Orin 147
Àkànṣe Dúkìá
Bíi Ti Orí Ìwé
	- Ọlọ́run l’ẹ́dàá tuntun, - Àwọn ’mọ tó f’ẹ̀mí yàn. - Ó rà wọ́n nínú ayé; - Wọ́n ti r’ójúure rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe dúkìá, - Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n. - Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́. - Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé. 
- Orílẹ̀èdè mímọ́ ni, - Wọ́n mọyì òtítọ́ gan-an. - Ó pè wọ́n nínú òòkùn - Wá sínú ìmọ́lẹ̀. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe dúkìá, - Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n. - Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́. - Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé. 
- Wọ́n ńbá’ṣẹ́ ìsìn wọn lọ, - Wọ́n ńk’ágùntàn mìíràn jọ. - Adúróṣinṣin ni wọ́n. - Wọ́n ńpàṣẹ Jésù mọ́. - (ÈGBÈ) - Àkànṣe dúkìá, - Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n. - Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́. - Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé. 
(Tún wo Aísá. 43:20b, 21; Mál. 3:17; Kól. 1:13.)