ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 9/8 ojú ìwé 9-11
  • Ọjọ́ Ọ̀la Aláàbò Níkẹyìn!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Aláàbò Níkẹyìn!
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Lájorí Ohun Tó Fà Á
  • Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Jákèjádò Ayé Lábẹ́ Ìjọba Àgbáyé
  • “Ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti Ààbò”
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ogun Tí Wọ́n Á Fi Bọ́ǹbù Átọ́míìkì Jà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ Ewu Agbára Átọ́míìkì A Ti Fòpin sí I Pátápátá!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
    Jí!—2004
  • Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Kí Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Má Jà?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 9/8 ojú ìwé 9-11

Ọjọ́ Ọ̀la Aláàbò Níkẹyìn!

“Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.”—AÍSÁYÀ 14:7.

“AYÉ wa yìí jẹ́ ayé àwọn alágbára olóhun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ ọwọ́ ní ti ìwà ọmọlúwàbí. Ohun tí a mọ̀ nípa ogun pọ̀ ju ohun tí a mọ̀ nípa àlàáfíà lọ, a mọ̀ nípa ìpànìyàn ju ìwàláàyè lọ.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, tí Ọ̀gágun Àgbà kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ ní ọdún 1948, rán wa létí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tó wà nínú Bíbélì pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Bí àwọn èèyàn bá ní àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lọ́wọ́, wọ́n lè ṣe ohun tó burú ju pípa ọmọnìkejì wọn lára lọ; wọ́n lè pa wọ́n run ráúráú!

Síbẹ̀, aráyé kò mọ bí òun ṣe lè kó àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé dà nù. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé níní àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lọ́wọ́ àti lílò wọ́n kò bá ìwà ọmọlúwàbí mu. Fún àpẹẹrẹ, George Lee Butler, tó ti fẹ̀yìn tì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gágun Àgbà Nínú Ẹgbẹ́ Ológun Òfuurufú Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Wíwà tí ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan bá wà níbi tí ẹnì kan to ohun ìjà sí pelemọ lásán ń fi hàn pé a lè wòye ipò kan tí a ti lè . . . ronú lọ́nà kan ṣáá pé ó bọ́gbọ́n mu láti lo ohun ìjà náà. Ìyẹn kò bójú mu rárá.”

Bó ti wù kó rí, akọ̀ròyìn Martin Woollacott, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: “Àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò yé fajú èèyàn mọ́ra, ní adúrú gbogbo ohun tí àwọn ọ̀mọ̀ràn àti àwọn tí ń ṣonígbọ̀wọ́ ìhùwà ọmọlúwàbí ń sọ nípa àìwúlò àti àléébù wọn. Àwọn ìjọba gbà gbọ́ pé àwọn nílò wọn fún ète ààbò tó bójú mu; wọ́n tún ń kó wọn jọ nítorí kò síyèméjì pé àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé jẹ́ oríṣi agbára òkùnkùn kan tó ju tẹ̀dá lọ tí àwọn òṣèlú àti àwọn ológun kà sí, tí wọ́n sì fẹ́ láti ní.”

Òótọ́ ni pé láàárín ẹ̀wádún tó kọjá, èèyàn ti gbìyànjú lọ́nà kan ṣáá láti yẹra fún ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ṣùgbọ́n láàárín àkókò yẹn kan náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n ti fi àwọn ohun ìjà tó wọ́pọ̀ pa. Tí a bá yẹ bí aráyé ti ṣe sí wò, yóò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé, láìpẹ́ láìjìnnà, wọn óò lo àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wọ̀nyí.

Àwọn Lájorí Ohun Tó Fà Á

Ǹjẹ́ a lè fòpin sí ìwà arógunyọ̀ tí aráyé ní? Àwọn kan ṣàlàyé pé àìnírònú, ìmọtara-ẹni-nìkan, àti gìràgìrà tí kò yẹ ló ń mú kí aráyé máa jagun. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Kenneth Waltz sọ pé: “Bó bá ṣe pé ìwọ̀nyí ni lájorí ohun tó ń fa ogun, nígbà náà a gbọ́dọ̀ lè mú ogun kúrò nípa mímú ipò ẹ̀dá sunwọ̀n sí i, kí a sì là wọ́n lóye.”

