ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 5/8 ojú ìwé 13-15
  • Èé Ṣe Tí Èrò Bí Mo Ṣe Tóbi Tó Fi Gbà Mí Lọ́kàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Èrò Bí Mo Ṣe Tóbi Tó Fi Gbà Mí Lọ́kàn?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífebi Para Ẹni Kú
  • Àrùn Ayọ́kẹ́lẹ́ Náà
  • Àwọn Ewu Ìlera
  • Bí Mi Ò Bá Fẹ́ràn Bí Mo Ṣe Rí Ńkọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ọ̀ràn Sísanra Tó Gbà Mí Lọ́kàn?
    Jí!—1999
  • Èé Ṣe Tí Mo Fi Rí Tẹ́ẹ́rẹ́ Báyìí?
    Jí!—2000
  • Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 5/8 ojú ìwé 13-15

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Èrò Bí Mo Ṣe Tóbi Tó Fi Gbà Mí Lọ́kàn?

“Ìjàkadì kan tí kò ṣeé dá dúró ń lọ lọ́kàn mi. Apá kan mi ń fẹ́ láti jẹun, ṣùgbọ́n apá kejì lòdì sí jíjẹun nítorí pé ẹ̀rù ń bà mí pé mo lè lọ tóbi jù.”—Jaimee.

KÍ NI ohun tó bà ọ́ lẹ́rù ju lọ láyé yìí? Kíá ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin yóò dáhùn pé: títóbi ni. Ní gidi, ìwádìí kan fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́bìnrin òde òní kò bẹ̀rù ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, àrùn jẹjẹrẹ, tàbí ikú àwọn òbí wọn tó bí wọ́n ṣe bẹ̀rù sísanra!

Nígbà mìíràn, ó máa ń yani lẹ́nu pé ìdààmú nípa bí a ṣe tóbi tó ti máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a ṣì kéré. Ọ̀mọ̀wé Catherine Steiner-Adair sọ pé, kódà kí àwọn ọmọdébìnrin tó di ọ̀dọ́langba, púpọ̀ wọ́n máa ń kóra jọ láti “sọ̀rọ̀ nípa sísanra”—níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí tọ̀túntòsì wọ́n ti máa ń fi ìkórìíra tí wọ́n ní nípa ìrísí ara wọn hàn. Ẹ̀rí fi hàn pé ó ju wíwulẹ̀ fọ̀rọ̀wérọ̀ lọ. Nínú ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ ẹ̀ẹ́dégbèjìlá ó lé mọ́kàndínlọ́gọ́rin [2,379] ọmọdébìnrin, ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ń gbìyànjú láti fọn. Àwọn tí a sì ṣèwádìí náà lọ́dọ̀ wọn jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án àti ọmọ ọdún mẹ́wàá péré!

Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn èwe wọ̀nyí lè kó sínú ìdẹkùn àṣà ìṣọ́únjẹjẹ. Èyí tó burú jù ni pé ọ̀ràn àwọn kan lè wá dà bí ti Jenna ọmọ ogún ọdún. Ogójì kìlógíráàmù péré ni ọmọbìnrin tó ga ní ọgọ́jọ sẹ̀ǹtímítà yìí fi tóbi! Jenna sọ pé: “N kì í fẹ́ jẹun. Ohun tó ń dà mí láàmú jù ni pé ọdún mẹ́ta gbáko ló gbà mí kí n tó fọn, bí mo bá sì ń jẹun, láàárín oṣù kan péré, màá tún tóbi padà.”

Bóyá o lè lóye ìmọ̀lára tí Jenna ní. Ó lè jẹ́ pé ìwọ pẹ̀lú ti ń wá bí o ṣe máa fọn kí o bàa lè jojú ní gbèsè. Dájúdájú, kò sí ohun tó burú nínú pé kí ìrísí rẹ jẹ ọ́ lọ́kàn. Àmọ́, ní ti Jenna, ìfẹ́-ọkàn láti di ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀. Lọ́nà wo?

