ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÉMÍÌSÌ 1-2
Ohun Tó Ń Fa Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú
Tí èròkerò bá wá sí ẹ lọ́kàn, ṣe àwọn nǹkan yìí:
- Sapá láti gbé e kúrò lọ́kàn, kó o sì máa ro nǹkan míì.—Flp 4:8 
- Ronú nípa àbájáde búburú tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tó o bá lọ́wọ́ sí ìwàkiwà.—Di 32:29 
- Gbàdúrà.—Mt 26:41 
Tí èròkerò bá sọ sí ẹ lọ́kàn, àwọn nǹkan rere wo lo lè ronú lé táá mú kó o gbé èròkerò náà kúrò lọ́kàn?