ORIN 25
Àkànṣe Ìní
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Ìṣẹ̀dá tuntun làwọn - Ẹni àmì òróró. - Inú ọmọ aráyé - L’Ọlọ́run ti rà wọ́n. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe ìní ni - Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà. - Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́. - Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé. 
- 2. Orílẹ̀-èdè mímọ́ - Tó jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n. - Jèhófà mú wọn kúrò - Lókùnkùn sí ‘mọ́lẹ̀. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe ìní ni - Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà. - Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́. - Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé. 
- 3. Wọ́n ń pe àgùntàn mìíràn, - Wọ́n sì ń kó gbogbo wọn jọ. - Wọ́n dúró gbọn-in ti Jésù. - Wọ́n ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe ìní ni - Wọ́n jẹ́ fún ọ, Jèhófà. - Wọ́n fẹ́ ọ, wọ́n ń yìn ọ́. - Wọ́n ń pòkìkí rẹ kárí ayé. 
(Tún wo Àìsá. 43:20b, 21; Mál. 3:17; Kól. 1:13.)