“Àwọn Ìyípadà Pípabanbarì”
“Nínú ìtàn aráyé, kò tún sí ọ̀rúndún míì tí àwọn ìyípadà pípabanbarì, tó sì jẹ́ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti ṣẹlẹ̀ bíi ti ọ̀rúndún ogún yìí.”—The Times Atlas of the 20th Century.
Ọ̀PỌ̀ èèyàn tó bá ń fọkàn bá ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rúndún ogún yìí lọ yóò gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Walter Isaacson, olóòtú àgbà ìwé ìròyìn Time sọ, pé: “Báa bá ní ká fi ọ̀rúndún yìí wé àwọn míì tó ti kọjá, ọ̀rúndún abàmì lèyí o: ó fani mọ́ra lóòótọ́, àmọ́ nígbà míì ó ń jáni láyà, àní àràmàǹdà ni lọ́jọ́kọ́jọ́.”
Olórí ìjọba Norway tẹ́lẹ̀ rí, Gro Harlem Brundtland, pẹ̀lú sọ pé ọ̀rúndún yìí jẹ́ “ọ̀rúndún tó kún fún ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí, . . . ọ̀rúndún tí ìwà burúkú ènìyàn peléke.” Obìnrin yìí sọ pé ọ̀rúndún yìí jẹ́ “ọ̀rúndún ìtẹ̀síwájú ńláǹlà [àti ní àwọn ibòmíràn] ó jẹ́ ọ̀rúndún ìlọsíwájú tí a ò rírú ẹ̀ rí nínú ètò ọrọ̀ ajé.” Àmọ́, bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣe ni àdúgbò àwọn tálákà túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i, nítorí pé “àdúgbò wọ̀nyẹn túbọ̀ ń kún àkúnya, tí àwọn àìsàn tí ipò òṣì àti àyíká tó dọ̀tí ń fà sì túbọ̀ ń gbèèràn.”
Rúkèrúdò Òṣèlú
Nígbà tí ọ̀rúndún ogún bẹ̀rẹ̀, ìlà ọba Manchu ní China, Ilẹ̀ Ọba Ottoman, àti àwọn ilẹ̀ ọba mélòó kan ní Yúróòpù ló ń ṣàkóso apá tó pọ̀ jù lọ láyé. Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì nìkan nasẹ̀ dé ìdámẹ́rin àgbáyé, ó sì ṣàkóso ẹnì kan nínú mẹ́rin ní gbogbo ayé. Àní tipẹ́tipẹ́ kí á tó dé apá ìparí ọ̀rúndún yìí, ni gbogbo ilẹ̀ ọba wọ̀nyí ti di àmúpìtàn. Ìwé The Times Atlas of the 20th Century sọ pé: “Ọdún 1945 ni agbára bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọba.”
Òpin tó dé bá ìjọba amúnisìn ló jẹ́ kí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè tó gbòde kan ní Yúróòpù láàárín ọ̀rúndún kẹtàdínlógún sí ìkọkàndínlógún nasẹ̀ dé àwọn ibi yòókù láyé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, iná ìfẹ́ orílẹ̀-èdè bẹ̀rẹ̀ sí jó rẹ̀yìn ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Yúróòpù . . . Ṣùgbọ́n ní Éṣíà àti Áfíríkà, ṣe ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè bùyààrì, ní pàtàkì nítorí ohun tójú wọ́n rí lábẹ́ ìjọba amúnisìn.” Ìwé The Collins Atlas of World History sọ pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “bí àwọn Orílẹ̀-Èdè Onípò Kẹta ṣe yọjú nìyẹn, tí sànmánì tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún márùn-ún ṣáájú, pẹ̀lú ìjẹgàba Yúróòpù, sì wá sópin.”
Bí àwọn ilẹ̀ ọba ti ń fọ́ kélekèle, bẹ́ẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ń dìde—ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì jẹ́ pé ìjọba tiwa-n-tiwa ló ń ṣàkóso wọn. Ṣùgbọ́n ṣe ni àwọn ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ tó wà ní Yúróòpù àti Éṣíà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì sábà máa ń kógbá ìjọba tiwa-n-tiwa sílé. Àwọn ìjọba onígírímọ́káì wọ̀nyí kì í jẹ́ kéèyàn rímú mí, ọwọ́ wọn sì ni gbogbo owó ìlú àti iléeṣẹ́ ìròyìn àti àwọn ológun wà. Nígbà tó wá yá ṣá, gbogbo kìràkìtà wọn láti jẹ gàba lórí ayé wá sópin, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ owó àti ẹ̀mí ló ti run sí i.
