ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 60-68
Ẹ Yin Jèhófà, Olùgbọ́ Àdúrà
Tó o bá ṣèlérí fún Jèhófà, máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ
- Tó o bá ń gbàdúrà nípa àwọn ìlérí tó o ṣe, Jèhófà á fún ẹ lókun kó o lè mú un ṣẹ 
- Bí a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ni ìlérí tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ṣe 
Hánà
Tó o bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e
- Kí àdúrà wa lè nítumọ̀, a ní láti máa sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa fún Jèhófà 
- Tí àdúrà wa bá ṣe pàtó, ìdáhùn Jèhófà sí àdúrà wa á ṣe kedere sí wa 
Jésù
Jèhófà ni Olùgbọ́ àdúrà gbogbo àwọn tó lọ́kàn rere
- Jèhófà máa ń tẹ́tí sí “àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo” tó fẹ́ mọ̀ ọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀ 
- Ìgbàkigbà la lè gbàdúrà sí Jèhófà 
Kọ̀nílíù
Àwọn nǹkan tí mo fẹ́ fi sínú àdúrà mi.