ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 7/8 ojú ìwé 3
  • Ewu Wo Ló Wà Nínú—Bí O Ṣe Ń Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ewu Wo Ló Wà Nínú—Bí O Ṣe Ń Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Tó Sàn Jù Ha Ni Bí?
  • Ọ̀ràn Ìlera Ti Sunwọ̀n Sí i Jákèjádò Ayé—Àmọ́ Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jàǹfààní Rẹ̀
    Jí!—1999
  • Bóo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—1999
  • Ǹjẹ́ Ó Tiẹ̀ Yẹ Kó O Máa Ṣeré Ìmárale?
    Jí!—2005
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 7/8 ojú ìwé 3

Ewu Wo Ló Wà Nínú—Bí O Ṣe Ń Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ?

LÓRÍṢIRÍṢI ọ̀nà ló fi jẹ́ pé ipò ìlera kò tíì dáa tó yìí rí. Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) gbé jáde lọ́dún 1998 sọ pé: “Ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ló ń gbádùn ètò àbójútó ìlera, omi tó dáa àti ètò ìmọ́tótó, bó ti wù kó kéré mọ.” Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ayé ló jẹ́ mẹ̀kúnnù, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Iléeṣẹ́ Ìròyìn Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti ròyìn, “ipò òṣì lágbàáyé ti lọọlẹ̀ gan-an ní àádọ́ta ọdún tó kọjá ju bó ṣe lọọlẹ̀ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn.”

Ètò ìṣègùn tó gbé pẹ́ẹ́lí sí i lágbàáyé ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kún iye ọdún tó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn lò láyé láti ìgbà ìbí wọn. Ní 1955, ọdún méjìdínláàádọ́ta ló ṣeé ṣe kí ìwàláàyè gùn mọ. Nígbà tó máa fi di ọdún 1995, ó ti fò sókè lọ sí ọdún márùnlélọ́gọ́ta. Ọ̀kan lára ìdí tí ìwàláàyè fi ń gùn sí i ni pé ọ̀pọ̀ àrùn tí ń yọ àwọn ọmọdé lẹ́nu la ti gbógun tì.

Ní kìkì ogójì ọdún sẹ́yìn, ikú àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún márùn-ún jẹ́ ìpín ogójì nínú ìpín ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tó kú. Ṣùgbọ́n, lọ́dún 1998, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tó wà lágbàáyè ló gba àjẹsára lòdì sí àwọn àmódi ńlá tí ń kọlu ọmọdé, àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí sì ṣiṣẹ́ gan-an. Fún ìdí yìí, iye àwọn ọmọ tó kú kí wọ́n tó pé ọdún márùn-ún ti wá sílẹ̀ sí ìpín mọ́kànlélógún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tó kú. Gẹ́gẹ́ bí àjọ WHO ti wí, “kokooko lara àwọn èèyàn ń le sí i, tí ẹ̀mí wọ́n sì ń gùn sí i.”

Àmọ́ o, báwọn èèyàn bá túbọ̀ ń pẹ́ láyé ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé rádaràda layé wọn rí, a jẹ́ pé òfo ni gbogbo àṣeyọrí táa ń pariwo kiri. Nítorí kí nǹkan lè dáa yìí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lépa àwọn nǹkan fàájì kiri. Ṣùgbọ́n irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ní àkóbá tó ń ṣe fún ìlera.

Ìgbésí Ayé Tó Sàn Jù Ha Ni Bí?

Àwọn ìyípadà lẹ́nu àìpẹ́ yìí nínú ìṣúnná owó láwùjọ ti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn padà lọ́nà tó pabanbarì. Ó ti wá ṣeé ṣe báyìí fáwọn èèyàn tí ń gbé àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà láti rówó ra àwọn nǹkan tọ́wọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ nìkan ń tó tẹ́lẹ̀ rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ lára ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí ti ṣílẹ̀kùn àǹfààní láti túbọ̀ pẹ́ láyé, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ayé ìjẹkújẹ tó lè ṣekú pa wọ́n.

Fún àpẹẹrẹ, ẹgbàágbèje àwọn èèyàn ló ń fi owó púpọ̀ sí i tí ń wọlé fún wọn ra ìràkurà bí oògùn líle, ọtí líle, àti tábà tí wọ́n ń sọ di bárakú. Ó mà ṣe o, a kúkú mọ ohun tó ń yọrí sí. Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Ìṣòro ìlera tí ń gbilẹ̀ jù lọ lágbàáyé kì í ṣe èyí tí àrùn ń fà, bí kò ṣe ohun tí iléeṣẹ́ kan ń ṣe jáde.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé: “Láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, àìsàn tí tábà ń fà lè pọ̀ ju àrùn tí ń gbèèràn lọ, kó sì di ewu gíga jù lọ sí ìlera ẹ̀dá ènìyàn kárí ayé.” Ìyẹn nìkan kọ́, ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Ó ń ṣeni ní háà láti gbọ́ pé sìgá mímu ló ń fa ìpín ọgbọ̀n nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn àrùn jẹjẹrẹ tí ń pani, pẹ̀lúpẹ̀lù, irú ìgbésí ayé téèyàn ń gbé, pàápàá irú oúnjẹ téèyàn ń jẹ àti àìṣe eré ìdárayá tún máa ń fa iye ikú tó pọ̀ tó yẹn tí àrùn jẹjẹrẹ ń ṣokùnfà.”

Láìsí àní-àní, ọ̀nà táa bá yàn láti gbà gbé ìgbésí ayé wa yóò ní ipa pàtàkì lórí ìlera wa. Báwo wá ni a ṣe lè mú kí ìlera wa sunwọ̀n sí i? Ǹjẹ́ irú oúnjẹ táa ń jẹ àti eré ìdárayá nìkan tó? Ní àfikún sí i, ipa wo làwọn kókó tó jẹ mọ́ èrò orí àti tẹ̀mí ń kó nínú ọ̀nà ìgbésí ayé tó lè mú ìlera wa sunwọ̀n sí i?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́