yóò máa wò, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “fọgbọ́n yan ohun tí wọn yóò wò” dípò tí wọn yóò fi gbà pé gbogbo ohun tí àwọn rí jẹ́ òtítọ́.

Àwọn Ọmọdé àti Kaféènì

Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé, bí àwọn ọmọdé kò tilẹ̀ mu kọfí tàbí tíì, ọ̀pọ̀ ni ó máa ń mu kaféènì tó pọ̀ tó nínú àwọn ohun mímu tó ní èròjà carbonate àti ṣokoléètì nínú, tí wọ́n sì máa ń jìyà rẹ̀ nígbà tí wọn kò bá mu ún mọ́. Àkójọ àwọn oníṣègùn ọpọlọ tí Dókítà Gail A. Bernstein, ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ní Yunifásítì ti Minnesota ṣe aṣáájú wọn, darí àfiyèsí sí ipa tí kaféènì ní lórí iye àkókò ìpọkànpọ̀ àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí wọ́n ti tó ilé ẹ̀kọ́ lọ. Wọ́n mú kí iye kaféènì tí àwọn ọmọ náà ń mu tó agolo cola mẹ́ta lóòjọ́. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, àwọn ọmọ náà kò mu kaféènì fún odindi ọjọ́ kan. Ìwọ̀n ìpọkànpọ̀ àwọn ọmọ náà lọ sílẹ̀ gan-an ní ọjọ́ yẹn àti ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà. Àwọn olùwádìí náà sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù láti dá ohun ìyàlẹ́nu yìí dúró ni mímú kí àwọn ọmọdé yẹra fún àwọn ohun mímu tó ni kaféènì púpọ̀ nínú.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́