Fífebi Para Ẹni Kú

Jenna bá ìṣòro àṣà ìjẹun tó léwu kan tí ń jẹ́ àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra jà. Bẹ́ẹ̀ ló rí nínú ọ̀ràn ti Jaimee, tí a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ níṣàájú. Fún ìgbà díẹ̀, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí wulẹ̀ ń fi ebi pa ara wọn kú, kí í sì í ṣe àwọn nìkan ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ọ̀kan lára ọgọ́rùn-ún ọmọbìnrin ló ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọ̀dọ́bìnrin ló ní ìṣòro náà—kódà ẹnì kan tí o mọ̀ lè ní ìṣòro náà!

Ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra lè bẹ̀rẹ̀ láìfura. Ọ̀dọ́bìnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ oúnjẹ jẹ lọ́nà tó jọ pé kò ní pa á lára, bóyá nítorí àtifọn níwọ̀nba. Àmọ́, nígbà tí ó bá fọn dé ibi tó ń fẹ́, kò ní tí ì tẹ́ ẹ lọ́rùn. Bó bá ń wo dígí, á máa sọ láìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nípa bó ṣe rí, pé: “Mo ṣì sanra jù!” Nítorí náà, yóò pinnu láti fọn díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, kó tún fọn díẹ̀ sí i. Tó bá tún yá, á tún fẹ́ fọn sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ti ṣínà fún ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, ó sì ti kira bọ̀ ọ́ ná.

Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo àwọn tí kì í jẹun dáadáa ló ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra. Ìdààmú àwọn kan nípa bí wọ́n ṣe tóbi tó bọ́gbọ́n mu, àti pé fífọn níwọ̀nba lè ṣe wọ́n láǹfààní. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ló ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìrísí ara wọn. Ìwé ìròyìn FDA Consumer fi níní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìrísí ẹni wé wíwo dígí tí a gbé sí ọgbà ìṣeré. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ńṣe ni wàá rí i tí o tóbi ju bí o ṣe rí gẹ́lẹ́ lọ.”

Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra náà máa ń bẹ̀rù pé kí òun má sanra—kódà tó bá gbẹ bí igi ìgbálẹ̀. Ó lè máa ṣeré ìdárayá láṣejù kí ó bàa lè fọn, ó sì lè máa yẹ ẹ̀rọ ìtẹ̀wọ̀n wo nígbà bí mélòó kan lóòjọ́ láti rí i dájú pé òun ò “tún tóbi padà.” Tó bá fẹ́ jẹun, ìwọ̀nba ṣín-ún ló máa jẹ. Tàbí kó má tilẹ̀ jẹ rárá. Heather sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbé oúnjẹ ọ̀sán tí mọ́mì sè fún mi dáni lọ sí ilé ẹ̀kọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń dà á nù. Láìpẹ́, ó wá mọ́ mi lára kí n máà máa jẹun débi pé bí mo bá tilẹ̀ dédìí oúnjẹ, n kì í lè jẹ ẹ́. Ebi kì í pa mí.”

Inú àwọn tó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra bí ti Heather kọ́kọ́ máa ń dùn tí wọ́n bá rí i pé àwọn ti fọn. Ṣùgbọ́n àìjẹun dáadáa á wá ṣe ọṣẹ́ tiẹ̀. Oorun á máa kun ẹni tó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra náà yóò sì máa ṣe dìẹ̀dìẹ̀. Iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ yóò máa jó rẹ̀yìn. Ó lè máà rí nǹkan oṣù rẹ̀.a Bí àkókò ti ń lọ, ìlùkìkì ọkàn-àyà rẹ̀ àti ìwọ̀n ìfúnpá rẹ̀ lè lọ sílẹ̀ lọ́nà tó léwu. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ẹni tó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra kò ní mọ̀ pé ewu èyíkéyìí wà lórí òun. Ní gidi, ewu kan ṣoṣo tó rò pé òun lè ní ni sísanra padà—bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìwọ̀n kìlógíráàmù kan péré.

Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra nìkan ni ìṣòro àṣà ìjẹun tó wà, òun nìkan sì kọ́ ló wọ́pọ̀ jù lọ. Ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ jẹ́ ìṣòro kan tí ń bá àwọn ọmọbìnrin tí iye wọn jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ti àwọn tó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra jà. Bákan náà ni ìṣòro àjẹjù wà, èyí tó tan mọ́ ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ léraléra. Ẹ jẹ́ kí a fìṣọ́ra gbé àwọn ìṣòro wọ̀nyí yẹ̀ wò.

