Ẹ̀pà Lílọ̀—Bí Wọ́n Ṣe Ń ṣe é Ní Áfíríkà
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA ÀÁRÍN GBÙNGBÙN ÁFÍRÍKÀ
NÍ ÀWỌN orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ojú ohun tí a ń nà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ sórí awẹ́ búrẹ́dì jẹ lásán ni àwọn èèyàn fi ń wo ẹ̀pà lílọ̀. Àmọ́, ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, ó ń kó ipa tó túbọ̀ ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ ni wọ́n máa ń fi ẹ̀pà lílọ̀ sè. Bó ṣe ń rí ní àwọn àgbègbè mìíràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kì í rọrùn láti rí ìyẹ̀fun tí wọ́n fi ń mú ọbẹ̀ ki. Òun ló fà á tó fi jẹ́ ẹ̀pà lílọ̀ ni wọ́n máa ń lò dípò rẹ̀.
Àmọ́, kì í ṣe pé a kàn lè rí agolo ẹ̀pà lílọ̀ rà ní ilé ìtajà wóróbo o. Ṣíbí ni wọ́n fi ń wọ̀n ọ́n tà, ó sì wọ́n gan-an. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ní Áfíríkà fi máa ń fẹ́ ṣe é fúnra wọn. Bí wọ́n ṣe ń ṣòpò ẹ̀ wuni gan-an. A bá àwọn obìnrin Áfíríkà mélòó kan sọ̀rọ̀ la fi rí àlàyé táa ṣe sísàlẹ̀ yìí kó jọ.
Gbígbin Ẹ̀pà
Dájúdájú, oko ẹ̀pà ò ṣòro dá. Èyí tó le jù níbẹ̀ ni títú ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ gbìn ín sí. Ìgbà tí ilẹ̀ ṣì gbẹ tó sì le níbẹ̀rẹ̀ ìgbà òjò ni wọ́n máa ń ṣe èyí. Oṣù April ni wọ́n máa ń fọwọ́ gbin kóró rẹ̀, bí òjò bá sì tètè rọ̀, wọ́n lè hú “ẹ̀pà” níparí oṣù August tàbí níbẹ̀rẹ̀ oṣù September.
Irúgbìn onípódi ni ẹ̀pà—ẹ̀yà ẹ̀wà ni. O lè rò pé igi ló ń so ẹ̀pà, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ewéko ṣúúrú kan ni irúgbìn tó ń so ẹ̀pà, ọ̀nà àrà ló sì fi ń so nínú ilẹ̀.
Ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, wọ́n lè fi ilẹ̀ tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́rùn-ún mítà níbùú àti àádọ́ta mítà lóròó gbin ẹ̀pà. Àwọn èèyàn kan máa ń gbìn ín sórí ilẹ̀ kékeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn. Ọkọ́ tí ọwọ́ ẹ̀ ò gùn àti àdá ni wọ́n sábà máa ń fi ro oko ẹ̀pà. Iṣẹ́ ẹ̀yìn gbáà sì ni iṣẹ́ náà! Irúgbìn náà gba kí wọ́n bójú tó o gan-an, pàápàá tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn ín. Ojú ò gbọ́dọ̀ kúrò nínú oko ẹ̀pà kí ikún àti àwọn ẹranko mìíràn má bàa máa hú u jẹ. Wọn kò sì ní jẹ́ kí ilẹ̀ ibẹ̀ le jù, kí igbó má sì kún bò ó.
Wọ́n ní láti fojú sí oko náà dáadáa pàápàá bí ìgbà ìkórè bá ti sún mọ́lé. Wọ́n lè ní kí àwọn ọmọ máa ṣọ́ ọ bí ìgbà àtikórè rẹ̀ bá ti ń bọ̀. Obìnrin kan sọ pé aládùúgbò òun kan sọ pé òun rí ewé ẹ̀pà òun lórí igi kan nítòsí. Àwọn ọ̀bọ ló hú u lọ jẹ lórí igi!
Gbogbo ìdílé ló sábà máa pawọ́ pọ̀ kórè rẹ̀. Gbogbo wọn á lọ sí oko láti ṣèrànwọ́. Ńṣe ni wọ́n ń fọwọ́ hú irúgbìn náà, wọ́n á sì gbé e kalẹ̀ kó gbẹ, lẹ́yìn náà, wọ́n á wá já àwọn ẹ̀pà náà, wọ́n á wá fi orí rù ú wá sí abúlé nínú bàsíà ńlá.
