- Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:                        96 
- Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn:                             239 
- Àròpọ̀ Iye Ìjọ:                               111,719 
- Iye Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé:             19,013,343 
- Iye Tó Jẹ Nínú Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé:                     12,604 
- Gongo Akéde:                              7,782,346 
- Ìpíndọ́gba Iye Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù:          7,538,994 
- Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2011 Lọ:             143,322 
- Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi:                  268,777 
- Ìpíndọ́gba Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù:       416,993 
- Ìpíndọ́gba Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Déedée Lóṣooṣù:         950,022 
- Àròpọ̀ Iye Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù:           1,748,697,447 
- Ìpíndọ́gba Iye Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣooṣù:      8,759,988 
Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2012, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná iye tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìn-lé-lọ́gọ́sàn-án [184,000,000] owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ wọn.
◼ Bákan náà, kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìlá [21,612]. Wọ́n wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.