Wíwá Ìgbésí Ayé Ìdẹ̀ra
“Bí ọ̀rúndún ogún ti ń tẹ̀ síwájú, ìdàgbàsókè nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ . . . ti yí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn padà.”—The Oxford History of the Twentieth Century.
Ọ̀KAN lára ìyípadà tó kàmàmà ní sànmánì yìí ni ìyípadà nínú iye ènìyàn. Kò sí ọ̀rúndún míì tí iye àwọn olùgbé ayé ti sáré pọ̀ tó yìí rí. Bílíọ̀nù kan ṣoṣo ló jẹ́ lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1800, ó sì lé ní nǹkan bí bílíọ̀nù kan àtààbọ̀ ní ọdún 1900. Nígbà tó máa fi di ọdún 1999, iye àwọn olùgbé ayé ti wọ bílíọ̀nù mẹ́fà! Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i yìí ló sì ń fẹ́ àwọn ohun amáyédẹrùn.
Ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìṣègùn àti àbójútó ìlera tó péye wà lára ohun tó fà á táwọn èèyàn fi ń pọ̀ sí i. Ìpíndọ́gba gígùn ẹ̀mí ní àwọn ilẹ̀ bí Ọsirélíà, Jámánì, Japan, àti Amẹ́ríkà—tó dín sí àádọ́ta ọdún ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ti lé ní àádọ́rin ọdún báyìí. Ṣùgbọ́n o, nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dáa láwọn ibòmíì. Gígùn ẹ̀mí àwọn èèyàn tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ó kéré tán, ṣì jẹ́ àádọ́ta ọdún tàbí kó dín sí iye yẹn.
‘Báwo Lẹ Ṣe Wà Láìsí . . . ?’
Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fáwọn èwe láti lóye báwọn baba ńlá wọn ṣe wà láìsí ọkọ̀ òfuurufú, kọ̀ǹpútà, tẹlifíṣọ̀n—àwọn nǹkan tí kì í ṣe bàbàrà mọ́ báyìí, àní táwọn èèyàn tí ń gbé ní àwọn ilẹ̀ ọlọ́rọ̀ kà sí kòṣeémánìí. Fún àpẹẹrẹ, wo bí ọkọ̀ ti yí ìgbésí ayé wa padà. Apá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni wọ́n hùmọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn Time sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ọkọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìhùmọ̀ tó sọ ọ̀rúndún ogún yìí dà bó ti dà, láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.”
Lọ́dún 1975, wọ́n ní bí ọkọ̀ bá ṣàdédé di èyí tí kò sí mọ́, iṣẹ́ á bọ́ lọ́wọ́ ẹnì kan nínú mẹ́wàá ní Yúróòpù. Yàtọ̀ sí wàhálà tó máa kó bá àwọn iléeṣẹ́ tí ń ṣe mọ́tò, ńṣe ni àwọn báǹkì, àwọn ilé ìtajà ńláńlá, àwọn ilé àrójẹ tí ń gbé oúnjẹ wá báni nídìí ọkọ̀, àtàwọn iléeṣẹ́ míì tó jẹ́ pé ọkọ̀ làwọn èèyàn ń wọ̀ wá rajà níbẹ̀ yóò kógbá sílé. Nígbà tí kò bá sọ́nà táwọn àgbẹ̀ fi máa kó irè oko dọ́jà, inú oko loúnjẹ máa rà sí. Àwọn tíbi iṣẹ́ wọ́n wà nígboro ṣùgbọ́n tí wọn kì í gbé àárín ìgboro kò ní lè débi iṣẹ́ mọ́. Àwọn òpópónà márosẹ̀ tó kún ìgboro á wá dá páropáro.
