ORIN 9
Jèhófà Ni Ọba Wa!
- 1. Ẹ yọ̀, ẹ fògo fún Jèhófà - Tor’áwọn ọ̀run ń sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀. - Ẹ jẹ́ ká forin ayọ̀ yin Ọlọ́run wa; - Ká sọ àwọn iṣẹ́ ‘yanu rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! 
- 2. Ẹ ròyìn ògo rẹ̀ fáráyé; - Jèhófà Ọlọ́run l’Olùgbàlà wa. - Jèhófà l’Ọba wa tó yẹ ká fìyìn fún. - A tẹrí ba ní iwájú rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! 
- 3. Ó fi Ọmọ rẹ̀ sórí ìtẹ́, - Ìṣàkóso rẹ̀ sì ti fìdí múlẹ̀. - Kí ojú ti àwọn ọlọ́run ayé yìí, - Jèhófà nìkan ni ìyìn yẹ. - (ÈGBÈ) - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! - Jẹ́ kí ọ̀run máa yọ̀, kílẹ̀ ayé sì dùn, - Torí Jèhófà ti dọba wa! 
(Tún wo 1 Kíró. 16:9; Sm. 68:20; 97:6, 7.)