Lẹ́yìn Ìjì, Ẹ̀sìn Kristẹni Borí
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MÒSÁŃBÍÌKÌ
ÌJÌ líle kọlu ìlú Màpútò, ní Mòsáńbíìkì, lálẹ́ March 2, 1998. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìjì náà ti ba ibi gbogbo jẹ́. Àwọn igi tó wó wà káàkiri etíkun, omi tí ń ru gùdù ba gbogbo ọ̀nà jẹ́, ẹ̀fúùfù ti gbé ọ̀pọ̀ òrùlé lọ, àwọn ilé mìíràn sì ti wó.
Digbídigbí làwọn ilé tó wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúró. Ṣùgbọ́n ilé aládùúgbò wọn kan, tí wọ́n fi igi kọ́, tí wọ́n sì fi páànù bò, kò lẹ́mìí ẹ̀. Ilé náà kò rẹ́sẹ̀ dúró lójú ẹ̀fúùfù líle náà, ṣe ló ya lulẹ̀. A dúpẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ilé náà, èyíinì ni obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ márààrún, mórí bọ́ láìfarapa. Àmọ́ ṣá o, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun ìní wọn ló ṣègbé.
Láàárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society bẹ ìdílé náà wò, wọ́n sì rí wọn tí wọ́n ń ṣa ìwọ̀nba nǹkan ìní wọn tó kù láti inú pàǹtírí náà. Àwọn nǹkan tí wọ́n pàdánù mú kí ọkàn wọ́n túbọ̀ bà jẹ́, níwọ̀n bí wọn kò ti ní owó tó tó láti fi tún ilé wọn kọ́. Ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ń rí, látinú oúnjẹ wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ tí wọ́n ń tà lọ́jà ló ti ń wọlé fún ìdílé náà, nítorí wọn kò ní bàbá.
Lẹ́yìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàyẹ̀wò ipò wọn, kíá ni wọ́n nawọ́ ìrànwọ́ sí ìdílé náà. Wọ́n dé orí ìpinnu náà pé àwọn ohun èlò ìkọ́lé tó bà jẹ́ kù lára ilé náà kò ṣeé tún lò. Fún ìdí yìí, agbo àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n nílò jọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé mọ́ńbé kan tó dúró sán-ún.
Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, ṣe làwọn aládùúgbò ń garùn, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ni háà ṣe wọ́n, nígbà tí wọ́n rí bí iṣẹ́ náà ti ń tẹ̀ síwájú kánmọ́kánmọ́. Láàárín ọjọ́ márùn-ún, a ti kọ́ ilé náà tán, ó sì ti ṣeé gbé. Nígbà tóbìnrin náà wọ ilé rẹ̀ tuntun, ó kàn lanu ni, kò mọ ohun tí ì bá sọ. Àmọ́, kò dìgbà tó bá sọ̀rọ̀, torí pé ayọ̀ ìyá náà àti tàwọn ọmọ rẹ̀ hàn kedere nígbà táwọn òṣìṣẹ́ náà rí wọ́n tí wọn bu ẹ̀rín sẹ́nu, tí ojú wọn sì fi hàn pé wọ́n mọrírì ohun tí wọ́n ṣe fún wọn gan-an.
Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn pẹ̀lú láyọ̀. Inú wọn dùn pé àwọn náà láǹfààní láti fi ẹ̀mí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́.—Gálátíà 6:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
March 5
March 6
March 7
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń gbé ládùúgbò yìí tún ilé ìdílé yìí kọ́