Àwọn mìíràn sọ pé ohun tó ń fa ogun kò ṣẹ̀yìn ètò ìṣèlú àgbáyé. Nítorí pé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan tó wà lómìnira ń lépa ire ìjọba tirẹ̀, kò sọ́gbọ́n tí ìforígbárí ò ní sí. Níwọ̀n bí kò ti sí ọ̀nà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tó ṣeé gbíyè lé tí a lè gbà yanjú aáwọ̀, ńṣe logun ń bẹ́ sílẹ̀. William E. Burrows àti Robert Windrem kọ ọ́ nínú ìwé wọn tó ń jẹ́ Critical Mass pé: “Ọ̀ràn ti ìṣèlú ló burú jù níbẹ̀. Kò sí irú ìṣàkóso tó gbéṣẹ́ tó lè kẹ́sẹ járí láìsí ìfohùnṣọ̀kan ìtìlẹ́yìn olóṣèlú láti dáwọ́ títo àwọn ohun ìjà alágbára jọ dúró tàbí láti mú un kúrò pátápátá.”

Ronú nípa àwọn ìjíròrò tó ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàmúlò Àdéhùn Fífòfinde Dídán Gbogbo Ohun Ìjà Wò. Ìwé ìròyìn Guardian Weekly ṣàpèjúwe wọn bí “ìfèròwérò gbígbónájanjan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ògbóǹtarìgì àti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ní bòókẹ́lẹ́ tàbí tí wọ́n ní ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n lè fi ṣe wọ́n kíákíá.” Àpilẹ̀kọ kan náà sọ pé: “Kò sí èyíkéyìí lára [ẹgbẹ́] méjèèjì tó ń wéwèé láti jọ̀wọ́ ohun ìjà wọn tàbí agbára wọn, tàbí láti jáwọ́ nínú gbogbo ohun tí a là sílẹ̀ fún wọn láti mú kí ohun ìjà wọn tàbí agbára wọn sunwọ̀n sí i.”

Ó hàn gbangba pé ó pọn dandan kí àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bí a óò bá fòpin sí gbogbo ewu tó ń bá ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé rìn. Ìwé Critical Mass sọ pé: “Bó bá jẹ́ pé káàkiri àgbáyé ni a ti ń to àwọn ohun ìjà alágbára jọ, bó ṣe yẹ kí ìgbìyànjú láti yí i padà náà ṣe rí nìyẹn. Ìgbẹ́kẹ̀lé tọ̀túntòsì sì gbọ́dọ̀ rọ́pò ìlérí ìparun tọ̀túntòsì níbi gbogbo, . . . bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àjálù yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà.” Ó dunni pé àjọṣepọ̀ àti àdéhùn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé lónìí sábà máa ń dà bí ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe ní ọ̀rúndún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn pé: ‘Wọ́n ń pa irọ́ lórí tábìlì kan náà.’—Dáníẹ́lì 11:27, Byington.

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Jákèjádò Ayé Lábẹ́ Ìjọba Àgbáyé

Bó ti wù kó rí, Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pète ojúlówó ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jákèjádò ayé lábẹ́ ìjọba àgbáyé tó gbéṣẹ́. Láìmọ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti gbàdúrà fún ìṣàkóso yìí nígbà tí wọ́n ń ka Àdúrà Olúwa pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ìjọba jẹ mọ́ ọ̀ràn àkóso. Àti pé Jésù Kristi, Ọmọ Aládé Àlàáfíà ni Olórí nínú Ìjọba yẹn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin . . . Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” (Aísáyà 9:6, 7) Bíbélì ṣèlérí nípa ìjọba yẹn lábẹ́ Jésù pé: “Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú,” tàbí àwọn ìṣàkóso ènìyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.