Ọ̀rúndún Tó Kún fún Ogun
Àní, ohun náà gan-an tó mú kí ọ̀rúndún ogún yìí yàtọ̀ sí gbogbo ọ̀rúndún tó ṣáájú rẹ̀ ni ogun. Òpìtàn ará Jámánì náà, Guido Knopp, kọ̀wé nípa Ogun Àgbáyé Kìíní pé: “August 1, 1914: Kò sẹ́ni tó fura pé ọjọ́ yẹn ni ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tó jẹ́ sáà àlàáfíà ní Yúróòpù, dópin; kò sì sẹ́ni tó ṣàkíyèsí pé ìgbà yẹn gan-an ni ọ̀rúndún ogún tóó bẹ̀rẹ̀—pẹ̀lú àkókò ogun tó gba ọgbọ̀n ọdún gbáko, níbi téèyàn ti ń han èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ léèmọ̀.”
Hugh Brogan, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn, fi yé wa pé “ipa tí ogun náà ní lórí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kò ṣeé kó, ó pabanbarì, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ kò sì tíì tán ńlẹ̀ títí di báa ti ń wí yìí [ní 1998].” Ọ̀gbẹ́ni Akira Iriye, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ní Yunifásítì Harvard, kọ̀wé pé: “Ogun Àgbáyé Kìíní jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ nínú ìtàn Ìlà Oòrùn Éṣíà àti ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lóríṣiríṣi ọ̀nà.”
Abájọ tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica fi pe Ogun Àgbáyé Kìíní àti èkejì ní “ìgbà tí iná ìtàn ìṣèlú ọ̀rúndún ogún jó dóríi kókó.” Ó wá sọ pé “Ogun Àgbáyé Kìíní ló fa ìṣubú ìlà ọba ńlá mẹ́rin . . . , òun ló fa Ìyípadà Tegbòtigaga Bolshevik ní Rọ́ṣíà, òun . . . ló sì ṣe atọ́kùn Ogun Àgbáyé Kejì.” Ó tún sọ fún wa pé àwọn ogun àgbáyé wọ̀nyí “kò lẹ́gbẹ́ táa bá ní ká sọ iye ẹ̀mí tó ṣègbé, àní ìpakúpa tìrìgàngàn, àti iye àwọn nǹkan tó bà jẹ́.” Guido Knopp tún sọ pé: “Ìwà ìkà àti ìwà òǹrorò tí wọ́n hù séèyàn kọjá sísọ. Nínú àwọn yàrà . . . ló ti bẹ̀rẹ̀ sí di pé ẹ̀mí èèyàn ò jọni lójú mọ́, tó wá di nǹkan yẹpẹrẹ.”
Nítorí kí irú ogun afẹ̀jẹ̀wẹ̀ bẹ́ẹ̀ má bàa jà mọ́, wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lọ́dún 1919. Nígbà tí ọ̀ràn àlàáfíà ayé kọjá agbára òun náà, ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè rọ́pò rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti dènà Ogun Àgbáyé Kẹta, apá rẹ̀ ò ká àwọn Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀, ó sì ti tó ẹ̀wádún mélòó kan báyìí tí ìyẹn ti ń fẹjú, tó fẹ́ di ogun runlérùnnà. Bẹ́ẹ̀ náà ni agbára rẹ̀ ò ká àwọn ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí ń jà kárí ayé, irú èyí tí ń jà ní àgbègbè Balkan.
Bí iye àwọn orílẹ̀-èdè ti ń pọ̀ sí i láyé, ló túbọ̀ ń ṣòro láti pa àlàáfíà mọ́ láàárín wọn. Ìfiwéra àwòrán àwọn orílẹ̀-èdè ayé ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní àti bó ṣe rí báyìí fi hàn pé nígbà tí ọ̀rúndún yìí bẹ̀rẹ̀, ó kéré tán orílẹ̀-èdè mọ́kànléláàádọ́ta ló wà ní Áfíríkà báyìí, àti mẹ́rìnlélógójì ní Éṣíà tí kò sí tẹ́lẹ̀. Lára orílẹ̀-èdè márùnlélọ́gọ́sàn-án tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lónìí, mẹ́rìndínlọ́gọ́fà lára wọn ni kì í ṣe orílẹ̀-èdè olómìnira nígbà tí wọ́n dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lọ́dún 1945!
“Ọ̀kan Lára Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Yani Lẹ́nu Jù Lọ”
Ní apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Ilẹ̀ Ọba Rọ́ṣíà ni alágbára tó gbilẹ̀ jù lọ ní gbogbo ayé. Ṣùgbọ́n kíákíá ló bẹ̀rẹ̀ sí pàdánù ìtìlẹyìn tó ní. Òǹṣèwé nì, Geoffrey Ponton, sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé “ìyípadà tegbòtigaga pọndandan, ọ̀ràn àtúnṣe nìkan kọ́.” Ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n ogun ńlá náà, ìyẹn ni Ogun Àgbáyé Kìíní, àti rúkèrúdò tó tẹ̀yìn ẹ̀ yọ, ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá tanná ran ìyípadà tegbòtigaga náà ní pẹrẹu.”
