ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 26-33
Bẹ Jèhófà Pé Kó Jẹ́ Kó O Ní Ìgboyà
Dáfídì túbọ̀ ní ìgboyà nígbà tó rántí bí Jèhófà ṣe gbà á sílẹ̀ láwọn ìgbà kan
- Jèhófà gba Dáfídì sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún nígbà tó wà lọ́mọdé 
- Jèhófà jẹ́ kí Dáfídì pa béárì kan kó lè dáàbò bo agbo ẹran rẹ̀ 
- Jèhófà ti Dáfídì lẹ́yìn nígbà tó pa Gòláyátì 
Kí ló máa jẹ́ ká ní ìgboyà bíi ti Dáfídì?
- Àdúrà 
- Iṣẹ́ ìwàásù 
- Lílọ sí ìpàdé 
- Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé 
- Fífún àwọn ẹlòmíì níṣìírí 
- Ká máa rántí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà kan