MARCH 16-22, 2026
ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n
Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ìràpadà?
“Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?”—RÓÒMÙ 7:24.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bí ìràpadà ṣe jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, bó ṣe jẹ́ ká nírètí pé a máa bọ́ lọ́wọ́ àìpé àti bó ṣe jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
1-2. Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kẹ́nì kan gbà wá? (Róòmù 7:22-24) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
Ẹ JẸ́ ká fojú inú wo ọkùnrin kan tó wà lábẹ́ ilé tó ti wó lulẹ̀. Ọkùnrin náà ò kú, àmọ́ kò sí bó ṣe lè jáde lábẹ́ ilé náà torí àwókù ilé náà ti bò ó mọ́lẹ̀. Kò sí ohun tó lè ṣe ju pé kó máa kígbe pé káwọn èèyàn wá ran òun lọ́wọ́, kó sì máa retí pé ẹnì kan á wá yọ òun kúrò níbẹ̀.
2 Bọ́rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa náà ṣe rí nìyẹn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ó di ẹlẹ́ṣẹ̀. Gbogbo àwa àtọmọdọ́mọ ẹ̀ náà sì di ẹlẹ́ṣẹ̀ torí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ló dà bí ìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bo gbogbo aráyé mọ́lẹ̀, tá ò sì lè gbára wa sílẹ̀. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣe fún wa. (Ka Róòmù 7:22-24.) Ó sọ pé: “Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?” Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé láìjẹ́ pé ẹnì kan gba òun lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yìí, ó máa yọrí sí ikú. (Róòmù 6:23) Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Àfi kẹ́nì kan gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún!
Bí ẹni tí ilé wó bò mọ́lẹ̀ ṣe máa fẹ́ kẹ́nì kan gba òun sílẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún náà ti bò wá mọ́lẹ̀, a sì nílò ẹni tó máa gbà wá (Wo ìpínrọ̀ 1-2)
3. Àwọn nǹkan wo ni ìràpadà máa ṣe fún wa?
3 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ ìṣòro tó ní, ó sọ ohun tó fi hàn pé ọ̀nà àbáyọ wà. Lẹ́yìn tó béèrè pé: “Ta ló máa gbà mí lọ́wọ́ ara tó ń kú lọ yìí?” tayọ̀tayọ̀ ló sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ìràpadà tí Jésù san ni Jèhófà fi gbà wá.a Ìràpadà yìí ló máa jẹ́ ká lè (1) rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, (2) nírètí pé a máa bọ́ lọ́wọ́ àìpé àti (3) á jẹ́ ká pa dà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn nǹkan tí ìràpadà ṣe fún wa yìí, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà “Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí.” (Róòmù 15:13) Àá sì túbọ̀ mọyì Jésù, “ẹni tí a tipasẹ̀ rẹ̀ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà.”—Kól. 1:14.
ÌRÀPADÀ Ń JẸ́ KÁ RÍ ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ GBÀ
4-5. Àǹfààní wo ni ìràpadà ń ṣe fún gbogbo wa? (Oníwàásù 7:20)
4 A nílò ìràpadà torí ó máa jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀, ó lè jẹ́ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe. (Ka Oníwàásù 7:20.) Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣàgbèrè tàbí tó pààyàn. (Léf. 20:10; Nọ́ń. 35:30, 31) Àmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì ò burú tóyẹn, síbẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ ń jẹ́ torí pé ohun tí ò dáa ò lórúkọ méjì. Àpẹẹrẹ kan ni ohun tí onísáàmù náà Dáfídì sọ, ó ní: “Màá ṣọ́ ẹsẹ̀ mi kí n má bàa fi ahọ́n mi dẹ́ṣẹ̀.” (Sm. 39:1) Ìyẹn fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè mú ká dẹ́ṣẹ̀.—Jém. 3:2.
5 Ronú nípa àwọn nǹkan tó o ti sọ tàbí tó o ti ṣe sẹ́yìn. Ṣé o ti sọ̀rọ̀ kan rí tó o wá rí i pé kò yẹ kó o sọ? Àbí o ti ṣàṣìṣe kan tó o wá pa dà kábàámọ̀ ẹ̀? Ó dájú pé kò sẹ́ni tírú ẹ̀ ò ṣe rí. Bíbélì sọ pé: “Tí a bá sọ pé, ‘A ò ní ẹ̀ṣẹ̀,’ à ń tan ara wa, òótọ́ ò sì sí nínú wa.”—1 Jòh. 1:8.