Láti lè ṣe ohun ìrìnnà jáde tìrìgàngàn láìwọ́nwó, wọ́n dá àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá tó wá wọ́pọ̀ lóde òní sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, níbi tí wọ́n ti ń ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀yà ara ẹ̀rọ sílẹ̀, tí wọ́n á wá tò wọ́n pa pọ̀ lẹ́yìn náà. (Irú àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá wọ̀nyí ló ń jẹ́ ká lè máa ṣe àwọn ohun èlò mìíràn jáde lọ́pọ̀ yanturu, gẹ́gẹ́ bí onírúurú àwọn nǹkan táà ń lò ní kíṣìnnì.) Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, ohun ìrìnnà tí àwọn olówó fi ń gbádùn làwọn èèyàn ka mọ́tò sí ní àwọn ilẹ̀ díẹ̀, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti di ohun tí tẹrú-tọmọ fi ń ṣẹsẹ̀ rìn lápá ibi púpọ̀ láyé. Òǹṣèwé kan sọ pé, “ìgbésí ayé ì bá mà nira ní apá ìgbẹ̀yìn ọ̀rúndún ogún o, ká ní kò sí mọ́tò ni.”
Lílépa Fàájì
Láyé àtijọ́, tí ò bá di dandan, èèyàn kì í ràjò. Àmọ́ ní ọ̀rúndún ogún yìí, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ o—pàápàá jù lọ ní àwọn ilẹ̀ ọlọ́rọ̀. Báwọn èèyàn ṣe ń ríṣẹ́ olówó gọbọi ṣe, tí wákàtí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀ ń dín kù, tó wá jẹ́ nǹkan bí ogójì wákàtí tàbí tí kò tilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, làwọn èèyàn wá túbọ̀ ń lówó lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ráyè rìnrìn àjò. Ìrìn àjò wá di ọ̀ràn gbígbéra lọ síbi tóo bá fẹ́. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bọ́ọ̀sì, àti ọkọ̀ òfuurufú jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn láti gbafẹ́ lọ sọ́nà jíjìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn wá ń rin ìrìn àjò afẹ́ kiri.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Times Atlas of the 20th Century ti wí, ìrìn àjò afẹ́ “ní ipa ńlá lórí orílẹ̀-èdè táwọn arìnrìn-àjò ń bẹ̀ wò àti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá.” Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni irú ìrìn bẹ́ẹ̀ ń bímọ ire. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ti ba ibi tí wọ́n wá wò jẹ́.
Àwọn èèyàn tún ní àkókò púpọ̀ sí i láti fi lépa eré ìdárayá. Ọ̀pọ̀ di eléré ìdárayá; àwọn míì fi tiwọn mọ sí fífi taratara gbárùkù ti ẹgbẹ́ eléré ìdárayá tàbí àwọn eléré orí pápá tí wọ́n yàn láàyò. Ìgbà tí tẹlifíṣọ̀n dé, eré ìdárayá wá di ti kóówá. Àwọn eré ìdárayá tó ń wáyé láàárín orílẹ̀-èdè àtàwọn èyí tí ń wáyé lápá ibòmíràn láyé wá di èyí táwọn èèyàn ń ranjú mọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n.
Ìwé The Times Atlas of the 20th Century sọ pé: “Eré ìdárayá àti sinimá ni igi lẹ́yìn ọ̀gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ tí ń ṣètò fàájì lóde òní, iléeṣẹ́ wọ̀nyí sì wà lára àwọn tó ní òṣìṣẹ́ tó pọ̀ jù lọ láyé, tó sì ń pawó wálé jù lọ.” Lọ́dọọdún, àwọn èèyàn ń ná ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là sórí eré ìnàjú, títí kan tẹ́tẹ́ títa, tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń pawọ́ dà. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí kan lọ́dún 1991 sọ pé táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn iléeṣẹ́ tó tóbi jù lọ láwọn Orílẹ̀-Èdè Yúróòpù, iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́ títa ló wà ní ipò kejìlá, nítorí pé lọ́dọọdún, ó kéré tán, ó ń pa tó ẹ̀tàdínlọ́gọ́ta bílíọ̀nù dọ́là.
