ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 9/8 ojú ìwé 20-21
  • Wọ́n Pinnu Láti Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Pinnu Láti Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrètí Àjíǹde Mú Ẹsẹ̀ Mi Dúró
  • Kò Juwọ́ Sílẹ̀
    Jí!—1999
  • Ìrètí Àjíǹde Dájú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Nínú Àjíǹde Ṣe Jinlẹ̀ Tó Lọ́kàn Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • “Arákùnrin Rẹ Máa Dìde”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 9/8 ojú ìwé 20-21

Wọ́n Pinnu Láti Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀

ÌWÉ ìròyìn Jí!, January 8, 1999 gbé àpilẹ̀kọ kékeré kan jáde nípa ìṣòro àrùn jẹjẹrẹ tí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tí ń jẹ́ Matt Tapio ní. Àkọlé àpilẹ̀kọ náà ni “Kò Juwọ́ Sílẹ̀.” Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Matt kú ní April 19, 1998, nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ lórí àpilẹ̀kọ náà lọ́wọ́.

Àpilẹ̀kọ náà fa ọ̀rọ̀ Matt yọ, èyí tó sọ nígbà ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò tí a ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ tí a wá tẹ́tí sí ní ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì ṣí àwọn ọ̀dọ́ tó kà á lórí. Díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí ń fi bí ìmọ̀lára wọn ṣe rí hàn nìyí.

Deseree, ọmọ ogún ọdún láti Kánádà, kọ̀wé nípa bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí òun àti ẹnì kejì òun nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kà nípa bí Matt ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó pé: “Ńṣe la bú sẹ́kún. A sì ń sunkún. Gbogbo wa, pàápàá àwa ọ̀dọ́, lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Matt láti ‘ṣe ohun tí a bá lè ṣe nísinsìnyí! . . . Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ má ṣe ṣíwọ́ wíwàásù nípa Jèhófà’!”

Erin, láti Kentucky, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, kọ̀wé pé: “Ńṣe ni mo ń sunkún bí mo ṣe ń ka ìrírí rẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tí ara mi dá ṣáṣá, mo fẹ́ sa gbogbo ipá mi láti sin Jèhófà nígbà tí mo lè sìn ín, kó bàa lè jẹ́ pé lọ́jọ́ kan tí Matt bá jíǹde, màá lè sọ bí ìrírí rẹ̀ ṣe fún mi níṣìírí tó fún un.” Bákan náà, Maria, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti Texas, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ṣàlàyé pé: “Mo ti pinnu láti sa gbogbo ipá mi láti sin Jèhófà níwọ̀n ìgbà tí ara mi bá ṣì yá gágá. Ìmọ̀ràn Matt ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”

Jessica, èwe kan láti South Carolina, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí, ó sì jẹ́ ìṣírí gidigidi fún èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan láti rí i tí èwe mìíràn ní ìtara gan-an bẹ́ẹ̀ tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kìkì kíkà nípa ipò tí Matt Tapio wà mú kí n wá mọ bí ìlera tí mo ní ṣe jẹ́ ìbùkún ńláǹlà fún mi. Mo ti kọ orúkọ Matt sára orúkọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ti mo ní lọ́kàn láti kí káàbọ̀ nínú ètò tuntun!”

Sara, láti San Severino Marche, Ítálì, kọ̀wé pé: “Àpilẹ̀kọ náà mú mi bú sẹ́kún. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mí, ẹgbẹ́ lèmi àti Matt. Níwọ̀n bí ara mi ti yá gágá, ó jẹ́ ìfẹ́ mi láti má ṣe ṣíwọ́ sísọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, bí Matt kò ti ṣíwọ́ sísọ ọ́, kódà ní àkókò tó ṣòro jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ẹ ṣeun tí ẹ ń tẹ ìrírí irú èyí jáde, ó ń mú kí a lè lo ìgbésí ayé wa, àkókò wa, àti agbára wa dáradára nínú iṣẹ́ Jèhófà.—Oníwàásù 12:1.”

Ìrètí Àjíǹde Mú Ẹsẹ̀ Mi Dúró

Yálà èèyàn jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, lónìí, ó wọ́pọ̀ pé a máa ń rí i tí èèyàn ń kú. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Heidi sọ pé: “Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tó kọjá, méjì lára àwọn tó sún mọ́ mi gan-an ló ti kú, ohun kan ṣoṣo tó sì ń fún mi níṣìírí ni ìrètí rírí wọn nígbà àjíǹde.