6-7. Kí ni Jèhófà máa ń wò mọ́ wa lára kó tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ìràpadà ni Jèhófà máa ń wò mọ́ wa lára kó tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá. (Éfé. 1:7) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà máa ń gbójú fo àwọn àṣìṣe wa bíi pé kò tó nǹkan. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé inú Jèhófà kì í dùn tá a bá dẹ́ṣẹ̀. (Àìsá. 59:2) Torí pé ó máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ohun kan gbọ́dọ̀ wà tó máa wò mọ́ wa lára kó tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wá.
7 Nínú Òfin Mósè, kí Ọlọ́run tó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ẹran rúbọ. (Léf. 4:27-31; 17:11) Ẹbọ tí wọ́n ń rú yẹn ṣàpẹẹrẹ ẹbọ ìràpadà tí Jésù san àti àǹfààní tó máa ṣe wá. Ẹbọ ìràpadà yìí ló jẹ́ ká lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì fi hàn pé ó mọ bí ìràpadà tí Jésù san ṣe ṣeyebíye tó. Lẹ́yìn tó sọ irú àwọn ìwà tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, ó sọ pé: “A ti wẹ̀ yín mọ́; a ti yà yín sí mímọ́; a ti pè yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—1 Kọ́r. 6:9-11.
Ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú láyé àtijọ́ ṣàpẹẹrẹ ẹbọ ìràpadà tí Jésù san àti àǹfààní tó máa ṣe wá (Wo ìpínrọ̀ 6-7)
8. Kí ló yẹ kó o máa ronú nípa ẹ̀ bó o ṣe ń múra Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí?
8 Bó o ṣe ń múra Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí, máa ronú nípa àǹfààní tó o ti rí torí pé Jèhófà ń dárí jì ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, a kì í dára wa lẹ́bi mọ́ torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn tá a sì ti ronú pìwà dà, ìràpadà ló sì mú kí èyí ṣeé ṣe. Àmọ́, tó bá ṣòro fún ẹ láti gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́ ńkọ́? O lè máa ronú pé, ‘Mo mọ̀ pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àmọ́ mi ò rò pé ó lè dárí ji èmi.’ Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ nìyẹn, rántí pé: Jèhófà ló ń pinnu ẹni tí òun máa dárí jì, ó sì ti fún Jésù ọmọ ẹ̀ láṣẹ láti ṣèdájọ́. Kò fún ìwọ tàbí ẹlòmíì láṣẹ láti pinnu ẹni tóun máa dárí jì tàbí ẹni tóun ò ní dárí jì. Bíbélì sọ pé: ‘Tí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bí [Jèhófà] fúnra rẹ̀ ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.’ (1 Jòh. 1:6, 7) A gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí, bí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì míì náà ṣe jẹ́ òótọ́. Jèhófà máa ń wo ìràpadà mọ́ wa lára, ìyẹn sì máa ń mú kó ṣàánú wa, kódà Bíbélì sọ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.”—Sm. 86:5.
ÌRÀPADÀ JẸ́ KÁ NÍRÈTÍ PÉ A MÁA BỌ́ LỌ́WỌ́ ÀÌPÉ
9. Yàtọ̀ sí ìwà tí ò dáa tá a hù, kí ni nǹkan míì tí ẹ̀ṣẹ̀ ń tọ́ka sí? (Sáàmù 51:5 àti àlàyé ìsàlẹ̀)
9 Nínú Bíbélì, kì í ṣe ìwà tí ò dáa tá a hù nìkan ni ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” ń tọ́ka sí, ó tún ń sọ nípa àìpé tá a jogún nígbà tí wọ́n bí wa. (Ka Sáàmù 51:5 àti àlàyé ìsàlẹ̀.) Àìpé tá a jogún yìí ló máa ń jẹ́ ká hùwà tí ò dáa. Yàtọ̀ síyẹn, kì í jẹ́ kí ara wa jí pépé, ó ń mú ká máa ṣàìsàn, ká máa darúgbó, ká sì máa kú. Ìdí nìyẹn táwọn ọmọ ìkókó tí ò dẹ́ṣẹ̀ kankan fi máa ń ṣàìsàn, tí wọ́n sì ń kú. Ìyẹn náà ló fà á tó fi jẹ́ pé àti ẹni rere àti ẹni burúkú ló ń jìyà, tí wọ́n sì ń kú. Gbogbo àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù tá a jẹ́ aláìpé la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀.
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì di aláìpé?
