APÁ 14
Báwo Lo Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà?
Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni kí o dúró sí. 1 Pétérù 5:6-9
Má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Ó gba ìgboyà láti ṣe èyí.
Má ṣe bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú; ìṣèlú ò fara mọ́ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀.
Yan ohun tí ó tọ́, ìyẹn ni pé kí o tẹ́tí sí Ọlọ́run. Mátíù 7:24, 25
Dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà; wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run.
Máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nípa Ọlọ́run, sì máa sapá láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Tí ìgbàgbọ́ rẹ bá ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí o ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kí o sì ṣèrìbọmi.—Mátíù 28:19.
Máa tẹ́tí sí Ọlọ́run. Máa ka Bíbélì, kí o sì ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé rẹ̀ fún ọ. Lẹ́yìn náà, máa fi àwọn ohun tí ò ń kọ́ sílò. Tí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà láàyè títí láé.—Sáàmù 37:29.