“Inú mi dùn gan-an sí Matt àti ipò ìdúróṣinṣin tó mú láti máa wàásù fún àwọn ẹlòmíràn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ kò yá. Àpẹẹrẹ gidi ló jẹ́ fún gbogbo wa, mo sì ń fojú sọ́nà láti gbá a mọ́ra nígbà àjíǹde.”

Ìyá kan tó ń jẹ́ Nancy kọ̀wé pé: “Pẹ̀lú omijé ni mo ka àpilẹ̀kọ náà. Ohun kan wú sínú ọpọlọ ọmọbìnrin wa Rachelle, òun ló pa á ní January 11, 1996, ọjọ́ méjì ṣáájú kí Matt tó ṣàṣeyọrí láti ṣèrìbọmi. Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni Rachelle nígbà tí nǹkan náà gba ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n bíi ti Matt, kò juwọ́ sílẹ̀, ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú inú Jèhófà dùn nígbà gbogbo.

“Ọjọ́ ńlá ni yóò jẹ́ nígbà tí Jèhófà yóò ṣe wá lógo láti rí ọmọbìnrin wa tí ara rẹ̀ yá gágá, tí yóò sì lè gbádùn ìgbà ọmọdé rẹ̀ ní kíkún. Bíi ti Jáírù àti aya rẹ̀, a lè má mọ ohun táà bá ṣe, nítorí tí ‘ayọ̀ náà á pọ̀ jọjọ.’”—Máàkù 5:42.

Shannon, láti Georgia, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, kọ̀wé pé: “Ìtàn yìí kọ́ mi pé èèyàn lè di alágbára nítorí ti Jèhófà kódà bí ó bá ń ṣàìsàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn pàtó kan ò ṣe mí báyìí, ara mi sì máa ń yá gágá, màá tọ́jú èyí kí n lè kà á tó bá yá.

“Mo lérò pé ìrètí àjíǹde yóò tu àwọn òbí Matt nínú. Ẹnì kan tó sún mọ́ èmi náà kú ní 1995—ìyá ìyá mi ni ẹni náà. Inú mi dùn gan-an pé mo mọ Jèhófà àti pé mo ní ìrètí àtirí àwọn èèyàn mi lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Ọ̀dọ́langba ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan kọ̀wé pé: “Àwọn òbí mi tẹ ìjẹ́pàtàkì lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni mọ́ èmi àti àwọn arábìnrin mi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin lọ́kàn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo ka ìrírí yìí, mo wá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí èèyàn fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀ràn ìpàdé lílọ. Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí Matt pé wọ́n kọ́ ọ dáadáa nípa tẹ̀mí. Àpẹẹrẹ ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo wa. Mo fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti fara da irú àdánù yìí, Jèhófà kò fìgbà kan fi wá sílẹ̀.

“Mo nírètí pé màá pàdé Matt nínú ayé tuntun. Mo fẹ́ sọ fún un pé àpẹẹrẹ gidi ló jẹ́ àti pé gbogbo wa la ń rántí rẹ̀ nínú ọkàn wa. Ọlọ́run àwọn alààyè ni Jèhófà jẹ́, ibi tí àbúrò mi obìnrin tó kú lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn wà ni Matt wà nísinsìnyí—nínú ìrántí Jèhófà. (Lúùkù 20:38) Matt, Eva, tó jẹ́ àbúrò mi, àti ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ wà níbẹ̀. Jèhófà mà dára o, òun kò sì ní ta wá nù láé.”

Lóòótọ́, ìrètí àjíǹde jẹ́ àgbàyanu. Ǹjẹ́ kí ó jẹ́ ohun iyebíye sí wa, kí a sì fìmọrírì hàn fún ìlérí kíkọyọyọ yìí nípa rírántí Ẹlẹ́dàá wa lójoojúmọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, ti ṣe.

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 20]

Deseree

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 20]

Erin

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 20]

Maria

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 20]

Jessica

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 21]

Sara

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 21]

Heidi

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 21]

Nancy, pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ àti ọmọ wọn, Rachelle

[Àwọn tó wà ní ojú ìwé 21]

Shannon

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́