Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
Ṣé ò ń kọ́kàn sókè torí báwọn nǹkan ṣe ń gbówó lórí? Ṣé oríṣiríṣi iṣẹ́ lò ń rọ́ mọ́ra kó o ṣáà lè rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu? Ṣé iṣẹ́ ẹ ti wá ń gba gbogbo àkókò ẹ débi pé o kì í fi bẹ́ẹ̀ wà pẹ̀lú ìdílé ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí àwọn nǹkan tó o lè ṣe tó ò fi ní máa kọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ àtàwọn nǹkan táá jẹ́ kó o máa láyọ̀ bí nǹkan ò tiẹ̀ rọrùn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn, wàá rí àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe táá mú kí nǹkan dáa sí i lọ́jọ́ iwájú àti báwọn nǹkan yẹn ṣe lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ báyìí.