ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w26 January ojú ìwé 8-13
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Borí Èrò Tí Kò Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Borí Èrò Tí Kò Tọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ PỌ́Ọ̀LÙ
  • OHUN TÍ PỌ́Ọ̀LÙ ṢE KÓ LÈ BORÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́
  • ÀWỌN NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÁ BORÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́
  • JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ MÁA SAN Ẹ́ LÉRÈ
  • Báwo Lo Ṣe Lè Borí Èrò Òdì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Fún Ẹ Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2026
w26 January ojú ìwé 8-13

MARCH 9-15, 2026

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Borí Èrò Tí Kò Tọ́

“Èmi abòṣì èèyàn!”—RÓÒMÙ 7:24.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ohun tá a lè ṣe tá a bá ń ní èrò tí kò tọ́.

1-2. Àwọn nǹkan wo ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà míì, báwo lọ̀rọ̀ ẹ̀ sì ṣe jọ tiwa lónìí? (Róòmù 7:21-24)

TÓ O bá ń ronú nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé o rò pé oníwàásù tó nígboyà ni, olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ tàbí ẹni tó kọ ọ̀pọ̀ ìwé nínú Bíbélì? Tó bá jẹ́ pé ohun tó o rò nìyẹn, o gbà á. Àmọ́, àwọn ìgbà kan wà tínú Pọ́ọ̀lù ò dùn, tó ṣàníyàn, tí nǹkan sì tojú sú u. Irú àwọn nǹkan yìí sì máa ń ṣe ọ̀pọ̀ lára wa lónìí.

2 Ka Róòmù 7:21-24. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, àwọn nǹkan tó sọ yẹn sì jọ ohun tó máa ń ṣe àwa náà lónìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olóòótọ́ ni Pọ́ọ̀lù tó sì wù ú kó máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àìpé tó jogún mú kó ṣòro fún un láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní gbogbo ìgbà. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù máa ń ronú nípa àwọn ìwà tó ti hù sẹ́yìn kó tó di Kristẹni àti ìṣòro míì tó ń bá yí. Àwọn nǹkan yìí kì í jẹ́ kínú ẹ̀ dùn.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Tún wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)

3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú Pọ́ọ̀lù kì í dùn láwọn ìgbà míì tó sì máa ń ní èrò tí kò tọ́,a ó máa ń sapá kó lè borí èrò náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló dé tí Pọ́ọ̀lù fi pe ara ẹ̀ ní “abòṣì èèyàn”? Báwo ló ṣe borí èrò tí kò tọ́? Báwo làwa náà ṣe lè borí èrò tí kò tọ́?

ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ PỌ́Ọ̀LÙ

4. Àwọn nǹkan wo ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá Pọ́ọ̀lù?

4 Àwọn ìwà tó ti hù sẹ́yìn. Kí Pọ́ọ̀lù tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ tó di Kristẹni, ọ̀pọ̀ nǹkan tí kò dáa ló ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta pa, kò sì rí ohun tó burú níbẹ̀. (Ìṣe 7:58; 8:1) Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ṣenúnibíni sí, ó sì hùwà ìkà sí wọn.—Ìṣe 8:3; 26:9-11.

5. Báwo ló ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó rántí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣe sẹ́yìn?

5 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, àwọn ìgbà míì wà tínú ẹ̀ kì í dùn tó bá rántí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣe sẹ́yìn. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kí ìwà ìkà tó hù nígbà tó ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni túbọ̀ máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ sáwọn ará Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 55 S.K., ó sọ pé: ‘Mi ò yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.’ (1 Kọ́r. 15:9) Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ó kọ lẹ́tà sáwọn ará Éfésù, ó sọ pé òun “kéré ju ẹni tó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́.” (Éfé. 3:8) Nígbà tó tún kọ lẹ́tà sí Tímótì, ó sọ pé, “asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.” (1 Tím. 1:13) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó bá lọ bẹ ìjọ kan wò, tó sì rí àwọn tó ti ṣenúnibíni sí tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn!

6. Kí ni nǹkan míì tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá Pọ́ọ̀lù? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Ẹ̀gún kan wà nínú ara rẹ̀. Ohun kan wà tó kó ẹ̀dùn ọkàn bá Pọ́ọ̀lù, ó sì fi wé ‘ẹ̀gún kan nínú ara rẹ̀.’ (2 Kọ́r. 12:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kò sọ ohun tó fà á, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àìsàn tàbí ìṣòro kan ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì lè jẹ́ nǹkan míì.b

7. Kí ló jẹ́ kó nira fún Pọ́ọ̀lù láti ṣe ohun tó tọ́? (Róòmù 7:18, 19)

7 Àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní. Kò rọrùn fún Pọ́ọ̀lù láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní. (Ka Róòmù 7:18, 19.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wù ú láti ṣe ohun tó dáa, àìpé kì í jẹ́ kó rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Òun fúnra ẹ̀ sọ pé ohun rere ló máa ń wu òun láti ṣe, àmọ́ nǹkan burúkú tóun ò fẹ́ ló máa ń wá sóun lọ́kàn. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sapá gan-an kó lè máa ṣe ohun tó tọ́. (1 Kọ́r. 9:27) Ẹ wo bó ṣe máa dun Pọ́ọ̀lù tó nígbà tó bá rí i pé òun ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó tóun ti pinnu pé òun ò ní ṣe!

OHUN TÍ PỌ́Ọ̀LÙ ṢE KÓ LÈ BORÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́

8. Àwọn nǹkan wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó jẹ́ kó lè borí àwọn ìwà tí ò dáa tó ní?

8 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará, ohun tó sọ jẹ́ ká rí i pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ran òun àtàwọn ará lọ́wọ́ láti borí àwọn ìwà tí ò dáa tí wọ́n ní. (Róòmù 8:13; Gál. 5:16, 17) Léraléra ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà tí ò dáa tó yẹ káwa Kristẹni yẹra fún. (Gál. 5:19-21, 26) Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ó máa ń ronú nípa àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní kó lè ṣàtúnṣe. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù á máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó lè mọ àwọn àyípadà tó yẹ kóun ṣe àti bóun ṣe máa ṣe é. Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù náà fi ìmọ̀ràn tó fún àwọn ará sílò.

9-10. Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní? (Éfésù 1:7) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Àwọn ìgbà míì wà tí Pọ́ọ̀lù máa ń rẹ̀wẹ̀sì, síbẹ̀ ó ṣì ń sapá kó lè máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, inú ẹ̀ máa ń dùn bó ṣe ń gbọ́ ìròyìn tó dáa nípa àwọn ará, táwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bá lọ bẹ ìjọ wò. (2 Kọ́r. 7:6, 7) Ó tún máa ń láyọ̀ bó ṣe mú àwọn ará lọ́rẹ̀ẹ́. (2 Tím. 1:4) Bákan náà, ó mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sóun. Ó dájú pé inú Pọ́ọ̀lù ń dùn torí ó ń fi “ẹ̀rí ọkàn tó mọ́” sin Ọlọ́run. (2 Tím. 1:3) Kódà nígbà tó wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ‘máa yọ̀ nínú Olúwa.’ (Fílí. 4:4) Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yìí jẹ́ ká rí i pé Pọ́ọ̀lù ò fìgbà gbogbo ronú mọ́ nípa àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Kò sí àní-àní pé nígbàkigbà tí èrò tí kò tọ́ bá wá sí i lọ́kàn, ó máa ń sapá kó lè gbé e kúrò lọ́kàn, á sì máa ro àwọn nǹkan táá jẹ́ kó máa láyọ̀.

10 Ohun míì tó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè borí ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ ni pé ó gbà pé nítorí òun ni Jésù ṣe kú. (Gál. 2:20; ka Éfésù 1:7.) Ìyẹn jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà ti dárí ji òun lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Róòmù 7:24, 25) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Pọ́ọ̀lù tó sì ti ṣe àwọn àṣìṣe kan sẹ́yìn, tayọ̀tayọ̀ ló fi “ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́” fún Ọlọ́run.—Héb. 9:12-14.

Fọ́tò: 1. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàṣàrò. 2. Ó rántí ìgbà tó pàṣẹ fún ọmọ ogun kan pé kó wọ́ Kristẹni kan jáde nínú ilé ẹ̀. 3. Ó ronú nípa bí Jésù ṣe kú lórí òpó igi oró.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣìṣe tí Pọ́ọ̀lù ṣe sẹ́yìn máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a nígbà míì, ó máa ń ronú nípa ìràpadà, ìyẹn sì jẹ́ kó lè borí ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 9-10)


11. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

11 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó lè jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwa náà ń sapá ká lè rí i pé a ò ro èròkerò, a ò sọ ìsọkúsọ, a ò sì ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. Ó lè máa ṣe wá bíi pé kì í ṣe irú wa ló lè múnú Jèhófà dùn. Nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Elizac tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ń sọ nípa kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní, ó sọ pé: “Tí mo bá ronú nípa Pọ́ọ̀lù, ọkàn mi máa ń balẹ̀ torí mo mọ̀ pé ohun tó ń ṣe mí ti ṣe òun náà rí. Ó tún jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ pé Jèhófà mọ ohun táwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ń bá yí.” Bíi ti Pọ́ọ̀lù, kí làwa náà lè ṣe ká lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ ká sì máa láyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa?

