Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ọ̀ràn Sísanra Tó Gbà Mí Lọ́kàn?
“Ohun tó ń yọ mí lẹ́nu jù lọ láyé mi ni bóyá kí n fi àwọn èròjà tí ń múni sanra sáàárín búrẹ́dì mi. Báwo ni mo ṣe lè pọkàn pọ̀ sórí ohunkóhun nígbà tó jẹ́ pé ọ̀ràn irú èròjà tí ń múni sanra tí a ń fi sáàárín búrẹ́dì ló gbà mí lọ́kàn? Kí wá ni ìpinnu mi? N kò ní fi èròjà tí ń múni sanra sáàárín búrẹ́dì mi—èròjà inú rẹ̀ tí ń múni sanra ti pọ̀ jù. Àṣà àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra tún ṣẹ́gun. Mo tún kó sínú ìṣòro náà padà.”—Jaimee.
ÀṢÀ jíjẹun lọ́nà òdì ń pọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èwe lójú.a Kì í ṣe èrò ọkàn èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn láti máa febi pa ara wọn (àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra), wọn kì í sì í ní in lọ́kàn láti máa jẹ àjẹjù kí wọ́n wá ṣu ú dà nù (ìṣòro ìyánnújù fún oúnjẹ) nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ète fífọn níwọ̀nba. Ṣùgbọ́n kí wọ́n tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ti wà nínú àkámọ́ àṣàkaṣà fífebipara-ẹni tàbí jíjẹ àjẹjù. Jaimee sọ pé: “Nítorí kí n lè ṣàkóso bí mo ṣe sanra ni mo ṣe bẹ̀rẹ̀ àṣà ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ yìí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí òun ló ń darí mi.”
Bí o bá rí i pé ipa tí oúnjẹ ń ní lórí bí o ṣe sanra tó ń gbà ọ́ lọ́kàn, kí lo lè ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí ó yé ọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ti bá àṣà jíjẹun lọ́nà òdì jà, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀! Ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?
Wíwo Ara Rẹ Nínú Dígí
Ṣíṣàìdààmú nípa ìrísí rẹ ni ìgbésẹ̀ pàtàkì kan nínú ṣíṣẹ́gun ìjà tí a ń bá àṣà jíjẹun lọ́nà òdì jà. Ìwé Changing Bodies, Changing Lives sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n ní ìṣòro àṣà jíjẹun lọ́nà òdì ló ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìrísí ara wọn. Wọn kò fi ojú gidi wo ara wọn, wọ́n sì ń ṣòfíntótó ara wọn jù, pàápàá ìrísí wọn.”
Ní gidi, àwọn èwe kan gbé èrò tí wọ́n ní nípa ara wọn karí bí wọ́n ṣe rí; wọ́n sì ń ka àbùkù èyíkéyìí lára wọn sí ohun bíburújáì. Vicki, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Mo sanra gan-an débi pé ńṣe lara ń ni mí. Ìbàdí mi fẹ̀ débi pé mi ò lè wọ aṣọ kí n kì í sínú ṣòkòtò.” Kódà, lẹ́yìn tí Vicki ti fọn ní ìwọ̀n kìlógíráàmù mẹ́wàá, kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Kì í jẹun, tó bá sì jẹun, àjẹjù á wọ̀ ọ́, á wá bi ohun tó jẹ dà nù.
Lóòótọ́, kò burú pé kí o ṣàníyàn nípa ìrísí rẹ dé àyè kan. Nípa èyí, ó dùn mọ́ni nínú láti mọ̀ pé Bíbélì sọ̀rọ̀ tó dára nípa ìrísí àwọn obìnrin àti ọkùnrin mélòó kan, bí Sárà, Rákélì, Jósẹ́fù, Dáfídì, àti Ábígẹ́lì.b Bíbélì tilẹ̀ sọ pé Ábíságì, olùṣètọ́jú Dáfídì, “lẹ́wà dé góńgó.”—1 Àwọn Ọba 1:4.
Ṣíṣàlàyé Ojúlówó Ẹwà
Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì kò fi ìrísí tàbí ìgbékalẹ̀ ara ẹni sí ipò kìíní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé ìjẹ́pàtàkì karí “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.” (1 Pétérù 3:4) Ẹni tí a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló ń mú kí a wu Ọlọ́run àti ènìyàn tàbí kí a jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú wọn.—Òwe 11:20, 22.
Gbé ọ̀ràn Ábúsálómù, ọmọ Ọba Dáfídì, yẹ̀ wò. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ọkùnrin kankan tí ó lẹ́wà bí Ábúsálómù tí ó yẹ fún ìyìn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ní gbogbo Ísírẹ́lì. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀, kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 14:25) Síbẹ̀, aládàkàdekè ni ọ̀dọ́mọkùnrin tí a ń wí yìí. Ìgbéraga àti ọ̀kánjúà tì í láti fẹ́ fipá gba ipò lọ́wọ́ ọba tí Jèhófà yàn sípò. Nítorí náà, Bíbélì kò sọ ohun tó dára nípa Ábúsálómù ṣùgbọ́n ó pè é ní aláìṣòótọ́ tí kò lójútì àti ẹni tó kórìíra ẹni débi pé kó ṣekú pani.
