ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | KÓLÓSÈ 1-4
Ẹ Bọ́ Ìwà Àtijọ́ Sílẹ̀, Kí Ẹ sì Fi Ìwà Tuntun Wọ Ara Yín Láṣọ
Ṣé àwọn ìwà kan wà tó o máa ń hù tẹ́lẹ̀, tó o ti yí pa dà nígbà tó o di ìránṣẹ́ Jèhófà? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà dùn sí ohun tó o ṣe. (Isk 33:11) Àmọ́, ó gba pé kó o máa báa lọ láti máa sapá kí àwọn ìwà àtíjọ́ yẹn má bàa gbérí mọ́, kó o sì máa fi àwọn ìwà tuntun ṣèwà hù. Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o lè rí àwọn ibi tó o ti lè sunwọ̀n sí i:
- Ṣé mo ṣì ń bínú sí ẹnì kan tó ṣe nǹkan tó dùn mí? 
- Ṣé mo máa ń ṣe sùúrù, kódà nígbà tí mo bá ń kánjú tàbí tó bá rẹ̀ mí? 
- Tí èrò ìṣekúṣe bá wá sí mi lọ́kàn, ṣe kíá ni mo máa ń gbé e kúrò lọ́kàn? 
- Ṣé mo máa ń ro nǹkan tí kò dáa nípa àwọn tó wá láti ìlú míì tàbí orílẹ̀-èdè míì? 
- Ṣé mo bínú sí ẹnì kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí àbí mo sọ̀rọ̀ burúkú sí i?