ORIN 162
Mo Fẹ́ Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
1. Jèhófà Ọlọ́run mi,
Ìwọ ni Ẹlẹ́dàá mi.
O mọ ohun tó yẹ kí n ṣe
Kí n lè láyọ̀ tòótọ́.
O fẹ́ kí n ka Bíbélì,
Kí n lè túbọ̀ sún mọ́ ọ.
Ìyẹn máa jẹ́ kí n nírètí,
Káyé mi nítumọ̀.
(ÈGBÈ)
Mo fi ayé mi fún ọ.
Tọ́ mi sọ́nà, kí n ṣèfẹ́ rẹ.
Àwọn òfin rẹ dára,
Ó máa ń múnú mi dùn.
Màá wáyè kẹ́kọ̀ọ́,
Kí n lè sún mọ́ ọ.
2. Kìràkìtà ayé yìí
Lè jẹ́ kí ọwọ́ mi dí.
Síbẹ̀, ó yẹ kí n máa wáyè
Láti ka Bíbélì.
Ìyẹn máa jẹ́ kí n lókun
Láti borí àdánwò.
Mò ń gbàdúrà kí àwọn míì
lè láyọ̀ tí mò ń ní.
(ÈGBÈ)
Mo fi ayé mi fún ọ.
Tọ́ mi sọ́nà, kí n ṣèfẹ́ rẹ.
Àwọn òfin rẹ dára,
Ó máa ń múnú mi dùn.
Màá wáyè kẹ́kọ̀ọ́,
Kí n lè sún mọ́ ọ.
Mo fi ayé mi fún ọ.
Tọ́ mi sọ́nà, kí n ṣèfẹ́ rẹ.
Àwọn òfin rẹ dára,
Ó máa ń múnú mi dùn.
Màá wáyè kẹ́kọ̀ọ́,
Kí n lè sún mọ́ ọ.
Mo fi ayé mi fún ọ.
Tọ́ mi sọ́nà, kí n ṣèfẹ́ rẹ.
Àwọn òfin rẹ dára,
Ó máa ń múnú mi dùn.
Màá wáyè kẹ́kọ̀ọ́,
Kí n lè sún mọ́ ọ.
(Tún wo Mát. 5:6; 16:24; Àìsá. 40:8; Sm. 1:1, 2; 112:1; 119:97; 2 Tím. 4:4.)