ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/08 ojú ìwé 14-15
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Sá fún Ìbẹ́mìílò?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Sá fún Ìbẹ́mìílò?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibi Tí Ìbẹ́mìílò Máa Ń Já Sí
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Pa Wá Mọ́
  • Dènà Àwọn Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Kó O Lè Borí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Èé Ṣe Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Nífẹ̀ẹ́ Sí Ìbẹ́mìílò?
    Jí!—2000
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kí O Yẹra Fún Ìbẹ́mìílò
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 7/08 ojú ìwé 14-15

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Sá fún Ìbẹ́mìílò?

NÍBÌ kan nílẹ̀ Éṣíà, àwùjọ àwọn èèyàn kan ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níbi àríyá tí wọ́n fi ń júbà àwọn òrìṣà. Gọngọ tún wá sọ nígbà tí wọ́n ké sí àwọn obìnrin méjì pé kí wọ́n wá jó kí wọ́n bàa lè gba ẹ̀mí. Kíá ojú àwọn obìnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ranko, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n torí tọrùn bí ẹni pé wọ́n gbé agbára abàmì wọ̀.

Ní Puerto Rico, abọ̀rìṣà kan (santero) ń gbára dì láti bá Ṣàngó, ìyẹn ọlọ́run ààrá, sọ̀rọ̀. Oníṣàngó náà ń rọ́yìn àwọn ohun tó rí nínú ìran, gbogbo àwọn tó wà nínú yàrá náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí ẹni pé ẹ̀mí gbé wọn.

Iṣẹ́ òkùnkùn bí irú ìwọ̀nyí ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà gbọ́ pé agbára abàmì wà, wọ́n sì ń wá fìn-ín ìdí kókò àwọn agbára abàmì náà. Àwọn ìwé, eré ìdárayá, eré orí tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn sinimá tó ń gbé ẹ̀mí èṣù, iṣẹ́ oṣó, àtàwọn ohun abàmì lárugẹ, sì tún wá pọ̀ lọ jàra.

Àmọ́, Bíbélì kọ́ni pé béèyàn bá lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òkùnkùn, ńṣe ni onítọ̀hún ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Ìbẹ́mìílò kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré tàbí ohun tí kò lè pani lára. Kì í wulẹ̀ ṣe wíwádìí ohun téèyàn ò mọ̀ lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì burúkú tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.—Ìṣípayá 12:9, 12.

Ká sòótọ́, ohun tí ìjẹ ń ṣe fún apẹja ni ìbẹ́mìílò ń ṣe fáwọn ẹ̀mí èṣù. Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìjẹ ni apẹja máa ń lò láti fi mú onírúurú ẹja. Bákan náà, àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lo ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìbẹ́mìílò láti lè ki orí onírúurú èèyàn bọ abẹ́. Bíbélì pe olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan [búburú] yìí.” Ó sì ti fọ́ ojú inú ọ̀pọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa yé wọn kí wọ́n má sì mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe.—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Ibi Tí Ìbẹ́mìílò Máa Ń Já Sí

Ohun táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú ń fẹ́ láti ṣe rèé: Wọ́n fẹ́ pín ọkàn wa níyà kí wọ́n sì ṣì wá lọ́nà ká má bàa ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Wọ́n máa ń mú káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sáwọn ohun rere tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n ṣe, yálà lọ́nà èèṣì tàbí kí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀. Nítorí náà, ìbẹ́mìílò kì í jẹ́ kéèyàn rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ó máa ń sọni di aláìnírètí, ìparun ló sì máa gbẹ̀yìn rẹ̀.—Ìṣípayá 21:8.

Luis, tó wá láti Puerto Rico sọ pé: “Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé làwọn òbí mi ti ń lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò. Ó ti di apá kan ẹ̀sìn àwọn òbí mi, ọjọ́ sì pẹ́ tí wọ́n ti ń bá a bọ̀. Mo lágbára láti sọ nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀, mo sì máa ń fi káàdì tarot pinnu ibi tọ́rọ̀ máa já sí, àmọ́ mo rò pé Ọlọ́run ló dá ẹ̀bùn yìí mọ́ mi. Mo máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jẹ tẹ́tẹ́ nípa bíbá wọn mú nọ́ńbà tó máa jẹ. Aburú táwọn ẹ̀bùn ti mo rò pé mo ní yìí ń ṣe fún mi ni pé wọn ò jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sórí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí n sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run.”—Jòhánù 17:3.

Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé kò séwu nínú bíbá ẹ̀mí lò, wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ pé ó ṣàǹfààní. Wọ́n lè sọ pé agbọmọlà làwọn kan lára wọn tàbí kí wọ́n sọ pé wọ́n máa ń lani lọ́yẹ̀, wọ́n lè sọni dọlọ́rọ̀, tàbí kí wọ́n múni láyọ̀. Irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ gbáà lèyí jẹ́. Luis sọ pé: “Kò sí bí kò ṣe ní í náni ní nǹkan kan.”

Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Chad bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn ìran tó ń mú kó máa díjì, wọ́n sì ń fi àìróorun sùn dá a lóró. Ó sọ pé: “Àwọn ẹ̀mí èṣù bẹ̀rẹ̀ sí fòòró mi wọ́n sì ń pọ́n mi lójú ní alaalẹ́.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè pa wá mọ́ lọ́wọ́ irú ìfòòró ẹni bẹ́ẹ̀?

Bí Ọlọ́run Ṣe Pa Wá Mọ́

A gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ohunkóhun tó bá la ìbẹ́mìílò lọ ká bàa lè pa ara wa mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú. (Gálátíà 5:19-21) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà pàṣẹ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n yẹra fún àwọn àṣà wọ̀nyí: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni . . . tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Diutarónómì 18:10-12.

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ṣe láti dáàbò bo ara wọn ni pé wọ́n kó ìwé tàbí àwọn ohun èlò míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò dà nù. Ken, tó jáwọ́ nínú ìbẹ́mìílò sọ pé, “Mo tú gbogbo ẹrù mi palẹ̀, mo sì dáná sun gbogbo ohun tí mo rí pé kò dáa nínú ẹ̀.”—Wo Ìṣe 19:19, 20.

Ààbò tó nípọn jù lọ ni pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́. Kíyè sí ohun tí Jákọ́bù 4:7, 8 gbà wá níyànjú láti ṣe, ó sọ pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara, ẹ̀yin aláìnípinnu.”

Jèhófà Ọlọ́run ń kọ́ àwọn tó bá sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, ó sì ń dáàbò bò wọ́n. Wọn kò “ṣe aláìmọ àwọn ète” Sátánì, wọn ò sì jẹ́ kó fi ẹ̀tàn mú àwọn. (2 Kọ́ríńtì 2:11; 11:14) Àti pé Jèhófà ni Olódùmarè. Bí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà bá mú ká ké pè é, kò ní jẹ́ káwọn ẹ̀mí búburú fòòró wa. Chad, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé: “Torí pé mo mọ àwọn tó ń pọ́n mi lójú tí mo sì ń ké pe Jèhófà Ọlọ́run pé kó gbà mí lọ́wọ́ wọn mú kí wọ́n dẹ́kun fífòòró mi.”—Sáàmù 91:1, 2.

Ó ṣe kedere pé àwọn ọlọ́kàn rere lè máa láyọ̀ pé Ọlọ́run lè dáàbò bo àwọn nísinsìnyí, àti pé ó máa tó pa àwọn ẹ̀mí èṣù àtàwọn tó bá wà lábẹ́ ìdarí wọn run. Sì wá wo bí ayọ̀ àti àlàáfíà tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà náà á ti pọ̀ tó, tó bá di pé aráyé dòmìnira pátápátá kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ẹ̀mí búburú!—Aísáyà 11:9; Ìṣípayá 22:15.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Àwọn àṣà ìbẹ́mìílò wo làwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí?—Diutarónómì 18:10-12; Ìṣípayá 21:8.

◼ Ta ló ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ?—2 Kọ́ríńtì 2:11; 11:14; Ìṣípayá 12:9, 12.

◼ Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú?—Jákọ́bù 4:7, 8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Ká sòótọ́, ohun tí ìjẹ ń ṣe fún apẹja ni ìbẹ́mìílò ń ṣe fáwọn ẹ̀mí èṣù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́