ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 106-109
“Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”
Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tètè gbàgbé bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n là?
- Dípò kí wọ́n pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jèhófà, ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àtàwọn nǹkan tara ní wọ́n gbájú mọ́ 
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó?
- Pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́ 
- Máa ṣàṣàrò lórí ìrètí ọjọ́ ọ̀la 
- Tó o bá n gbàdúrà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn nǹkan pàtó tó ti ṣe fún ẹ