ORIN 116
Agbára Inúure
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Tọkàntọkàn là ń yìn ọ́, Jèhófà - Torí pé Ọ̀rọ̀ rẹ - Jẹ́ ká mọ bágbára rẹ ṣe pọ̀ tó, - Síbẹ̀ ò ń fìfẹ́ hàn sí wa. 
- 2. Jésù ń pe àwọn tẹ́rù wọn wúwo - Kí wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. - Onínúure ni, onírẹ̀lẹ̀ ni; - Ó máa mú ìtura bá wọn. 
- 3. Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ - Ti fàpẹẹrẹ lélẹ̀. - Tá a bá jẹ́ onínúure bíi tiwọn, - Yóò sọ wá di alágbára! 
(Tún wo Míkà 6:8; Mát. 11:28-30; Kól. 3:12; 1 Pét. 2:3.)