ÀWỌN NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÁ BORÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́

12. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?

12 Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà. Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa ronú bó ṣe tọ́. A lè fi àwọn nǹkan yìí wé àwọn nǹkan tá a máa ń ṣe kí ìlera wa lè dáa. Tá a bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, tá à ń ṣeré ìdárayá, tá a sì ń sùn dáadáa, ara wa máa jí pépé. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tá à ń múra ìpàdé sílẹ̀, tá à ń lọ sípàdé, tá à ń dáhùn, tá a sì ń wàásù déédéé, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, kò ní jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa.—Róòmù 12:11, 12.

13-14. Àǹfààní wo làwọn ará wa kan rí torí pé wọ́n ń ṣe ohun tó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

13 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Arákùnrin John. Nígbà tó wà lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlógójì (39), àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àìsàn jẹjẹrẹ. Nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́, ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Ó ń rò ó pé, ‘Báwo lọmọdé ara mi ṣe máa nírú àìsàn yìí?’ Nígbà yẹn, ọmọkùnrin ẹ̀ ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́tà lọ. Kí ló jẹ́ kí John borí èrò tí kò tọ́? Ó sọ pé, “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rẹ̀ mí, mo máa ń rí i dájú pé èmi àti ìdílé mi ń ṣe ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A kì í pa ìpàdé jẹ, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń wàásù, a sì máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé wa déédéé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí ò rọrùn.” Nígbà tí John rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ọkàn wa lè kọ́kọ́ gbọgbẹ́. Àmọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà máa fún wa lókun, á sì jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dá mi lójú pé Jèhófà máa ràn yín lọ́wọ́, bó ṣe ràn mí lọ́wọ́.”

14 Eliza tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sípàdé, tí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni mo máa ń rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì ń gbọ́ àdúrà mi. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n láyọ̀.” Arákùnrin Nolan tóun àti ìyàwó ẹ̀ Diane ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní Áfíríkà sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe, ó ní: “Láwọn ìgbà tí nǹkan bá tojú sú wa, a máa ń rí i dájú pé a ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Jèhófà sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa láyọ̀, ká sì máa ronú bó ṣe tọ́. A máa ń rán ara wa létí pé Jèhófà máa dúró tì wá. A ò mọ bó ṣe máa ṣe é o, àmọ́ ó dá wa lójú pé á ṣe bẹ́ẹ̀.”

15. Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ borí èrò tí kò tọ́? Ṣàpèjúwe.

15 Tá a bá ṣì ń ní èrò tí kò tọ́ lẹ́yìn tá a ti sa gbogbo ipá wa, àwọn nǹkan míì wà tá a lè ṣe. Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé ẹ̀yìn ń dùn ẹ́ tó o sì fẹ́ kó lọ, o lè ní kẹ́nì kan bá ẹ wọ́ ọ. Àmọ́ tí kò bá lọ, á jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kó o lè mọ ohun tó fa ìṣòro náà, o lè ṣèwádìí nípa ẹ̀ tàbí kó o lọ rí dókítà. Lọ́nà kan náà, tó o bá ṣì ń ní èrò tí kò tọ́ tó o sì fẹ́ borí ẹ̀, á dáa kó o ṣèwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run tàbí kó o ní kí ẹnì kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ gbà ẹ́ nímọ̀ràn. Jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

16. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá jẹ́ kó o mọ ohun tó fà á tó o fi ń ní èrò tí kò tọ́? (Sáàmù 139:1-4, 23, 24)

16 Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Ó dá Ọba Dáfídì lójú pé Jèhófà mọ òun dáadáa. Ìdí nìyẹn tó fi bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun mọ “àwọn ohun tó ń gbé [òun] lọ́kàn sókè.” (Ka Sáàmù 139:1-4, 23, 24.) Ìwọ náà lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ ohun tó fà á tó o fi ń ní èrò tí kò tọ́ àti bó o ṣe lè borí ẹ̀. O tún lè bi ara ẹ̀ láwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí ló ń kó mi lọ́kàn sókè gan-an? Ṣé ohun kan wà tí mo máa ń rí tàbí gbọ́ tó máa ń jẹ́ kí n lérò tí kò tọ́? Ṣé kì í ṣe pé mo máa ń ronú ṣáá nípa nǹkan náà dípò kí n gbé e kúrò lọ́kàn?’

