Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nípakúpa Kárí Ayé?
Ní July 2022, kárí ayé ni wọ́n ti yìnbọn pa àwọn èèyàn nípakúpa:
- “Bí wọ́n ṣe pa gbajúmọ̀ olóṣèlú kan lórílẹ̀-èdè Japan [ìyẹn Shinzo Abe, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí ìjọba] ti dá wàhálà sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà, ó sì ti mú kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn kárí ayé torí pé ìwà ipá ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní orílẹ̀-èdè Japan, òfin sì tún wà nípa bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ lo ìbọn.”—July 10, 2022, The Japan Times. 
- “Bí ọkùnrin kan ṣé yìnbọn pa àwọn mẹ́ta ní ilé ìtajà Copenhagen lórílẹ̀-èdè Denmark ti kó ìpayà bá àwọn èèyàn.”—July 4, 2022, Reuters. 
- Lórílẹ̀-èdè South Africa, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló kú nígbà tí àwọn ọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò ìbọn sí ilé ìgbafẹ́ kan ní ìlú Soweto.”—July 10, 2022, The Guardian. 
- “Nígbà ọlidé July 4 lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ohun tó lé ní igba ó lé ogún (220 ) èèyàn ni wọ́n yìnbọn pa nípakúpa lópin ọ̀sẹ̀ yẹn.”—July 5, 2022, CBS News. 
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tírú ìwà ipá yìí máa dópin? Kí ni Bíbélì sọ?
Ìwà Ipá Máa Dópin
Bíbélì pe àkókó wa yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tí àwọn èèyàn á jẹ́ ẹni tó burú gan-an, tí wọ́n á sì máa hùwà ipá. (2 Tímótì 3:1, 3) Irú àwọn ìwà yìí ti mú kẹ́rù máa ba àwọn èèyàn. (Lúùkù 21:11) Bíbélì ṣèlérí pé àkókò kan ń bọ̀ tí ìwà ipá máa dópin tí ‘àwọn èèyàn á máa gbé ibi tí àlàáfíà ti jọba, nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.’ (Àìsáyà 32:18) Báwo ni ìwà ipá ṣe máa dópin?
Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run, ó sì máa run àwọn ohun ìjà ogun wómúwómú.
- “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a ó pa wọ́n run kúrò ní ayé.”—Òwe 2:22. 
- “[Ọlọ́run] ń fòpin sí ogun kárí ayé. Ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun nínú iná.”—Sáàmù 46:9. 
Ọlọ́run á mú káwọn èèyàn máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà, ìyẹn á sì mú kí ìwà ipá dópin títí láé.
- “Wọn ò ní fa ìpalára kankan, tàbí ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi, torí ó dájú pé ìmọ̀ Jèhófà máa bo ayé, bí omi ṣe ń bo òkun.”—Àìsáyà 11:9. 
- Kódà ní báyìí, Ọlọ́run ń kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé láti jáwọ́ nínú ìwà ipá àti lílo àwọn ohun ìjà. Ó fẹ́ kí ‘wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.’—Míkà 4:3. 
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ẹ̀rù ò ní bà wá mọ́ kárí ayé, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Aráyé Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Fa Ìbẹ̀rù?”
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó máa fòpin sí ìwà ipá pátápátá, ka àpilẹ̀kọ náà “Peace on Earth at Last!” Lédè Gẹ̀ẹ́sì.