Lẹ́yìn náà, kí ni wọ́n máa wá ṣe sí ẹ̀pà náà? Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọ̀ ọ́, wọ́n á fiyọ̀ sí i nígbà tí wọ́n ń sè é. Ìdílé á jẹ díẹ̀ níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ wọ́n á wá tọ́jú èyí tó pọ̀ jù pa mọ́ láti fi sebẹ̀ tó bá yá. Ńṣe ni wọ́n á sá a sílẹ̀ẹ́lẹ̀ nítòsí ilé títí yóò fi gbẹ dáadáa. Wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹnì kan sídìí rẹ̀ kó máa ṣọ́ ọ kí àwọn ewúrẹ́ tí ń rìn káàkiri má bàa fi panu.
Lẹ́yìn tí ẹ̀pà náà bá gbẹ, wọ́n á dà á sí ibì kan tí wọ́n fi koríko àti amọ̀ kọ́ sórí òpó. Èyí á jẹ́ kí ara ẹ̀pà náà gbẹ, kò sì tún ní jẹ́ kí àwọn ẹranko jẹ̀pàjẹ̀pà àti àwọn ọmọdé tí ń wá ohun tí wọ́n máa fi panu nígbà tí Màmá wà nínú oko lè débẹ̀.
Bí Àsán Ẹ̀pà Ṣe Ń Di Ẹ̀pà Lílọ̀
Kí wọ́n tó lè lọ ẹ̀pà náà, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ pa á. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á yan án, èyí sábà máa ń jẹ́ nínú agbada pẹrẹsẹ, tí wọ́n gbé ka iná tí wọ́n figi dá. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí ó máa ta sánsán kí ó sì rọrùn láti bó èèpo ara rẹ̀. Wọ́n a jẹ́ kí ẹ̀pà náà tutù, wọ́n á wá bó èèpo ẹ̀. Wọ́n á wá fi ẹ̀rọ ìlọǹkan lọ ẹ̀pà náà múlọ́múlọ́. Bí kò bá sí ẹ̀rọ ìlọǹkan, ọlọ ni ìyàwó ilé á fi lọ̀ ọ́.
Láìpẹ́, wọ́n á fi ẹ̀pà lílọ̀ náà sebẹ̀ kó lè ki, inú ìṣasùn ni wọ́n sábà máa ń sè é sí, wọ́n sì máa ń fi jẹ pákí, ọ̀gẹ̀dẹ̀, tàbí ìrẹsì. Bí o bá fẹ́ mọ bí ọbẹ̀ tí wọ́n fi ẹ̀pà lílọ̀ sè ṣe rí lẹ́nu, o ò ṣe gbìyànjú kí o sè é wò?
O lè sè é bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń sè é kí o fi se ọbẹ̀ ẹran, àlùbọ́sà, aáyù, àti omi ọbẹ̀ tòmáátì. Se ẹran náà rọ̀, kí o sì da ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ sí i bóo bá fẹ́. Bí ìyẹn ti ń hó lórí iná, fi omi díẹ̀ po ẹ̀pà yíyan tí a lọ̀ náà—nǹkan bí ife kan fún ekìrí ẹran ńlá méjì—kí o sì dà á sínú ọbẹ̀ náà. Jẹ́ kó hó mọ́ra fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kí ẹ̀pà lílọ̀ náà má bàa han èèyàn lẹ́nu. Bí ọbẹ̀ náà kò bá ki tó bí o ṣe fẹ́, fi ẹ̀pà lílọ̀ díẹ̀ sí i. Fi iyọ̀ sí i bí o bá ṣe fẹ́ ẹ. Bí o bá fẹ́ kó ta, o lè fi ata rodo sí i.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé irú ọbẹ̀ yẹn máa ń dùn gan-an lórí ìrẹsì! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè má lè ṣe é dáadáa, wàá rí ọ̀pọ̀ nǹkan tí a ń fi ẹ̀pà lílọ̀ ṣe—bí wọ́n ṣe ń ṣe é ní Áfíríkà!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Wọ́n á hú ẹ̀pà, wọ́n á gbé e lọọlé, wọ́n á pa á, wọ́n á sì lọ̀ ọ́