ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÉMÍÌSÌ 3-5
Máa Fi Ọgbọ́n Ọlọ́run Ṣèwà Hù
Ọgbọ́n Ọlọ́run máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ ká yanjú aáwọ̀, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa. Tá a bá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù, ó máa hàn nínú ìwà wa.
BI ARA RẸ PÉ: ‘Èwo nínú àwọn ànímọ́ yìí ni mo fi hàn láìpẹ́ yìí? Báwo ni mo ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú bí mo ṣe ń fáwọn ànímọ́ yìí hàn?’
- Kí n jẹ́ mímọ́ 
- Kí n lẹ́mìí àlàáfíà 
- Kí n máa fòye báni lò 
- Kí n ṣe tán láti ṣègbọràn 
- Kí n máa ń ṣàánú gan-an, kí n sì máa so èso rere 
- Kí n má ṣe ojúsàájú 
- Kí n má sì ṣe àgàbàgebè