10 Ẹ jẹ́ ká fojú inú wo bí nǹkan ṣe rí fún Ádámù àti Éfà lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì di aláìpé. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ò jẹ́ kínú wọn dùn. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ẹ̀rí ọkàn wọn, ìyẹn òfin tá a ‘kọ sínú ọkàn wọn’ bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn lẹ́bi. (Róòmù 2:15) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n mọ̀ pé nǹkan kan ti ṣe àwọn, ó sì máa ṣàkóbá fún wọn. Wọ́n mọ̀ pé àwọn wà níhòhò, ó sì yẹ káwọn wá nǹkan bora. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ohùn Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n lọ sá pa mọ́ bí ọ̀daràn. (Jẹ́n. 3:7, 8) Ni ẹ̀rí ọkàn wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá wọn lẹ́bi, ojú ń tì wọ́n, wọ́n sì ń ṣàníyàn. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àwọn nǹkan yìí á máa burú sí i, á sì máa dà wọ́n láàmú títí wọ́n á fi kú.—Jẹ́n. 3:16-19.
11. Àkóbá wo ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti ṣe fún wa?
11 Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ṣàkóbá fún Ádámù àti Éfà, bẹ́ẹ̀ ló ń fojú tiwa náà rí màbo. Ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún yìí máa ń jẹ́ ká ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìrora. Kò sí bá a ṣe gbìyànjú tó láti yanjú àwọn ìṣòro wa, ìṣòro náà ò lè tán nílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì sọ pé a ti “tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún asán.” (Róòmù 8:20) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí torí pé bójú ṣe ń pọ́n wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan náà ló ń pọ́n gbogbo aráyé lápapọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ti gbìyànjú gan-an láti tún àyíká ṣe, láti dín ìwà ọ̀daràn kù, láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé, kí àlàáfíà sì wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Síbẹ̀, kàkà kéwé àgbọn dẹ̀, ńṣe ló ń le sí i. Báwo wá ni ìràpadà ṣe lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a ti jogún?
12. Ìrètí wo la ní torí pé Jèhófà fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà?
12 Ìràpadà tí Jèhófà pèsè jẹ́ ká nírètí pé a máa “dá ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹrú ìdíbàjẹ́.” (Róòmù 8:21) Nínú ayé tuntun, ìràpadà máa jẹ́ ká di ẹni pípé. Lásìkò yẹn, àìsàn, ìrora àtàwọn nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa máa dohun ìgbàgbé. Yàtọ̀ síyẹn, a ò ní máa ṣàníyàn mọ́, a ò sì ní máa dára wa lẹ́bi mọ́ torí pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé á ti dohun àtijọ́. Bákan náà, a máa tún ayé ṣe, àá máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, àwọn nǹkan tá a bá dáwọ́ lé á sì máa yọrí sí rere torí pé Jésù Kristi “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” tó rà wá pa dà láá máa ṣàkóso nígbà yẹn.—Àìsá. 9:6, 7.
13. Nǹkan míì wo la lè ronú nípa ẹ̀ bá a ṣe ń múra Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí?
13 Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tá a bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Fojú inú wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn tó o bá jí tó o sì rí i pé ara ẹ jí pépé, tí ìwọ àtàwọn èèyàn ẹ ò bẹ̀rù mọ́ pé ebi máa pa yín, pé ẹ máa ṣàìsàn tàbí pé ẹ máa kú. Kódà ní báyìí, ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe ń ronú nípa “ìrètí tó wà níwájú wa.” Ìrètì yìí dà bí ‘ìdákọ̀ró fún ọkàn wa, ó dájú, ó sì fìdí múlẹ̀.’ (Héb. 6:18, 19) Bí ìdákọ̀ró ṣe máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ dúró digbí tí ìjì bá ń jà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní ṣe máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, tó sì máa ń jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa “san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Héb. 11:6) Ẹ ò rí i pé ìràpadà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìtùnú gbà báyìí, tó sì ń jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa!
ÌRÀPADÀ MÚ KÁ PA DÀ DI Ọ̀RẸ́ ỌLỌ́RUN
14. Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ti fà láàárín àwa àti Ọlọ́run, kì sì nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
14 Látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣẹ̀, kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé gbogbo aráyé lápapọ̀ ti di àjèjì sí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa. (Róòmù 8:7, 8; Kól. 1:21) Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni pípé ni Jèhófà, àwọn ìlànà ẹ̀ sì pé, torí náà kì í fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ rárá àti rárá. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ojú rẹ ti mọ́ jù láti wo ohun búburú, ìwọ kò sì ní gba ìwà burúkú láyè.” (Háb. 1:13) Ẹ̀ṣẹ̀ ti mú káwa èèyàn jìnnà sí Ọlọ́run. Ó dìgbà tá a bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ìràpadà ló sì lè mú kí èyí ṣeé ṣe.
