Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nílé Ìwé?
Ní May 24, 2022, ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan wáyé nílùú Uvalde, ìpínlẹ̀ Texas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí ìwé ìròyìn The New York Times ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ pé “ọkùnrin kan yìnbọn pa ọmọléèwé mọ́kàndínlógún (19) àti olùkọ́ méjì . . . nílé ìwé kan tó ń jẹ́ Robb Elementary.”
Ó bani nínú jẹ́ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn USA Today sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, “nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (249) ìgbà ni wọ́n yìnbọn láwọn ilé ìwé lọ́dún tó kọjá, iye yẹn ló sì pọ̀ jù látọdún 1970.”
Kí nìdí táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí fi ń ṣẹlẹ̀? Kí ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ láìka ìwà burúkú yìí sí? Ṣé ìwà ipá tiẹ̀ lè dópin? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Kí nìdí tí ìwà ipá fi ń pọ̀ sí i láyé?
- Bíbélì pe àkókò wa yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó jẹ́ ká mọ̀ pé lákòókò yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ ẹni tí “kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni” àti “ẹni tó burú gan-an,” wọ́n á sì máa hùwà ọ̀dájú àti ìwà ipá. Ó wá fi kún un pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ “á máa burú sí i.” (2 Tímótì 3:1-5, 13) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?” 
Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí àwọn ìwà burúkú bíi yíyìnbọn pa àwọn èèyàn nílé ìwé máa ṣẹlẹ̀?’ Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè yìí, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Èèyàn Rere?”
Kí ló lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ láìka ìwà ipá tó kún inú ayé yìí sí?
- “Nítorí gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí . . . nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”—Róòmù 15:4. 
Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun to yẹ kó o ṣe láti dáàbò bo ara ẹ nínú ayé tó kún fún ìwà ipá yìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka ìwé ìròyìn Jí! tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Will Violence Ever End?” lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Tó o bá fẹ́ mọ ohun táwọn òbí lè ṣe káwọn ìròyìn tó ń bani lẹ́rù má bàa máa kó àwọn ọmọ wọn lọ́kàn sókè, ka àpilẹ̀kọ náà “Disturbing News Reports and Your Children” lédè Gẹ̀ẹ́sì.
Ṣé ìwà ipá yìí tiẹ̀ lè dópin?
- “Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—Sáàmù 72:14. 
- “Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Míkà 4:3. 
Ọlọ́run máa ṣe ohun tí èèyàn èyíkéyìí ò lè ṣe. Ìjọba ẹ̀ máa pa gbogbo ohun ìjà run, á sì fòpin sí ìwà ipá pátápátá. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.”