Ìsìn Ń Wọ̀ọ̀kùn ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
ÌWÉ ìròyìn The Sunday Times tìlúu London ròyìn pé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ń pa àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńláńlá tì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìjọ Àgùdà ti pàdánù nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] ọmọ ìjọ láti ọdún 1980, bákan náà, àwọn tó máa ń wá jọ́sìn ní Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—tó ṣì ń pàdánù ẹgbẹ̀ta ọmọ ìjọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀—kì í pọ̀ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́, iye yìí kò tó ìlàjì àwọn tó máa ń wá ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn àlùfáà ọkùnrin ló ti fi Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ẹgbẹ́ Alákòóso Àpapọ̀ pinnu lọ́dún 1992 láti máa fi àwọn obìnrin jẹ oyè àlùfáà.
Ìwé ìròyìn The Times sọ pé ọ̀pọ̀ tó ti fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ máa ń bínú, ó sì ń dùn wọ́n pé kò tiẹ̀ sẹ́ni tó gbìyànjú láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má lọ, tàbí kẹ́nì kan tiẹ̀ wá ọ̀nà àtiràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lọ. Ìwé ìròyìn náà ṣàlàyé pé àwọn kan “sọ pé Ṣọ́ọ̀ṣì náà kò gba tàwọn rò.”
Kádínà Basil Hume, tí í ṣe bíṣọ́ọ̀bù àgbà Ìjọ Àgùdà ní Westminster, kéde pé “ìṣúra tẹ̀mí àti ti ìwà rere ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ tán” láwùjọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Kí ló ń fà á gbẹ? Àkọlé kan nínú ìwé ìròyìn Catholic Herald sọ pé “Ìyàn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni. Ó ṣàlàyé pé: “Ohun tí wọ́n ń kà fún wa nígbà Máàsì kò ju àyọkà díẹ̀ látinú Májẹ̀mú Láéláé àti Tuntun, ṣùgbọ́n wọn kì í sábàá ṣàlàyé ohun tí wọ́n kà. . . . Ìtàn àwọn ẹni mímọ́ àti onírúurú ìwé tó dá lórí nǹkan tẹ̀mí dára, àmọ́ ìwọ̀nba ni ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n lè ṣe láti la Ìwé Mímọ́ yéni.” Àpilẹ̀kọ yìí wá parí ọ̀rọ̀ sí pé “gbígbé ọ̀rọ̀ Bíbélì kalẹ̀ lọ́nà tó bóde mu, pẹ̀lú àbójútó tẹ̀mí lọ́kàn,” kò sí mọ́.
Nínú lẹ́tà tí òǹkàwé kan kọ sí ìwé ìròyìn Boston Target tìlúu Lincolnshire, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn ò fọkàn tán ẹ̀sìn mọ́ o . . . Iṣẹ́ wo làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí tilẹ̀ ń rí ṣe látàárọ̀ ṣúlẹ̀? Kì í kúkú ṣe pé wọ́n ń jáde lọ bá àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe . . . Ẹ̀sìn kan ṣoṣo tó jọ pé ó bìkítà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ló máa ń lọ bá àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ń fi tọkàntara wàásù òtítọ́—wọ́n á tún ní kóo wá bá àwọn ṣèpàdé, ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n tún ń sọ̀rọ̀ nípa àyíká wa, wọ́n sì ń wá nǹkan ṣe sí i. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ni mí o, ṣùgbọ́n mo gbédìí fáwọn èèyàn wọ̀nyí, mo sì máa ń tẹ́tí sí wọn.”
Ǹjẹ́ o ti lọ sípàdé wọn rí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ? Ibẹ̀ lo ti máa gbọ́ ìtọ́ni tó wúni lórí, tó sì ṣàǹfààní. Ṣé o fẹ́ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tóo ní nínú Bíbélì? Lọ́dún tó kọjá, ní igba ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ilẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo wákàtí tó ju bílíọ̀nù kan lára àkókò wọn lọ́fẹ̀ẹ́, láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì, wọ́n sì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tó ju mílíọ̀nù mẹ́rin lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ lákòókò yìí. A fẹ́ kíwọ náà mọ̀dí àbájọ.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.