15. Kí ni ìràpadà tù lójú, kí nìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe?
15 Bíbélì sọ pé Jésù “ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòh. 2:2) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹbọ ìpẹ̀tù” tún lè túmọ̀ sí “ohun tí a fi ń tuni lójú.” Báwo ni ìràpadà ṣe tu Jèhófà lójú? A ò lè retí pé kí ikú Ọmọ ẹ̀ tù ú nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìlànà òdodo Jèhófà ni ìràpadà tù lójú. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Róòmù 3:23-26) Kódà Jèhófà tiẹ̀ pe àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn ẹ̀ tọkàntọkàn ní olódodo kí Jésù tó kú. (Jẹ́n. 15:1, 6) Kí nìdí tí Jèhófà fi pè wọ́n ní olódodo? Ìdí ni pé ó dá Jèhófà lójú pé Jésù Ọmọ ẹ̀ máa san ìràpadà náà lọ́jọ́ iwájú. (Àìsá. 46:10) Ìràpadà yìí ló sì mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti pa dà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
16. Àwọn nǹkan míì wo lo tún lè ronú nípa ẹ̀ bó o ṣe ń múra Ìrántí Ikú Kristi ọdún yìí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ronú nípa àwọn nǹkan tó ò ń gbádùn báyìí torí pé o jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kíwọ náà máa pe Jèhófà ní “Baba” bí Jésù ṣe sọ. (Mát. 6:9) Nígbà míì sì rèé, o lè pè é ní “Ọ̀rẹ́” ẹ. Àmọ́ ìgbàkigbà tá a bá ń pe Jèhófà ní “Baba” tàbí “Ọ̀rẹ́” wa, ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ká sì rẹ ara wa sílẹ̀. Kí nìdí, ìdí ni pé aláìpé ni wá, torí náà àjọṣe èyíkéyìí tá a bá ní pẹ̀lú Jèhófà kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa. Ká má gbàgbé pé ìràpadà ló mú ká lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Jèhófà ti lo Jésù láti ‘mú gbogbo ohun mìíràn pa dà bá ara ẹ̀ rẹ́ bí ó ṣe fi ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró mú àlàáfíà wá.’ (Kól. 1:19, 20) Ìdí nìyẹn tá a fi ń gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tá a sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ṣì ni wá.
Ikú Jésù nìkan ló mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti pa dà di ọ̀rẹ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 16)
ÌRÀPADÀ JẸ́ KÁ RÍ I PÉ ALÁÀÁNÚ NI JÈHÓFÀ
17. Báwo ni ìràpadà ṣe jẹ́ ká rí i pé aláàánú ni Jèhófà? (Éfésù 2:4, 5)
17 Ìràpadà jẹ́ kó dá wa lójú pé “àánú [Jèhófà] pọ̀.” Ó “sọ wá di ààyè . . . nígbà tí a kú nínú àwọn àṣemáṣe wa.” (Ka Éfésù 2:4, 5.) “Àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” ń ké pé Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́ torí pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì nílò ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀. (Ìṣe 13:48) Jèhófà ń ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ti pé ó ń jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà, kí wọ́n lè sún mọ́ òun àti Jésù Ọmọ ẹ̀. (Jòh. 17:3) Àbẹ́ ò rí i pé òfo ni gbogbo ìsapá Sátánì já sí, torí ó rò pé ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà ò ní jẹ́ káwa èèyàn lè sún mọ́ Ọlọ́run mọ́, àmọ́ ibi tó fójú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀.
18. Bá a ṣe ń ronú nípa ìràpadà, kí lohun pàtàkì tó yẹ ká máa rántí?
18 Yàtọ̀ sí pé ká máa ronú nípa àǹfààní tí ìràpadà ń ṣe wá, ohun míì tó tún ṣe pàtàkì ni pé ká máa ronú nípa ìdí tí Jèhófà fi pèsè ìràpadà náà. Dípò ká ronú pé àǹfààní wa nìkan ni ìràpadà wà fún, ó yẹ ká máa rántí pé ìràpadà ni Jèhófà lò láti yanjú ọ̀rọ̀ tí Sátánì dá sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́n. 3:1-5, 15) Òhun tún ni Jèhófà lò láti sọ orúkọ ẹ̀ dí mímọ́, tó sì fi mú ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ ẹ̀ kúrò. Bákan náà, ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni. Kò tán síbẹ̀ o, bá a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Jèhófà fi inúure àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa ní ti pé a lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. (Òwe 27:11) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ìràpadà? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 19 Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ìràpadà lohun téèyàn san kó lè gba ẹnì kan sílẹ̀. Ikú ìrúbọ Jésù ló fi san ìràpadà tó gba àwọn olóòótọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.