Ẹwà ẹnì kan kò sinmi lórí ìgbékalẹ̀ ara rẹ̀. Ìdí rere wà tí Bíbélì fi sọ pé: “Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye. Yóò fún orí rẹ ní ọ̀ṣọ́ òdòdó olóòfà ẹwà; adé ẹwà ni yóò fi jíǹkí rẹ.”—Òwe 4:7, 9.
Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni pé kì í ṣe àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn nípa ìrísí ara ẹni nìkan ló sábà máa ń mú kí ìṣòro àṣà jíjẹun lọ́nà òdì yọjú. Ìwé kan sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí ọ̀ràn oúnjẹ jíjẹ ń gbà lọ́kàn tí wọ́n sì kó sínú ìdẹkùn ìṣòro àṣà jíjẹun lọ́nà òdì bí àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra, ìyánnújù fún oúnjẹ, àti àjẹjù kì í fi bẹ́ẹ̀ dá ara wọn lójú—wọn kò ní èrò tó ṣe gúnmọ́ nípa bí wọ́n ṣe wúlò tó, wọ́n sì máa ń rò pé àwọn ẹlòmíràn kì í ka àwọn sí pẹ̀lú.”
Àwọn ohun mélòó kan lè fa kí ènìyàn máà dá ara rẹ̀ lójú. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà, èrò àìdára-ẹni lójú lè bò ọ́—pàápàá tí o bá wú ju àwọn ojúgbà rẹ lọ. Lẹ́yìn náà, ilé tí pákáǹleke, tàbí ìfìyàjẹni tàbí ìbániṣèṣekúṣe ti máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra ni a ti tọ́ àwọn èwe kan dàgbà. Ohun yòówù tíì báà fà á, mímọ ohun náà tí ń tanná ran èrò àìjámọ́ǹkan ni yóò yanjú ọ̀ràn náà. Èyí túmọ̀ sí mímọyì bí a ṣe wúlò tó gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Dájúdájú, ó kéré tán, olúkúlùkù ló ní àwọn ànímọ́ kan tí a lè tìtorí rẹ̀ gbóríyìn fún un. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 12:14-18.) Lóòótọ́, o lè má mọ̀ wọ́n fúnra rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan tó dàgbà dénú lè sọ wọ́n fún ọ.
Àmọ́, ká ní o ní láti fọn ní ti gidi nítorí ìlera ńkọ́? Bíbélì dámọ̀ràn pé kí a jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà.” (1 Tímótì 3:11) Nítorí náà, ó dára jù lọ láti má ṣàṣejù nínú ọ̀ràn ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ tàbí kíkó sínú ìdẹkùn ìpètepèrò fífọn kíákíá. Bóyá ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà fọn ni láti máa jẹun tí ń ṣara lóore, kí a sì máa ṣe eré ìmárale níwọ̀nba. Ìwé ìròyìn FDA Consumer sọ pé: “Bí ó ti rí nínú ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn, ọ̀nà tó dára láti gbà fọn wà, èyí tí kò sì dára wà. Ọ̀nà tí kò dára ni ṣíṣàìjẹun ní àwọn ìgbà kan, pípinnu láti jẹ kìkì búrẹ́dì tí kò léròjà nínú kí a sì mumi sí i, kí a máa lo oògùn tí kì í jẹ́ kébi pani, tàbí kí o ṣe é tí wàá fi bì í dà nù.”
Agbára Tó Wà Nínú Fífi Àṣírí Han Ẹnì Kan
Nancy Kolodny, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, fi níní ìṣòro àṣà jíjẹun lọ́nà òdì wé “dídá nìkan bọ́ sí ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ kan, láìsí àwòrán ilẹ̀ tàbí atọ́ka, tí o kò sì mọ ibi tí àwọn ọ̀nà àbájáde wà, tí ìgbà tí wàá lè jáde níbẹ̀ kò dá ọ lójú tàbí bóyá wàá tilẹ̀ rọ́nà gbà jáde níbẹ̀. . . . Bí o ṣe ń pẹ́ níbẹ̀ tó ló ń dàrú mọ́ ẹ lójú, ló sì ń sú ọ bí o ti ń gbìyànjú láti jáde níbẹ̀.” Bí o bá ń rí àwọn àmì ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra tàbí ìyánnújù fún oúnjẹ, nígbà náà, o nílò ìrànlọ́wọ́. O kò lè dá jáde kúrò nínú “ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ” náà. Nítorí náà, fi àṣírí han ọ̀kan lára àwọn òbí rẹ tàbí àgbàlagbà mìíràn tí o fọkàn tán. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Púpọ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí irú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó ṣeé fọkàn tán bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni. Lóòótọ́, àwọn alàgbà kì í ṣe oníṣègùn, ìrànwọ́ tí wọn yóò ṣe kò sì ní dípò ìrànlọ́wọ́ tí oníṣègùn yóò ṣe. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn alábòójútó Kristẹni kò ní kọtí ikún sí “igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀,” ìmọ̀ràn àti àdúrà wọn sì lè ṣèrànwọ́ láti “mú aláàárẹ̀ náà lára dá.”—Òwe 21:13; Jákọ́bù 5:13-15.