Ìgbádùn tó ń ṣàn yìí wá jẹ́ káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí dán ìdánkúdàn-án wò. Fún àpẹẹrẹ, iye àwọn èèyàn tí ń lo oògùn olóró wá pọ̀ débi pé láàárín 1994 sí 1997, owó táwọn tí ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró pa wọlé pọ̀ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún kan ṣoṣo, gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni kan sì ti wí, èyí ló sọ ọ́ di “iṣẹ́ kan ṣoṣo tó mówó wọlé jù lọ lágbàáyé.”
“Ayé Àjẹkú”
Àwọn ẹ̀rọ amáyédẹrùn wá jẹ́ kí ayé lu jára. Lọ́wọ́ táa wà yìí, bí ìyípadà bá dé bá ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ níbì kan láyé, wéré ló ti máa tàn káyé. Ìyẹn ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Alvin Toffler, tó ṣe ìwé Future Shock, fi sọ tipẹ́ ní 1970 pé: “Ní tòdodo, àwọn rúkèrúdò ńlá ti ń ṣẹlẹ̀, kì í ṣòní, kì í ṣàná.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́ àwọn rògbòdìyàn àti rúkèrúdò wọ̀nyí kì í kọjá àwùjọ kan tàbí àwọn àwùjọ tó wà ní sàkáání wọn. Ọ̀pọ̀ ìran ènìyàn láá ti kọjá lọ, nígbà míì ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tilẹ̀ ti lè kọjá lọ, káwọn àwùjọ míì tó bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ ọ́n lára. . . . Ṣùgbọ́n lónìí, àwùjọ ẹ̀dá so kọ́ra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé gbàrà tí nǹkan kan bá ń ṣẹlẹ̀ níbì kan làwọn èèyàn á ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ ọ́n lára kárí ayé.” Àwọn tẹlifíṣọ̀n tí ń lo sátẹ́láìtì àti ọ̀nà táa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà táa mọ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì pẹ̀lú ti nípa lórí àwọn èèyàn jákèjádò ayé.
Àwọn kan sọ pé tẹlifíṣọ̀n ni ohun èlò tó lágbára jù lọ lórí àwọn èèyàn ní ọ̀rúndún ogún. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń kọminú sí ohun tí tẹlifíṣọ̀n ń gbé jáde, kò sẹ́ni tó lè sẹ́ agbára rẹ̀.” Àmọ́ tẹlifíṣọ̀n kò sàn ṣẹ́ àwọn ènìyàn tó ń ṣe àwọn ètò orí rẹ̀. Nítorí náà, bó ṣe lágbára láti súnni ṣe rere, bẹ́ẹ̀ náà ló lágbára láti súnni ṣe búburú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ètò rán-un-ràn-un, tó kún fún ìwà ipá àti ìṣekúṣe, ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn kan lọ́rùn, síbẹ̀ irú àwọn ètò bẹ́ẹ̀ kò tún àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ṣe, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń bà á jẹ́.
Neil Postman mẹ́nu kan ewu míì nínú ìwé rẹ̀ Amusing Ourselves to Death, ó ní: “Ohun táà ń sọ kì í ṣe ọ̀ràn bóyá àwọn ètò kan tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ń dá wa lára yá àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àmọ́ ohun táà ń sọ ni pé gbogbo ètò orí tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n ń dọ́gbọ́n gbé kalẹ̀ bí èyí tí ń dáni lára yá . . . Ohun yòówù kí wọ́n gbé jáde tàbí èròǹgbà yòówù kó jẹ́, lájorí èrò tí wọ́n ń fẹ́ gbìn sí wa lọ́kàn ni pé, fún ìgbádùn àti fàájì wa ni.”
Báwọn èèyàn ṣe ń fojoojúmọ́ ayé ṣe fàájì kiri, bẹ́ẹ̀ làwọn nǹkan tẹ̀mí àti ti ìwà rere ń jó rẹ̀yìn. Ìwé The Times Atlas of the 20th Century sọ pé: “Lápá ibi púpọ̀ jù lọ láyé, agbára ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ètò ẹ̀sìn ní ọ̀rúndún ogún.” Bí ìfẹ́ nípa nǹkan tẹ̀mí ti ń jó rẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni fàájì ṣíṣe wá di àkọ́múṣe, ó wá di nǹkan bàbàrà.
