ORIN 1
Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Alágbára Ńlá ni Ọ́, Jèhófà. - Ìwọ l’Orísun ìmọ́lẹ̀ àtìyè. - Ohun tó o dá ń fi agbára rẹ hàn; - Ayé àtọ̀run náà ń jẹ́rìí sí i. 
- 2. Ìṣàkóso rẹ jẹ́ ti òdodo, - Àwọn àṣẹ rẹ lo sì ti sọ fún wa. - Bí a ṣe ń ka Bíbélì, à ń rí i pé - Ọgbọ́n rẹ ti wá túbọ̀ ń yé wa. 
- 3. Ìfẹ́ ni ànímọ́ rẹ tó ga jù. - Àwọn oore rẹ kọjá àfẹnusọ. - A ó fìtara kéde orúkọ rẹ, - Àtàwọn ànímọ́ rẹ tó pọ̀. 
(Tún wo Sm. 36:9; 145:6-13; Oníw. 3:14; Jém. 1:17.)