Orin 136
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!
- Jèhófà, o ti wà tipẹ́, - Ìwọ yóò máa wà lọ. - O gbé ọmọ rẹ gorítẹ̀ẹ́; - O pàṣẹ kó jọba. - A ti wá bí Ìjọba náà; - ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé. - (ÈGBÈ) - Ní báyìí, ìgbàlà, - Ìjọba àtagbára dé. - ’Jọba náà ńṣàkóso. - Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!” 
- Àkókò Èṣù ti kúrú; - A mohun téyìí jẹ́. - À ńgbé lákòókò wàhálà, - A ró’un táyé kò rí. - A ti wá bí Ìjọba náà; - ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé. - (ÈGBÈ) - Ní báyìí, ìgbàlà, - Ìjọba àtagbára dé. - ’Jọba náà ńṣàkóso. - Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!” 
- Àwọn áńgẹ́lì ọ̀run yọ̀ - Wọ́n sì fayọ̀ kọrin. - Àwọn ọ̀run ti bọ́ lọ́wọ́ - Sátánì òpùrọ́. - A ti wá bí Ìjọba náà; - ’Jọba rẹ̀ yóò kárí ayé. - (ÈGBÈ) - Ní báyìí, ìgbàlà, - Ìjọba àtagbára dé. - ’Jọba náà ńṣàkóso. - Jọ̀wọ́: “Jẹ́ kó dé, Jẹ́ kó dé!” 
(Tún wo Dán. 2:34, 35; 2 Kọ́r. 4:18.)