SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
“Kò Lè Pé Ọdún Kan Tó O Fi Máa Kú!”
Zachaeus Martyn
WỌ́N BÍ I NÍ 1880
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1942
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin [72] nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
KÒ SÍ ẹnì kankan tó kọ́ Zachaeus lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó ka ìwé Salvation àti ìwé Duru Ọlọrun, ó rí i pé òun ti rí òtítọ́.
Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ Sunday kan lọ́dún 1941, Zachaeus bọ́ sọ́nà kó lè lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́. Ìrìn kìlómítà mẹ́jọ ló rìn gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kọjá. Wákàtí bíi mélòó kan kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ ló tí débẹ̀ torí pé kò mọ àkókò tí ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀. Zachaeus wá jókòó de àwọn ará títí wọ́n fi dé. Lẹ́yìn ìpàdé Sunday kẹta tó wá ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sọ fún ìjọ Áńgílíkà tó ń lọ tẹ́lẹ̀ ní àdúgbò rẹ̀ pé kí wọ́n yọ orúkọ òun kúrò lára àwọn ọmọ ìjọ wọn.
Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì yẹn fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní, “Ìwọ bàbá arúgbó yìí, tó o bá ń rin ìrìn kìlómítà mẹ́jọ gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè yìí, tó ò ń lọ tó o sì tún ń pa dà láti ilé ìpàdé àwọn aráabí yẹn, kò lè pé ọdún kan tó o fi máa kú!” Ojú rẹ̀ ni Zachaeus ń sọ̀kalẹ̀ òkè yẹn lọ, tó sì ń gùn ún bọ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ọdún márùn-ún gbáko. Ìgbà yẹn ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí kú! Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lẹ́yìn náà, kò sí nǹkan kan tó ṣe Zachaeus, ko-ko-ko ni ara rẹ̀ le.
Zachaeus sin Jèhófà tọkàntọkàn títí dìgbà tó kú ní ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97].