ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 68
  • 2022: Ọdún Wàhálà àti Ìdàrúdàpọ̀—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2022: Ọdún Wàhálà àti Ìdàrúdàpọ̀—Kí Ni Bíbélì Sọ?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2022 ń jẹ́ ká mọ̀
  • Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lọ́dún tó ń bọ̀?
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Ń Yìnbọn Pa Àwọn Èèyàn Nípakúpa Kárí Ayé?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Lọ́wọ́ Sí Ogun—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 68
Àwòrán: 1. Ọkọ àtìyàwó kan ń wo àjálù tí ìjì fà létíkun. 2. Ìyá kan tí ìrònú bá àti ọmọ ẹ̀. 3. Wọ́n ń yẹ obìnrin kan wò bóyá ó ní àrùn Kòrónà.

Òsì: Ìjì Líle Ian, Florida, USA, September 2022 (Sean Rayford/Getty Images); àárín: Ìyá kan àti ọmọ ẹ̀ sá kúrò nílùú wọn, Donetsk, Ukraine, July 2022 (Alex Chan Tsz Yuk/SOPA Images/LightRocket via Getty Images); ọ̀tún: Wọ́n ń yẹ ọ̀pọ̀ èèyàn wò bóyá wọ́n lárùn Kòrónà, Beijing, China, April 2022 (Kevin Frayer/Getty Images)

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

2022: Ọdún Wàhálà àti Ìdàrúdàpọ̀​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Lọ́dún 2022, àwọn ìròyìn tó dá lórí ogun, ipò ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ àtàwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ ló gbalẹ̀ gbòde. Bíbélì nìkan ló ṣàlàyé ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń jẹ́ ká mọ̀.

Ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún 2022 ń jẹ́ ká mọ̀

Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2022 jẹ́ kó túbọ̀ hàn gbangba pé àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà báyìí. (2 Tímótì 3:1) Àkókò yẹn sì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Kíyè sí bí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa mu:

“Ogun.”​—Mátíù 24:6.

  • “2022 Ni Ọdún Tí Ogun Bẹ̀rẹ̀ Pa Dà Nílẹ̀ Yúróòpù.”a

Wo àpilẹ̀kọ náà “Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Gbógun Wọ Orílẹ̀-èdè Ukraine.”

“Àìtó oúnjẹ.”​—Mátíù 24:7.

  • “Ebi Àpafẹ́ẹ̀kú Pa Àwọn Èèyàn Lọ́dún 2022.”b

Wo àpilẹ̀kọ náà “Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Ti Dá Kún Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ.”

“Àjàkálẹ̀ àrùn.”​—Lúùkù 21:11.

  • “Bí àrùn monkeypox àti Kòrónà ṣe ń ṣọṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àrùn rọpárọsẹ̀ tá a mọ̀ sí Polio tún bẹ̀rẹ̀ sí í han àwọn èèyàn léèmọ̀. Ṣe là ń tinú àìsàn kan bọ́ sínú òmíì.”c

Wo àpilẹ̀kọ náà “Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn.”

“Àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù.”​—Lúùkù 21:11.

  • “Ojú ọjọ́ ò fara rọ rárá ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2022. Kárí ayé làwọn nǹkan bí ooru gbígbóná, ọ̀gbẹlẹ̀, igbó tó ń jó àti omíyalé ti ṣọṣẹ́ gan-an. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ojú ọjọ́ tí ò fara rọ yìí bà jẹ́, kódà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn lẹ̀mí wọn lọ sí i, ó sì sọ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé di aláìnílé mọ́.”d

Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Ooru Ṣe Ń Mú Gan-an Kárí Ayé?”

“Rògbòdìyàn [tàbí, “rúkèrúdò; ìdàrúdàpọ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé].”​—Lúùkù 21:9.

  • “Torí pé inú ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn nítorí ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ àti bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń gbówó lórí, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn wọ́de lọ́dún 2022 láti fi ẹ̀hónú hàn sí ìjọba.”e

Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Nǹkan Ṣe Túbọ̀ Ń Gbówó Lórí Kárí Ayé?”

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lọ́dún tó ń bọ̀?

Kò sẹ́ni tó lè sọ ní pàtó pé báyìí ni nǹkan ṣe máa rí lọ́dún 2023. Àmọ́ ohun kan tá a mọ̀ ni pé, láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tún ayé ṣe. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba yẹn máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìyà fáwa èèyàn, á sì jẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí ṣẹ.​—Mátíù 6:9, 10.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o fi ìmọ̀ràn Jésù Kristi sọ́kàn pé ká “máa ṣọ́nà,” ká sì máa kíyè sí bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyè ṣe ń fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. (Máàkù 13:37) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nísinsìnyí àti bó ṣe lè jẹ́ kí ọkàn ìwọ àti ìdílé rẹ balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, jọ̀wọ́ kàn sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

a AP News, “2022 Ni Ọdún Tí Ogun Bẹ̀rẹ̀ Pa Dà Nílẹ̀ Yúróòpù,” látọwọ́ Jill Lawless, December 8, 2022.

b “Ìṣòro Àìtó Oúnjẹ Kárí Ayé” látọ̀dọ̀ World Food Programme.

c JAMA Health Forum, “Àjàkálẹ̀ Àrùn Gbalẹ̀ Gbòde, Látorí Kòrónà Dórí Monkeypox, Polio Àtàwọn Àrùn Míì,” látọwọ́ Lawrence O. Gostin, JD, September 22, 2022.

d Earth.Org, “Kí Ló Fà Á Tí Ojú Ọjọ́ Ò Fi Bára Dé Nígbà Ẹ̀ẹ̀rùn Ọdún 2022?” látọwọ́ Martina Igini, October 24, 2022.

e Carnegie Endowment for International Peace, “Ipò Ọrọ̀ Ajé Tó Dẹnu Kọlẹ̀ Mú Káwọn Èèyàn Wọ́de Gan-an Lọ́dún 2022,” látọwọ́ Thomas Carothers àti Benjamin Feldman, December 8, 2022.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́