ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 8B
Àsọtẹ́lẹ̀ Mẹ́ta Nípa Mèsáyà
1. “Ẹni Tó Lẹ́tọ̀ọ́ sí I Lọ́nà Òfin” (Ìsíkíẹ́lì 21:25-27)
ÀKÓKÒ ÀWỌN KÈFÈRÍ (607 Ṣ.S.K.–1914 S.K.)
- 607 Ṣ.S.K.—Wọ́n rọ Sedekáyà lóyè 
- 1914 S.K.—Jésù di Ọba, ó sì di Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alákòóso, òun ló ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” sí Ìjọba Mèsáyà 
Pa dà sí orí 8, ìpínrọ̀ 12 sí 15
2. “Ìránṣẹ́ Mi Yóò . . . Máa Bọ́ Wọn, Ó sì Máa Di Olùṣọ́ Àgùntàn Wọn” (Ìsíkíẹ́lì 34:22-24)
ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN (1914 S.K.–LẸ́YÌN AMÁGẸ́DỌ́NÌ)
- 1914 S.K.—Jésù di Ọba, ó sì di Olùṣọ́ Àgùntàn àti Alákòóso, òun ló ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” sí Ìjọba Mèsáyà 
- 1919 S.K.—A yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti máa bójú tó àwọn àgùntàn Ọlọ́run - A kó àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró jọ lábẹ́ ìdarí Mèsáyà Ọba; ogunlọ́gọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ wọn nígbà tó yá 
- LẸ́YÌN AMÁGẸ́DỌ́NÌ—Àwọn ìbùkún tí àkóso Ọba náà mú wá máa wà títí láé 
Pa dà sí orí 8, ìpínrọ̀ 18 sí 22
3. “Ọba Kan Ni Yóò Máa Ṣàkóso Gbogbo Wọn” Títí Láé (Ìsíkíẹ́lì 37:22, 24-28)