Àrùn Ayọ́kẹ́lẹ́ Náà

“Ọ̀rẹ́ mi kan jẹ́wọ́ láìpẹ́ yìí pé òun máa ń yọ́ oúnjẹ gbé, òun á sì lọ jẹ ẹ́ níbi tí a kò ti ní rí òun. Lẹ́yìn náà á wá ṣe é tí ó fi máa bì í dà nù. Ó sọ pé ó ti pé ọdún méjì tí òun ti ń ṣe bẹ́ẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èwe kan fi ṣàpèjúwe àwọn àmì tí a sábà máa ń rí lára ẹni tó bá ní ìṣòro àṣà ìjẹun tí a mọ̀ sí ìyánnújù fún oúnjẹ nínú ìwé tó kọ sí ẹ̀ka ìdámọ̀ràn ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan.

Ẹni tó ní ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ léraléra náà á yára jẹ oúnjẹ tó pọ̀ gan-an. Lẹ́yìn náà á wá ọ̀nà tí oúnjẹ tó jẹ náà yóò fi jáde kúrò ní inú rẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà nípa fífagbára mú ara rẹ̀ bì.b Lóòótọ́, ó lè jọ pé èrò bíbi ohun tó wà ní inú dà nù ń kóni nírìíra. Síbẹ̀, òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re Nancy J. Kolodny kọ̀wé pé: “Bí o bá ṣe ń jẹun tó tí o sì ń ṣu ú dà nù léraléra tó, ni yóò fi rọrùn fún ọ tó. Ìfarajin ìyánnújù fún oúnjẹ náà á wá tètè rọ́pò ìríra àti ẹ̀rù tó lè máa bà ọ́ níbẹ̀rẹ̀ pàápàá.”

A ti pe ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra àti ìyánnújù fún oúnjẹ ní “ọmọ ìyá kan náà tí kò jọra.” Bí wọ́n tilẹ̀ ní àmì tó yàtọ̀ síra, dídààmú jù nípa oúnjẹ ló ń fa àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì méjèèjì.c Ṣùgbọ́n ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ rọrùn gan-an láti fi bò ju ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra. Ó ṣe tán, jíjẹun tó pọ̀ gan-an kò ní jẹ́ kí ẹni tó ní ìṣòro náà fọn, ṣíṣu ú dà nù kò sì ní jẹ́ kí ó sanra. Nítorí náà, ẹni tó ní ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ náà lè má sanra jọ̀kọ̀tọ̀, ó sì lè máà pẹ́lẹ́ńgẹ́, ó sì lè dà bí ẹni tó ń jẹun dáadáa lójú ayé. Obìnrin kan tí ń jẹ́ Lindsey sọ pé: “Fún ọdún mẹ́sàn-án ni mo fi dáṣà jíjẹun púpọ̀ gan-an àti bíbì í dà nù tó ẹ̀ẹ̀mẹrin lójúmọ́. . . . Kò sí ẹni tó mọ̀ nípa ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ tí mo ní, nítorí pé mo fi bò dáadáa, mo sì ń fi ìrísí ìtóótun, ìdùnnú, àti ìwọ̀n ara tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ojú ayé.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ti ẹni tó ní ìṣòro àjẹjù yàtọ̀ díẹ̀. Bí ti ẹni tó ní ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ, ẹni yìí máa ń jẹ oúnjẹ tó pọ̀ gan-an lẹ́ẹ̀kan. Ìwé The New Teenage Body Book sọ pé: “Níwọ̀n bí a ti ń jẹun púpọ̀ gan-an ti a kì í sì í ṣu ú dà nù, ẹni tó ń jẹ àjẹjù náà lè sanra níwọ̀nba tàbí kí ó sanra jù tàbí kí ó sanra jọ̀kọ̀tọ̀.”