Bí àwọn Bolshevik ṣe gorí àlééfà ní Rọ́ṣíà lákòókò yẹn ni wọ́n dá ilẹ̀ ọba tuntun sílẹ̀, èyíinì ni ètò ìjọba Kọ́múníìsì àgbáyé, tí Soviet Union ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ogun àgbáyé ni wọ́n dá Ilẹ̀ Ọba Soviet sílẹ̀, ọta ìbọn kò gbẹ̀mí rẹ̀. Ìwé kan tí Michael Dobbs kọ, tó pè ní Down With Big Brother, sọ pé nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 1977 sí 1979, Soviet Union ti di “ilẹ̀ ọba ràgàjì tó ń wọ̀ọ̀kùn lọ.”
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lójijì ló ṣubú. Ìwé náà, Europe—A History, látọwọ́ Norman Davies, sọ pé: “Ńṣe ló tàkìtì, ìtàkìtì ọ̀hún sì pọ̀ débi pé a ò rírú ẹ̀ rí nínú ìtàn Yúróòpù,” ńṣe ló sì “ṣẹlẹ̀ wẹ́rẹ́.” Ní tòdodo, gẹ́gẹ́ bí Ponton ti sọ, “ìdìde, ìdàgbàsókè àti ìṣubú Soviet Union” jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yani lẹ́nu jù lọ ní ọ̀rúndún ogún yìí.”
Ká sòótọ́, ìṣubú Soviet Union wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára ọ̀wọ́ àwọn ìyípadà pípabanbarì tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rúndún ogún, tí àwọn àbájáde wọn kò lè tètè tán ńlẹ̀. Ṣùgbọ́n o, àwọn ìyípadà nínú ọ̀ràn òṣèlú kì í ṣe tuntun. Wọ́n ti ń ṣẹlẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.
Àmọ́ o, ìyípadà kan tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìjọba ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún, ìyípadà ọ̀hún kàmàmà. A óò jíròrò nípa ìyípadà yìí àti bó ṣe kàn ẹ́ tó bá yá.
Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ gbé ṣe ní ọ̀rúndún ogún. Nípa nǹkan wọ̀nyí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Michael Howard sọ pé: “Ó jọ pé àwọn ará Ìwọ̀-Oòrùn Yúróòpù àti Àríwá Amẹ́ríkà ní ìdí gúnmọ́ láti ka ọ̀rúndún ogún sí ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun tó sì jẹ́ aláyọ̀ nínú ìtàn aráyé.” Ǹjẹ́ ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí yọrí sí ohun tí wọ́n ń pè ní ìgbésí ayé ìdẹ̀ra?
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2-7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
1901
Ọbabìnrin Victoria kú lẹ́yìn jíjọba fún ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta
Ìgbà tí iye àwọn olùgbé ayé lé díẹ̀ ní bílíọ̀nù kan àtààbọ̀
1914
Wọ́n dìtẹ̀ pa Ferdinand Ọmọọba. Ogun Àgbáyé Kìíní sì bẹ̀rẹ̀
Olú ọba tó jẹ kẹ́yìn, Nicholas Kejì, àti ìdílé rẹ̀
1917
Lenin fa ìyípadà tegbòtigaga ní Rọ́ṣíà
1919
Wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀
1929
Ọjà okòwò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kùtà, ó sì fa Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé
Gandhi ò yé jà fún òmìnira Íńdíà
1939
Adolf Hitler gbógun ja Poland, ni Ogun Àgbáyé Kejì bá bẹ̀rẹ̀
Winston Churchill di olórí ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní 1940
Ìpànìyàn Nípakúpa
1941
Japan fi bọ́ǹbù fọ́ Pearl Harbor
1945
Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi bọ́ǹbù fọ́ ìlú Hiroshima àti Nagasaki. Ni Ogun Àgbáyé Kejì bá parí
1946
Àpéjọ Gbogbo Gbòò ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣèpàdé àkọ́kọ́
1949
Mao Tse-tung dá Orílẹ̀-Èdè Olómìnira China sílẹ̀
1960
Wọ́n dá orílẹ̀-èdè tuntun mẹ́tàdínlógún sílẹ̀ ní Áfíríkà
1975
Ogun Vietnam parí
1989
Wọ́n wó odi Berlin bí agbára ti ń bọ́ lọ́wọ́ ètò ìjọba Kọ́múníìsì
1991
Soviet Union tú ká