ORIN 64
À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Àǹfààní àláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ - Pé ìgbà ‘kórè la wà yìí. - Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀, ká bọ́ sí pápá, - Ká sì sa gbogbo ipá wa. - Torí pé Kristi wà pẹ̀lú wa, - Tó ń darí iṣẹ́ tá à ń ṣe yìí, - Èyí ń fún wa láyọ̀ lójoojúmọ́, - Ọlá ńlá ló sì jẹ́ fún wa. 
- 2. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run - Àtàwọn aládùúgbò wa, - Ó ń mú ká tẹra mọ́ ìwàásù, - Torí òpin ti sún mọ́lé. - À ń láyọ̀ bí a ṣe ńṣiṣẹ́ yìí; - Jèhófà ló ń fún wa láyọ̀. - A ó fìgbàgbọ́ fara dà á dé òpin, - A ó sì máa fayọ̀ bá a ṣiṣẹ́. 
(Tún wo Mát. 24:13; 1 Kọ́r. 3:9; 2 Tím. 4:2.)