Àwọn Ewu Ìlera

Àwọn ìṣòro àṣà ìjẹun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí lè kó ewu tó le gan-an bá ìlera ẹni. Àṣà àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra lè fa àìjẹunre kánú, àti pé nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó pọ̀—tí a fojú díwọ̀n sí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún—ó lè ṣekú pani. Jíjẹ oúnjẹ púpọ̀ gan-an, tí a wá ṣu dà nù lẹ́yìn náà tàbí tí a kò ṣu dà nù, lè kó ewu bá ìlera ẹni. Bí àkókò ti ń lọ, ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ lè yọrí sí ewu àrùn ọkàn-àyà òun iṣan ẹ̀jẹ̀, àtọ̀gbẹ, àti àwọn oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan pàápàá. Mímọ̀ọ́mọ̀ fagbára mú ara ẹni bi oúnjẹ dà nù lè dá ọgbẹ́ síni lọ́fun, lílo àwọn oògùn ìyàgbẹ́ àti oògùn ìtọ̀ nílòkulò sì lè yọrí sí dídákú nínú àwọn ọ̀ràn líle kan.

Bí ó ti wù kí ó rí, oríṣi ìṣòro àṣà ìjẹun mìíràn wà tí a ní láti gbé yẹ̀ wò. Àwọn tí wọ́n ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, ìyánnújù fún oúnjẹ, àti jíjẹ àjẹjù kì í sábà láyọ̀. Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ní iyì ara ẹni tó pọ̀ tó, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa ṣàníyàn, kí wọ́n sì sorí kọ́. Ó hàn kedere pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè ran àwọn tí wọ́n ní ìṣòro àṣà ìjẹun lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ èrò nípa bí wọ́n ṣe tóbi tó tí ó gbà wọ́n lọ́kàn? A óò dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí lọ́jọ́ iwájú.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí a bá ṣàyẹ̀wò ọmọbìnrin kan, a lè sọ pé ó ní ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra tí ó bá fi nǹkan bí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fọn ju bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ tí kò sì rí nǹkan oṣù rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

b Àwọn ọ̀nà mìíràn tí a ń gbà ṣu ohun tó wà nínú dà nù ní lílo oògùn ìyàgbẹ́ tàbí oògùn ìtọ̀ nínú.

c Àwọn mélòó kan tó ní ìṣòro wọ̀nyí ń yí láti orí àṣà àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra sí ìyánnújù fún oúnjẹ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Èrò Tí Kò Tọ̀nà Nípa Ara Ẹni

Kò sí ìdí tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọbìnrin tí ń dààmú nípa bí wọ́n ṣe tóbi tó fi ní láti máa dààmú. Nínú ìwádìí kan, ìpín méjìdínlọ́gọ́ta lára àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí mẹ́tàdínlógún gbà gbọ́ pé àwọn tóbi jù, nígbà tó jẹ́ pé ní gidi, ìpín mẹ́tàdínlógún péré lára wọn ló tóbi jù. Nínú ìwádìí mìíràn, ìpín márùndínláàádọ́ta lára àwọn obìnrin tí wọn kò tóbi tó ní gidi lérò pé àwọn ti tóbi jù! Ìwádìí kan tí a ṣe ní Kánádà fi hàn pé ìpín àádọ́rin lára àwọn obìnrin tó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn ni ọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe tóbi tó ń gbà lọ́kàn, ìpín ogójì sì ń dáṣà jíjẹun ségesège—àṣà fífọn àti sísanra padà.

Ó ṣe kedere pé èrò tí kò tọ̀nà nípa ara ẹni lè mú kí àwọn ọmọbìnrin kan máa dààmú jù nípa nǹkan tí kì í ṣe ìṣòro ní ti gidi. Kristin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún sọ pé: “Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó máa ń lo àlòjù oògùn tí kì í jẹ́ kí ènìyàn jẹun púpọ̀, mo sì mọ àwọn ọmọbìnrin díẹ̀ tí wọ́n ní ìṣòro àìjẹunrekánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra.” Ó tún sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kò sì sí èyí tó sanra páàpáà nínú wọn.”

Ìwé ìròyìn FDA Consumer ní ìdí rere láti dámọ̀ràn pé: “Dípò kí o má jẹun nítorí pé ‘gbogbo ènìyàn’ ń ṣe é tàbí nítorí pé o kò pẹ́lẹ́ńgẹ́ tó bí o ṣe fẹ́, kọ́kọ́ wádìí lẹ́nu dókítà kan tàbí onímọ̀ nípa àṣà ìjẹun bóyá o tóbi jù tàbí bóyá ọ̀rá ara rẹ pọ̀ jù fún ọjọ́ orí rẹ àti gíga rẹ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Kò sí ìdí tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe tóbi tó ń jẹ lọ́kàn fi ní láti dààmú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́