ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 8-9
Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn
Mátíù orí 8 àti 9 sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ní àgbègbè Gálílì. Bí Jésù ṣe wo àwọn èèyàn sàn fi hàn pé alágbára ni, àmọ́ ní pàtàkì, ó fi hàn pé ó láàánú, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gidigidi.
- Jésù wo adẹ́tẹ̀ kan sàn.—Mt 8:1-3. 
- Jésù wo ìránṣẹ́ ọ̀gá ológun kan sàn.—Mt 8:5-13 - Ó wo ìyá ìyàwó Pétérù sàn.—Mt 8:14, 15 - Ó lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ó sì mú àwọn aláìsàn lára dá. —Mt 8:16, 17 
- Jésù lé àwọn ẹ̀mí burúkú jáde sáàárín àwọn ẹlẹ́dẹ̀.—Mt 8:28-32 
- Jésù mú arọ lára dá.—Mt 9:1-8. - Ó mú obìnrin kan tó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀ lára dá, ó tún jí ọmọbìnrin Jáírù dìde.—Mt 9:18-26 - Ó la ojú afọ́jú, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.—Mt 9:27-34 
- Jésù rìnrìn-àjò kárí àwọn ìlú àti abúlé, ó sì ń wo onírúurú àìsàn àti òkùnrùn sàn.—Mt 9:35, 36 
Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa ṣàánú àwọn èèyàn, kí n sì nífẹ̀ẹ́ wọn?