Bí ó bá ń ni ọ́ lára láti fi àṣírí hàn ẹnì kan lójúkojú, kọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ ránṣẹ́ nínú lẹ́tà, kí o sì béèrè fún ìdáhùn. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o bá ẹnì kan jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Nancy Kolodny kọ̀wé pé: “Nípa mímọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́ pé o kò lè dá kojú rẹ̀ mọ́, ó túmọ̀ sí pé o ń kó wọnú àdéhùn láti gbà pé kí ẹlòmíràn máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ìsinsìnyí lọ.” Ó fi kún un pé: “Èyí lè jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ṣòro fún ọ láti ronú lé lórí àti láti gbé, ṣùgbọ́n wọ́n ṣeé mú lò, wọ́n jẹ́ irú èyí tí yóò darí rẹ sí ọ̀nà tó yẹ tí o lè gbà jáde níbi ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ náà.”
Àwọn èwe Kristẹni ní ohun pàtàkì mìíràn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́—àdúrà. Gbígbàdúrà sí Ọlọ́run kì í ṣe ọgbọ́n ìfini-lọ́kànbalẹ̀ kan. Ó jẹ́ ọ̀nà gidi tí ó sì ṣe pàtàkì láti bá Ẹlẹ́dàá sọ̀rọ̀, ẹni tí ó mọ̀ ọ́ dáadáa ju bí o ṣe mọ ara rẹ lọ! (1 Jòhánù 3:19, 20) Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tí ì tó àkókò tí Jèhófà yóò palẹ̀ gbogbo àìsàn mọ́ kúrò nílẹ̀, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ lè darí ìṣísẹ̀ rẹ kí o má bàa ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. (Sáàmù 55:22) Láti inú ìrírí tí Dáfídì onísáàmù náà fúnra rẹ̀ ní, ó kọ̀wé pé: “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi. Ẹni yìí tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ sì gbọ́. Ó sì gbà á là nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.”—Sáàmù 34:4, 6.
Nígbà náà, ṣàlàyé ìmọ̀lára rẹ fún Jèhófà Ọlọ́run lọ́nàkọnà. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: ‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé e, nítorí ó bìkítà fún ọ.’ (1 Pétérù 5:7) Láti fi ìmọrírì hàn fún inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o kò ṣe fara balẹ̀ ka Sáàmù orí 34, 77, 86, 103, àti 139? Ṣíṣàṣàrò nínú àwọn sáàmù wọ̀nyí yóò mú kí o túbọ̀ ní ìdánilójú pé Jèhófà jẹ́ olódodo, ó sì ń fẹ́ kí o ṣàṣeyọrí. Nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wàá ní irú ìmọ̀lára tí Dáfídì ní, nígbà tó ṣàkọsílẹ̀ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá ń ṣàníyàn tí mo sì ń dààmú, ìwọ ń tù mí nínú o sì ń mú mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.”—Sáàmù 94:19, Today’s English Version.
Ní Sùúrù—Díẹ̀díẹ̀ Ni Wàá Kọ́fẹ Padà
Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a ń ṣèrànwọ́ fún nítorí ìṣòro àṣà jíjẹun lọ́nà òdì kì í kọ́fẹ padà ní ọ̀sán-kan-òru-kan. Gbé ọ̀ràn Jaimee, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ yẹ̀ wò. Kódà lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀ sí í ràn án lọ́wọ́, ó ṣì ń ṣòro fún un láti parí ògì ẹ̀kún abọ́ kan. Ó sọ pé: “Ńṣe ni mo ní láti máa wí fún ara mi pé ohun tó dára fún mi nìyí, mo sì nílò oúnjẹ kí n má bàa kú. Ńṣe ló ń jọ pé ẹ̀kún ṣíbí kọ̀ọ̀kan tí mo ń jẹ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún pọ́n-ùn [ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlógíráàmù].”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí Jaimee fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ nígbà kan, ó pinnu láti ṣẹ́gun ọ̀ràn oúnjẹ tó ń gbà á lọ́kàn. “Mi ò ní kú. Màá bá àṣà yìí jà, màá sì ṣẹ́gun ẹ̀. Màá ṣẹ́gun ìṣòro àìjẹunkánú nítorí ìbẹ̀rù sísanra. Kò ní rọrùn o, àmọ́ màá ṣe é.” Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìwọ̀nba oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé àti ìwọ̀n eré ìmárale tó yẹ lè ṣèrànwọ́ láti máà jẹ́ kí o sanra jù