ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 9/8 ojú ìwé 12-13
  • Kí Ni Ojúṣe Ẹni Rere Nílùú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ojúṣe Ẹni Rere Nílùú?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtẹríba Kristẹni Fáwọn Aláṣẹ
  • “Láti Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
  • ‘Ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run bí Olùṣàkóso Dípò Ènìyàn’
  • Ọlọrun àti Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsìn Kristian Ìjímìjí àti Orílẹ̀-èdè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Sísan Ohun Ti Kesari Padà fún Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ojú-Ìwòye Kristian Nípa Ọlá-Àṣẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 9/8 ojú ìwé 12-13

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Ni Ojúṣe Ẹni Rere Nílùú?

LẸ́YÌN Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ èèyàn ní Yúróòpù àti ní Japan tó ka ara wọn sẹ́ni tí ń pòfin mọ́ àti ẹni rere nílùú, ló wá jẹ́jọ́, tí wọ́n sì jẹ̀bi ẹ̀sùn híhùwà ìkà nígbà ogun. Àwọn lọ́gàálọ́gàá nínú iṣẹ́ ológun wà lára wọn, bẹ́ẹ̀ náà làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, àtàwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mìíràn. Àwíjàre àwọn ìkà ènìyàn wọ̀nyí ni pé, ẹjọ́ àwọn kọ́, ohun tí wọ́n ní káwọn ṣe làwọn ṣe, wọ́n ní ojúṣe gbogbo afẹ́lùúfẹ́re nìyẹn. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀mí ìfẹ́lùúfẹ́re tí wọ́n gbé lérí, sún wọn dédìí híhùwà ìkà tó burú jáì sọ́mọ aráyé.

Àwọn kan tún wà o, tó ṣe pé, ṣe ni wọ́n ń fọwọ́ pa idà Ìjọba lójú. Ṣe làwọn mí-ìn tiẹ̀ dìídì ń tẹ àṣẹ ìjọba lójú, àwọn mí-ìn sì rèé, wọn ò kọ̀ láti lùfin bó bá jọ pé ọwọ́ ò ní bà wọ́n. Bẹ́ẹ̀ rèé, kì í kúkú ṣe pé àwọn èèyàn gbà pé ó dáa láti tàpá sáṣẹ, torí pé ṣe ni gbogbo ìlú á dà rú, tí gbogbo nǹkan á sì dojú rú bí kò bá sí ìjọba. Ṣùgbọ́n o, ìbéèrè to wà nílẹ̀ ni pé, Ibo ló yẹ ká fọkàn sin ìlú dé, kí a sì tẹ̀ lé òfin rẹ̀ dé? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìlànà pàtàkì kan yẹ̀ wò, àwọn ìlànà tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní láti ní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa ojúṣe wọn sí Ìjọba.

Ìtẹríba Kristẹni Fáwọn Aláṣẹ

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò tàpá rárá sófin àti ìlànà “àwọn aláṣẹ onípò gíga”—ìyẹn, àwọn tí ń ṣàkóso nígbà yẹn. (Róòmù 13:1) Àwọn Kristẹni gbà gbọ́ pé ó yẹ láti “wà ní ìtẹríba àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso.” (Títù 3:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ni wọ́n mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn ọ̀run, síbẹ̀ wọ́n ń tẹrí ba fáwọn alákòóso tó jẹ́ ènìyàn, wọn kì í sì í dá wàhálà sílẹ̀ fún Ìjọba. Kódà, Bíbélì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “máa fi ọlá fún ọba” nígbà gbogbo. (1 Pétérù 2:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ rọ àwọn Kristẹni pé: “Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ìyànjú mi ni pé, ṣáájú ohun gbogbo, kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà, ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ ẹbọ ọpẹ́, nípa gbogbo onírúurú ènìyàn, nípa àwọn ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní ipò gíga; kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ àti ìwà àgbà.”—1 Tímótì 2:1, 2.

Tọkàntọkàn làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi ń san owó orí èyíkéyìí tí wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn nígbà mí-ìn. Wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni onímìísí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pèsè lórí ọ̀ràn yìí: “Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.” (Róòmù 13:7) Lójú ìwòye àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, Ọlọ́run ló gba ìjọba Róòmù àti àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láyè láti máa ṣàkóso, fún ìdí yìí, lọ́nà kan “wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn,” nítorí pé wọ́n ń pèsè àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ díẹ̀ láwùjọ.—Róòmù 13:6.