Ìjọba àgbáyé tí a ń sọ yìí yóò mú àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ wọlé wá—ṣùgbọ́n kì í ṣe nípasẹ̀ fífi ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé halẹ̀ mọ́ni tàbí nípasẹ̀ àwọn àdéhùn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun ìjà. Sáàmù 46:9 sọ tẹ́lẹ̀ pé, Jèhófà Ọlọ́run “mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.” Àwọn ìwéwèé tó ń pọ̀n sápá kan kò ní wúlò rárá. Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Kristi yóò ṣe ju dídín iye àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kù lọ—yóò palẹ̀ àwọn àti gbogbo àwọn ohun ìjà ogun mìíràn mọ́ kúrò nílẹ̀.

Kò ní sí ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí ń wuni léwu nítorí pé kò ní sí àwọn alágbára ńlá, kò ní sí àwọn orílẹ̀-èdè oníjọ̀ngbọ̀n, kò ní sí àwọn apániláyà. Àlàáfíà tòótọ́ yóò borí: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.” Ọlọ́run tí kò lè purọ́ ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a mí sí yìí.—Míkà 4:4; Títù 1:2.

Bí Sáàmù 4:8 ṣe sọ, inú ìṣètò Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni a ti lè rí àlàáfíà àti ààbò tòótọ́, ó wí pé: “Àlàáfíà ni èmi yóò dùbúlẹ̀, tí èmi yóò sì sùn, nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, nìkan ṣoṣo ni ó mú kí n máa gbé nínú ààbò.” Bí ìrora gógó tó bá ìtàn aráyé rìn ṣe fi hàn, ayédèrú gbáà ni ìlérí èyíkéyìí tí àwọn èèyàn bá ń ṣe nípa “àlàáfíà àti ààbò,” àyàfi èyí tó bá jẹ́ nípasẹ̀ Ìjọba Jèhófà.—Fi wé 1 Tẹsalóníkà 5:3.

“Ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti Ààbò”

Ṣùgbọ́n ìwà arógunyọ̀ tó wà lára èèyàn ńkọ́? “Òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.” (Aísáyà 26:9) Irú òdodo kíkọ́ bẹ́ẹ̀ yóò ní ipa púpọ̀ lórí ìwà ẹ̀dá àti ipò ayé: “Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà; iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 32:17) Ìfẹ́ aládùúgbò ẹni àti àníyàn fún ire gbogbo èèyàn yóò rọ́pò ìwà jàgídíjàgan tàbí ìwà ipá èyíkéyìí. Àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé “yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó yí àwọn èèyàn oníwà bí ẹranko padà. Ó sọ nípa àkókò tí “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, “ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. . . . Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi.”—Aísáyà 11:6-9.

Ìgbàgbọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nínú àwọn ìlérí àtọ̀runwá wọ̀nyí ló ń mú kí a ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára nínú ìgbésí ayé wa. Nígbà tí a bá ronú nípa ọjọ́ iwájú, a kì í ronú nípa ilẹ̀ ayé tí a ti parun di ahoro. Kàkà bẹ́ẹ̀, a rí ìmúṣẹ ìlérí Bíbélì pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Àwọn kan á pe níní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ní ìwà àìmọ̀kan àti àìlọ́gbọ́n-nínú. Ṣùgbọ́n ta ni àìmọ̀kan ń bá jà ní ti gidi? Ṣé ẹni tó gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ ni àbí ẹni tó gba ìlérí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí àwọn òṣèlú ń ṣe gbọ́ láìjanpata? Ìdáhùn ìbéèrè náà ṣe kedere sí àwọn olùfẹ́ àlàáfíà.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn Bíbélì tí ń fúnni ní ìrètí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. O lè ṣètò kí wọ́n wá bẹ̀ ọ́ wò nípa kíkàn sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí tàbí nípa lílọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4

[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn ìdílé yóò máa “gbé ní ààbò,” a ó sì mú gbogbo onírúurú ohun ìjà kúrò pátápátá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

A óò mú àwọn ìwà arógunyọ̀ kúrò bí àwọn èèyàn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fi í sílò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́