ORIN 153
Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà
- 1. Ìbẹ̀rù ti bò mí— - Ìdààmú gbọkàn mi. - Ọlọ́run jọ̀ọ́ fi mí mọ̀nà; - Mo mọ̀ pó o máa gbà mí. - Ìṣòro pọ̀ láyé, - Ṣùgbọ́n mo gbà gbọ́ pé: - Atóófaratì mà ni ọ́; - Ayé mi dọwọ́ rẹ. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́ - Kí n lè máa rántí pé - Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà. - Kí n sì ṣọkàn akin; - Kí n fara dà á dópin. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà; - Ìwọ ni aṣẹ́gun. 
- 2. Tí ìbẹ̀rù bá dé. - Ó ń múni rẹ̀wẹ̀sì. - Ìwọ làpáta ààbò mi; - O kì í jáni kulẹ̀. - Jẹ́ kí n ní ìgboyà, - Kí n má sì ṣe jáyà. - Bó ti wù kí ‘ṣòro le tó— - Tìrẹ ni màá ṣe láé. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́ - Kí n lè máa rántí pé - Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà. - Kí n sì ṣọkàn akin; - Kí n fara dà á dópin. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà; - Ìwọ ni aṣẹ́gun. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, fún mi nígbàgbọ́ - Kí n lè máa rántí pé - Àwọn ọ̀tá kò lè borí wa. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n nígboyà. - Kí n sì ṣọkàn akin; - Kí n fara dà á dópin. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà; - Ìwọ ni aṣẹ́gun. - Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ní ìgboyà; - Ìwọ ni aṣẹ́gun.