Àwọn Irúgbìn Tó Sèso Lẹ́yìn Ọ̀pọ̀ Ọdún
A rí lẹ́tà tó tẹ̀ lé e yìí gbà lẹ́yìn tẹ́nì kan ka àpilẹ̀kọ náà “Ìpèníjà àti Ìbùkún Tó Wà Nínú Títọ́ Ọmọkùnrin Méje,” tó jáde nínú “Jí!” ti February 8, 1999.
Arákùnrin àti Arábìnrin Dickman mi ọ̀wọ́n,
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ìtàn yín tán ni, mo sì ronú pé mi ò gbọdọ̀ má kọ lẹ́tà yìí sí yín. Mo mọ ìdílé yín nígbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Mississippi [1960 sí 1961]. Kódà, iléèwé kan náà lèmi àtàwọn ọmọ yín lọ, mo sì máa ń wá bá àwọn ọmọ yín ṣeré nílé yín dáadáa. Ṣùgbọ́n ìyẹn kọ́ ló wọ èmi ọmọ kékeré yẹn lọ́kàn jù lọ. Àní bí mo ṣe kéré tóo nì, ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an pé àwọn ọmọ yín kì í kí àsíá níléèwé nítorí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ìjọ Onítẹ̀bọmi ti Grandview ni mí, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ yín ṣàlàyé ìdí tóun fi mú ìdúró yẹn fún mi, mo mọ̀ pé ó tọ̀nà.
Ọ̀kan lára wọn fún mi ní ìwé náà Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada,a àbí kí n kúkú sọ pé mo jí i. Mi ò rántí èyí tó jẹ́ nínú méjèèjì, ṣùgbọ́n mo kà á láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Nígbà yẹn, ìwé ìtàn àkàgbádùn lásán ni mo kà á sí. Ṣé mi ò kúkú fura pé a ti gbin irúgbìn òtítọ́ sínú mi, tí yóò sì wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Ìdílé mi ṣí lọ sí Àríwá lọ́dún 1964, mi ò sì lọ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Àgàbàgebè ẹ̀sìn tojú sú mi, ìyẹn ló fi jẹ́ pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, n kò fẹ́ ní nǹkan kan-án ṣe pẹ̀lú ètò ẹ̀sìn èyíkéyìí.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú gidigidi nípa ète ìgbésí ayé, mo rí i pé ó yẹ kí n ní ìbátan pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Mo fẹ́ ní ìbátan yẹn, ṣùgbọ́n n kò fẹ́ àgàbàgebè ẹ̀sìn. Àwọn irúgbìn òtítọ́ wọ̀nyẹn, táa ti gbìn sínú mi lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí hù; mi ò tilẹ̀ tíì mọ̀ nígbà yẹn.
Mo sáà ń ronú ṣáá lórí òtítọ́ náà pé n kò fẹ́ lọ sọ́run; orí ilẹ̀ ayé níbí ni mo fẹ́ máa gbé. Lójú tèmi, pílánẹ́ẹ̀tì yìí jẹ́ àgbàyanu ìṣẹ̀dá tó gbámúṣé, kí wá ni ìdí tí Ọlọ́run yóò fi pa á rẹ́? Pẹ̀lúpẹ̀lù, mi ò gbà pé Jésù ni Ọlọ́run. Bó bá ṣe pé òun ni Ọlọ́run, á jẹ́ pé ẹ̀tàn gbáà ni ìrúbọ tó lóun ṣe. Èrò àti ìmọ̀lára àti ìgbàgbọ́ wọ̀nyí, báa bá lè pè wọ́n ní ìgbàgbọ́, kò bára mu rárá pẹ̀lú ohun tí mo kọ́ nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà, àní àdúrà gidi, Jèhófà sì gbégbèésẹ̀ kánkán. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá kanlẹ̀kùn mi lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ sígbà yẹn, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣalábàápàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà látìgbà tí mo ti mọ ìdílé yín títí dìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, mi ò kóyán àwọn ọmọ yín kéré rárá, mo sì bọ̀wọ̀ fún wọn gan-an nítorí ìgboyà wọn láti dúró lórí òtítọ́. Gbàrà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ mi bẹ̀rẹ̀, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gba ìmọ̀, ni ojú mi ti là peregede. Ó gbà mí lọ́dún kan àtààbọ̀ láti tún ìgbésí ayé mi tò. Níkẹyìn, mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1975.
Ìgbàkigbà táa bá ń jíròrò nípa bí ìwà wa ṣe lè jẹ́ ẹ̀rí láìtilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀, ni mo máa ń ronú kan ìdílé yín. Nígbà táa bá ń jíròrò nípa ìjẹ́pàtàkì gbígbin ọ̀pọ̀ irúgbìn Ìjọba náà nítorí pé a kì í sábàá mọ èyí tí yóò ta gbòǹgbò, mo mọ̀ látinú ìrírí tara mi bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó.
Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún jíjẹ́ tẹ́ẹ jẹ́ ara àwọn èèyàn Jèhófà, tẹ́ẹ sì ń fi ìgbàgbọ́ yín ṣèwà hù nígbà yẹn. Láìmọ̀, ẹ ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti rí òtítọ́. Ìwà àti ìgbàgbọ́ yín, àti tàwọn ọmọ yín, jẹ́ kí òtítọ́ tàn dé inú ọkàn mi. Tẹ́lẹ̀, èrò mi ni pé kò sí bí mo tún ṣe lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí yín mọ́, tàbí bí mo ṣe lè dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Mo dúpẹ́, mo tún ọpẹ́ dá o.
Pẹ̀lú ìfẹ́ Kristẹni àtọkànwá,
L. O.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ ìwé yìí jáde lọ́dún 1958; kò sí nílẹ̀ báyìí.