Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2015
- Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 89 
- Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240 
- Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 118,016 
- Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 19,862,783 
- Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 15,177 
- Góńgó Akéde: 8,220,105 
- Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 7,987,279 
- Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2014: 1.5 
- Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 260,273 
- Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 443,504 
- Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé Lóṣooṣù: 1,135,210 
- Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 1,933,473,727 
- Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣooṣù: 9,708,968 
Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2015, ó ju igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] mílíọ̀nù owó dọ́là táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Bákan náà, kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ó lé mọ́kànlá [26,011]. Wọ́n wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.