“Gbogbo Ohun Tí Ń Dán . . .”
Ọ̀pọ̀ ìyípadà rere ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún, àmọ́, àwọn èèyàn máa ń sọ pé, “Gbogbo ohun tí ń dán kọ́ ni wúrà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jàǹfààní látinú ẹ̀mí gígùn, àpọ̀jù àwọn èèyàn láyé ti mú kí àwọn ìṣòro ńláńlá yọjú lákọ̀tun. Ìwé ìròyìn National Geographic sọ láìpẹ́ yìí pé: “Ó lè wá di pé àpọ̀jù àwọn èèyàn ni ìṣòro kánjúkánjú jù lọ tí a ó dojú kọ báa ti ń wọnú ẹgbẹ̀rúndún tuntun.”
Àwọn ọkọ̀ wúlò, a sì ń gbádùn wọn, àmọ́ àwọn náà ń ṣekú pa wá, àní nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlá àbọ̀ [250,000] ló ń kú lọ́dọọdún nínú jàǹbá ọkọ̀ kárí ayé. Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ sì jẹ́ òléwájú lára àwọn nǹkan tí ń tú èéfín burúkú sáfẹ́fẹ́. Àwọn tó ṣe ìwé 5000 Days to Save the Planet sọ pé ìbàyíkájẹ́ “ti di ìṣòro kárí ayé báyìí, ó ń ta jàǹbá fún ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn, ó sì ń ba ìwàláàyè àwọn ohun alààyè wọ̀nyí jẹ́ jákèjádò ayé.” Wọ́n ṣàlàyé pé: “A ò tiẹ̀ wá fi mọ sórí kìkì títa jàǹbá fún ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn, ní báyìí o, a ti bẹ̀rẹ̀ sí dabarú àwọn ètò náà gan-an tó jẹ́ kí Ilẹ̀ Ayé ṣeé gbé fún ọmọ adáríhurun.”
Ní ọ̀rúndún ogún, ìbàyíkájẹ́ ti di ìṣòro tí àwọn ọ̀rúndún tó ṣáájú kò gbúròó rẹ̀. Ìwé ìròyìn National Geographic sọ pé: “Bí kì í báá ṣe ẹnu àìpẹ́ yìí, kò sẹ́ni tó ronú débi pé èèyàn lè fọwọ́ ara rẹ̀ kó bá gbogbo ayé. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ti wá gbà báyìí pé irú àwọn ìyípadà, tí kò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn, ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí o.” Ìwé ìròyìn náà wá ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Àpapọ̀ iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ aráyé lè fa àkúrun gbogbo ẹ̀dá alààyè láàárín ìran ènìyàn kan ṣoṣo.”
Ti àsọdùn kọ́, ọ̀rúndún ogún yàtọ̀, ó yọyẹ́. Àwọn èèyàn, tó jẹ́ pé àǹfààní láti gbádùn ìgbésí ayé ìdẹ̀ra pọ̀ jaburata níwájú wọn tẹ́lẹ̀, ni ìwàláàyè àwọn alára wá wà nínú ewu báyìí, ó mà kúkú ga o!
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
1901
Marconi tàtaré ìsọfúnni àkọ́kọ́ gba orí òkun Àtìláńtíìkì kọjá
1905
Einstein tẹ èròǹgbà rẹ̀ jáde nípa òfin tí ń darí àgbáyé
1913
Ford ṣí iléeṣẹ́ rẹ̀ tó ń to ọkọ̀ ẹ̀yà Model-T
1941
Tẹlifíṣọ̀n dóde
1969
Èèyàn rìn lórí òṣùpá
Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí rin ìrìn àjò afẹ́ kiri
Ọ̀nà táa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà táa mọ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì wá gbòde kan
1999
Iye àwọn olùgbé ayé wọ bílíọ̀nù mẹ́fà