17. Àwọn nǹkan wo lo lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ kó o lè máa ronú lọ́nà tó tọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà látìgbàdégbà, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ronú nípa ìràpadà tí Jèhófà pèsè àti bó ṣe ń dárí jì wá, ìyẹn jẹ́ kó rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ohun tó yẹ kíwọ náà ṣe nìyẹn. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, o lè lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn nǹkan míì tó o lè fi ṣèwádìí lédè ẹ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń fàánú hàn sí wa, bó ṣe ń dárí jì wá àti bó ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa. Tó o bá ti rí àwọn àpilẹ̀kọ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kọ ọ́ sílẹ̀, kó o sì lẹ̀ ẹ́ síbi tí wàá ti máa rí i. Láwọn ìgbà tó o bá tún ń ṣàníyàn, á dáa kó o pa dà kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àpilẹ̀kọ náà. Bó o ṣe ń kà á, máa ronú nípa bó ṣe kàn ẹ́ àti bó o ṣe lè fi sílò.—Fílí. 4:8.

Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń kẹ́kọ̀ọ́. Ó ń lo Bíbélì àti tablet, ó sì ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó kọ́. Ó tún ń kọ ọ̀rọ̀ sínú Bíbélì ẹ̀.

Tó o bá ń ní èrò tí kò tọ́, ṣèwádìí nípa ẹni tó nírú ìṣòro tó o ní nínú Bíbélì kó o lè mọ bó o ṣe máa borí ìṣòro náà (Wo ìpínrọ̀ 17)


18. Àwọn nǹkan wo làwọn ará kan kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ tó ràn wọ́n lọ́wọ́?

18 Eliza tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣèwádìí nípa Jóòbù nígbà tó ń dá kẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Ó níṣòro tó pọ̀, bí ìṣòro kan ṣe ń lọ, ni òmíì sì ń tẹ̀ lé e. Òótọ́ ni pé àwọn ìṣòro yìí mú kó rẹ̀wẹ̀sì, síbẹ̀ kò fi Jèhófà sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ìdí tóun fi ń jìyà.” (Jóòbù 42:1-6) Diane, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Èmi àtọkọ mi máa ń lo ìwé Sún Mọ́ Jèhófà láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ ká lè máa fìwà jọ òun torí àwọn ànímọ́ náà ń hàn nínú ìwà wa. Dípò ká máa dára wa lẹ́bi torí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe, ṣe là ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àyípadà tó yẹ ká lè máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Nǹkan tá a ṣe yìí jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”—Àìsá. 64:8.

JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ MÁA SAN Ẹ́ LÉRÈ

19. Kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

19 Kódà tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a ṣì lè máa ṣàníyàn tàbí kínú wa má dùn. Àwọn ọjọ́ kan máa wà tí gbogbo nǹkan lè tojú sú wa. Àmọ́, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, á jẹ́ ká lè borí èrò tí kò tọ́ tó bá wá sí wa lọ́kàn. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wàá máa láyọ̀ torí o mọ̀ pé o ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, inú ẹ̀ sì ń dùn sí ẹ.

20. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?

20 Tá a bá ṣì ń ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn tàbí àwọn ìṣòro míì tá a ní, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí ẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 143:10) À ń fojú sọ́nà de ayé tuntun níbi tí gbogbo èèyàn á ti máa ṣe ohun tó tọ́, tínú wọn á sì máa dùn. Tó bá dìgbà yẹn, kò ní sí ohunkóhun táá máa kó wa lọ́kàn sókè mọ́, ojoojúmọ́ làá sì máa fayọ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa!

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ló mú kí nǹkan tojú sú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà míì?

  • Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù máa láyọ̀ bó ṣe ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀ kì í dùn nígbà míì?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè borí èrò tí kò tọ́?

ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ọ̀rọ̀ náà, “èrò tí kò tọ́” tá a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí ń sọ nípa àwọn ìgbà tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí tínú wa ò dùn. Kì í ṣe ẹ̀dùn ọkàn tó le tó gba pé ká lọ rí dókítà.

b Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó ń kọ àwọn lẹ́tà rẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kó ní ìṣòro ojú, ìyẹn sì lè mú kó ṣòro fún un láti kọ àwọn lẹ́tà sí ìjọ, kó sì wàásù bó ṣe fẹ́. (Gál. 4:15; 6:11) Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun táwọn olùkọ́ èké ń ṣe tí ò dáa ló kó ẹ̀dùn ọkàn bá Pọ́ọ̀lù. (2 Kọ́r. 10:10; 11:5, 13) Ohun yòówù kó jẹ́, ohun tá a mọ̀ ni pé àwọn nǹkan yẹn ò múnú Pọ́ọ̀lù dùn.

c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́