MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́ Lára Wọn?
Ṣé o ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni àbí alàgbà? O lè ní àwọn ẹ̀bùn àbínibí kan tàbí kó o mọ àwọn nǹkan kan táwọn míì ò mọ̀, o sì lè ti lọ sílé ìwé ju àwọn míì tá a yàn sípò nínú ìjọ yín. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè rí kọ́ lára àwọn arákùnrin yìí àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe alàgbà mọ́, bóyá torí ará tó ti di ara àgbà, àìlera tàbí àwọn ojúṣe míì nínú ìdílé.
WO FÍDÍÒ NÁÀ BỌ̀WỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌKÙNRIN ONÍRÌÍRÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- 1. Báwo ni Arákùnrin Richards ṣe fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún Arákùnrin Bello? 
- 2. Àṣìṣe wo ni Ben ṣe, kí sì nìdí? 
- 3. Ẹ̀kọ́ wo ni Ben rí kọ́ lára àpẹẹrẹ Èlíṣà? 
- 4. Bóyá arákùnrin ni ẹ́ tàbí arábìnrin, báwo lo ṣe lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn ará tó nírìírí, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn?