ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 10/8 ojú ìwé 13
  • Àgbákò Ogun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àgbákò Ogun
  • Jí!—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àwọn Ìyípadà Pípabanbarì”
    Jí!—1999
  • Ẹni Tó Wà Nídìí Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ogun Ha Jẹ́ Aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 10/8 ojú ìwé 13

Àgbákò Ogun

AAGO àràmàǹdà kan àti ẹ̀rọ ìka-ǹkan tí wọ́n gbé tì í tó wà ní Ibi Tí Ìjọba Ń Kó Ohun Àfipìtàn Ogun sí ní Ìlú London, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ti jẹ́ ohun àwòyanu fún àwọn àlejò tí ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Kì í ṣe wákàtí ni aago yìí ń kà o. Ohun tó ń ṣe ni pé kó jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ bí ohun gbígbàfiyèsí kan báyìí ṣe ṣẹlẹ̀ tó ní ọ̀rúndún yìí—ogun ni nǹkan náà. Bí ọwọ́ aago náà ṣe ń yí ni nọ́ńbà tó wà lórí ẹ̀rọ ìka-ǹkan náà ń lọ sókè sí i ní gbogbo ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta àti ẹ̀sún mẹ́ta. Nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan dúró fún ọkùnrin kan, obìnrin kan, tàbí ọmọ kan tí ogun pa láàárín ọ̀rúndún ogún.

Oṣù June 1989 ni ẹ̀rọ ìka-ǹkan náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ní ọ̀gànjọ́ òru December 31, 1999, ni yóò parí ohun tó ń kà. Tó bá di ìgbà yẹn, yóò ti ṣàkọsílẹ̀ ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù, èyí tí a lè gbà bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ pó jẹ́ iye àwọn tó bógun lọ láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá.

Àá ti í gbọ́—ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn tán! Wọ́n mà pọ̀ ju ìlọ́po méjì iye àwọn olùgbé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lápapọ̀ lọ. Síbẹ̀, ìṣirò yẹn ò sọ nǹkan kan nípa ìpayà àti ìrora tí àwọn èèyàn wọ̀nyẹn fojú winá rẹ̀. Kò sì ṣàpèjúwe irú ìyà tó jẹ àwọn tí èèyàn wọ́n kú—ẹgbàágbèje ìyá àti bàbá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò, opó àti àwọn ọmọ òrukàn. Ohun tí a rí fà yọ nínú ìṣirò yẹn ni pé: Ọ̀rúndún tiwa yìí làwọn èèyàn ti ṣòfò ẹ̀mí jù lọ nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá; àwọn nǹkan ibi tó ṣẹlẹ̀ ní sáà yìí ò láfiwé o.

Ìtàn àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún tún fi bí aráyé ṣe gbówọ́ tó nínú ká pààyàn hàn. Nínú gbogbo ìtàn, aráyé ò fi bẹ́ẹ̀ já ṣíṣe àwọn ohun ìjà tuntun kúnra àfìgbà tó di ọ̀rúndún ogún, tí ohun ìjà wá di pelemọ. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, àwọn ẹlẹ́ṣin tí wọ́n ń fi ọ̀kọ̀ jagun wà lára àwọn ọmọ ogun Yúróòpù. Lónìí, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń wo ibi tó ṣú biribiri àti àwọn ẹ̀rọ tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ tí a fi ń darí ọta, a lè ju bọ́ǹbù kó lọ pààyàn níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé, láìtàsé. Àwọn ọdún tó ti kọjá lọ láti ìgbà náà wá ti fún aráyé láyè láti lè ṣe àwọn ìbọn, ọkọ̀ ogun, ọkọ̀ ogun abẹ́ omi, ọkọ̀ òfuurufú ológun, ohun ìjà oníkòkòrò àrùn àti oníkẹ́míkà, àti “bọ́ǹbù” tuntun púpọ̀ sí i, lọ́nà tó túbọ̀ kọyọyọ.

Lọ́nà tó takora, aráyé ti wá gbówọ́ gan-an nínú dídá ogun sílẹ̀ débi pé ogun ti wá di eré ìdíje tí aráyé ò lẹ́mìí ẹ̀ mọ́. Bó ti rí nínú ìtàn àròsọ Frankenstein, tí erìkìnà kan pa ẹni tó ṣẹ̀dá rẹ̀, ogun ń halẹ̀ ikú mọ́ àwọn tó fún un lágbára ńlá tó ní. Ǹjẹ́ a lè mú erìkìnà yìí so tàbí ká mú un kúrò? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Fọ́tò U.S. National Archives

Fọ́tò U.S. Coast Guard

Nípasẹ̀ Ìyọ̀ǹda Onínúure Imperial War Museum

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́