Àtẹ Àwọn Ọjọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀
- ‘Ní àtètèkọ́ṣe . . .’ 
- 4026 Ṣ.S.K. Ìṣẹ̀dá Ádámù 
- 3096 Ṣ.S.K. Ádámù Ikú 
- 2370 Ṣ.S.K. Omi bẹ̀rẹ̀ sí í ya lulẹ̀ 
- 2018 Ṣ.S.K. A bí Ábúráhámù 
- 1943 Ṣ.S.K. Májẹ̀mú Ábúráhámù 
- 1750 Ṣ.S.K. Wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú 
- ṣáájú 1613 Ṣ.S.K. Àdánwò Jóòbù 
- 1513 Ṣ.S.K. Ìjáde kúrò ní Íjíbítì 
- 1473 Ṣ.S.K. Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì 
- 1467 Ṣ.S.K. Wọ́n parí ṣíṣẹ́gun àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì nílẹ̀ Kénáánì 
- 1117 Ṣ.S.K. A fòróró yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba 
- 1070 Ṣ.S.K. Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú Ìjọba 
- 1037 Ṣ.S.K. Sólómọ́nì di ọba 
- 1027 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù 
- nǹkan bí 1020 Ṣ.S.K. Wọ́n parí kíkọ ìwé Orin Sólómọ́nì 
- 997 Ṣ.S.K. A pín ìjọba Ísírẹ́lì sí méjì 
- nǹkan bí 717 Ṣ.S.K. Àkójọ àwọn Òwe parí 
- 607 Ṣ.S.K. Àwọn ọmọ ogun pa Jerúsálẹ́mù run; ìkónígbèkùn lọ sí Bábílónì bẹ̀rẹ̀ 
- 539 Ṣ.S.K. Kírúsì ṣẹ́gun ìlú Bábílónì 
- 537 Ṣ.S.K. Àwọn Júù tó wà nígbèkùn padà sí Jerúsálẹ́mù 
- 455 Ṣ.S.K. A tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́; ọ̀sẹ̀ 69 ti ọdún bẹ̀rẹ̀ 
- Lẹ́yìn 443 Ṣ.S.K. Málákì parí ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ 
- nǹkan bí 2 Ṣ.S.K. Ìbí Jésù 
- 29 S.K. A batisí Jésù àti Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run 
- 31 S.K. Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá; ó ṣe Ìwàásù Lórí Òkè 
- 32 S.K. Jésù jí Lásárù dìde 
- Nísàn 14, 33 S.K. Wọ́n kan Jésù mọ́gi (Oṣù Nísàn bọ́ sí apá kan oṣù March àti apá kan oṣù April) 
- Nísàn 16 33 S.K. Ọlọ́run jí Jésù dìde 
- Sífánì 6, 33 S.K. Pẹ́ńtíkọ́sì; ìtújáde ẹ̀mí mímọ́ (Oṣù Sífánì bọ́ sí apá kan oṣù May àti apá kan oṣù June) 
- 36 S.K. Kọ̀nílíù di Kristẹni 
- nǹkan bí 47 sí 48 S.K. Ìrìn àjò àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù 
- nǹkan bí 49 sí 52 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kejì tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù 
- nǹkan bí 52 sí 56 S.K. Ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta tí Pọ́ọ̀lù rìn láti lọ wàásù 
- 60 sí 61 S.K. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù 
- ṣáájú 62 S.K. Jákọ́bù, iyèkan Jésù kọ lẹ́tà rẹ̀ 
- 66 S.K. Àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ìlú Róòmù 
- 70 S.K. Àwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run 
- nǹkan bí 96 S.K. Jòhánù kọ ìwé Ìṣípayá 
- nǹkan bí 100 S.K. Ikú Jòhánù, ẹni tó gbẹ̀yìn lára àwọn àpọ́sítélì