“Láti Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”

A fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní níṣìírí láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìlú tí Ìjọba là kalẹ̀. Jésù Kristi alára rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé nígbà mìíràn kí wọ́n múra tán láti ṣe ju ohun táwọn aláṣẹ ìlú béèrè lọ. Ó ní: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mátíù 5:41) Bí àwọn Kristẹni bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, wọn yóò fi hàn pé kì í ṣe pé àwọn kàn fẹ́ máa yọ́fà àwọn nǹkan ìgbàlódé tí ń bẹ nílùú lọ́fẹ̀ẹ́ lófò, láìsan nǹkan kan padà. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń “gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—Títù 3:1; 1 Pétérù 2:13-16.

Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wọn tọkàntọkàn, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà. (Mátíù 22:39) Nítorí pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní ìfẹ́ yìí, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti ìwà rere, àwòkọ́ṣe ni wọ́n jẹ́ láwùjọ. Inú àwọn aládùúgbò máa dùn ṣáá ni pé Kristẹni ló múlé gbe àwọn. (Róòmù 13:8-10) Àwọn Kristẹni kò fi ìfẹ́ wọn mọ sórí wíwulẹ̀ yẹra fún ìwà ibi. Bíbélì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa yá mọ́ni, kí wọ́n máa fi tọkàntara wá ire ẹlòmí-ìn, kí wọ́n “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” kì í ṣe sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nìkan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti ṣe.—Gálátíà 6:10.

‘Ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run bí Olùṣàkóso Dípò Ènìyàn’

Ṣùgbọ́n o, ó ní ibi tí ìgbọràn sáwọn aláṣẹ ayé mọ. Wọn ò ní jẹ́ ṣe nǹkan kan tí yóò yọ ẹ̀rí-ọkàn wọn lẹ́nu tàbí tí yóò ba ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní Jerúsálẹ́mù pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé kí wọ́n ṣíwọ́ wíwàásù nípa Jésù, wọ́n fi yé wọn pé àwọn ò lè ṣíwọ́. Wọ́n là á mọ́lẹ̀ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:27-29) Àwọn Kristẹni kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú bíbọ olú ọba. (1 Kọ́ríńtì 10:14; 1 Jòhánù 5:21; Ìṣípayá 19:10) Kí wá ni ìyọrísí rẹ̀? Òpìtàn J. M. Roberts sọ pé: “Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bú wọn, kì í ṣe nítorí pé wọ́n jẹ́ Kristẹni, ṣùgbọ́n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí òfin pa láṣẹ.”—Shorter History of the World.

Èé ṣe tí wọ́n fi “kọ̀ láti ṣe ohun tí òfin pa láṣẹ” nínú ọ̀ràn yìí? Lóòótọ́ ni wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ló gba “àwọn aláṣẹ onípò gíga” láyè láti máa ṣàkóso, tó mú kí wọ́n kà wọ́n sí “òjíṣẹ́ Ọlọ́run,” torí wọ́n ń rí sí i pé ìlú tòrò. (Róòmù 13:1, 4) Síbẹ̀ àwọn Kristẹni mọ̀ pé òfin Ọlọ́run làgbà. Wọ́n rántí pé Jésù Kristi ti gbé ìlànà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì yìí kalẹ̀ fáwọn tí yóò di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Dandan ni kí wọ́n fi gbígbọ́ ti Ọlọ́run ṣáájú gbígbọ́ ti Késárì.

Ohun tó yọrí sí nígbà táwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ kùnà láti tẹ̀ lé ìlànà àtàtà wọ̀nyí fi hàn pé èyí ni ọ̀nà títọ́. Fún àpẹẹrẹ, John Keegan, òpìtàn nípa ọ̀ràn ogun, sọ pé àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà di “dọ̀bọ̀sìyẹsà fún ìjọba ìlú, wọ́n di irinṣẹ́ tí ìjọba [ń lò] ní pàtàkì fún kíkó ọmọ ogun jọ àti títọ́jú wọn.” Àwọn ọmọlẹ́yìn wọn bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sí àwọn ogun tó tàjẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. Keegan sọ pé: “Àwọn èèyàn wá kọ etí ikún sófin Ọlọ́run nígbà tí ẹ̀mí ìjà ń gùn wọ́n.”

Ṣùgbọ́n o, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kógo já nínú àpẹẹrẹ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tí wọ́n fi lélẹ̀. Ẹni rere ni wọ́n nílùú. Wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì tó ṣe kedere, wọ́n sì tẹ̀ lé ẹ̀rí-ọkàn wọn tí a fi Bíbélì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.—Aísáyà 2:4; Mátíù 26:52; Róòmù 13:5; 1 Pétérù 3:16.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

“Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́