ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 127
  • Ọ̀rọ̀ Ìtùnú Látinú Bíbélì Fáwọn Tí Wàhálà Lé Kúrò Nílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ìtùnú Látinú Bíbélì Fáwọn Tí Wàhálà Lé Kúrò Nílé
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tù Ẹ́ Nínú
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Jẹ́ Kó O Nírètí
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Fún Ẹ Lọ́gbọ́n
  • Ogun Lé Ọ̀pọ̀ Èèyàn Kúrò Lórílẹ̀-Èdè Ukraine
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Àjèjì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa ‘Fayọ̀ Sin Jèhófà’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Kí Ni Ojútùú Rẹ̀?
    Jí!—1996
  • Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 127
Àwọn méjì kan wà níbi tí wọ́n máa ń kó àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò nílé sí, wọ́n jókòó sílẹ̀, báàgì mélòó kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n ń wo àwọn tó kù.

Imagination World/stock.adobe.com

Ọ̀rọ̀ Ìtùnú Látinú Bíbélì Fáwọn Tí Wàhálà Lé Kúrò Nílé

Wa Àpilẹ̀kọ Yìí Jáde

Lọ́dọọdún, àìmọye èèyàn ló ń sá kúrò nílé nítorí ogun tàbí wàhálà míì. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ lọ́wọ́lọ́wọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ yé Ọlọ́run, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ka Bíbélì, wàá rí àwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ ọ̀la.

Ọ̀gbẹ́ni Christos Stylianides tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kọmíṣọ́nnà Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, ìyẹn European Union commissionera sọ pé: ‘Kì í ṣe àwọn ohun kòṣeémánìí nìkan ló yẹ ká fún àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò nílùú, ó tún yẹ ká sọ ohun tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.’b Tẹ́nì kan bá gbà pé nǹkan ṣì máa dáa, á jẹ́ kó lè fara da ìṣòro. Ó tún yẹ ká sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn torí ohun tójú wọn ti rí kí wọ́n lè fara da ẹdùn ọkàn wọn.

“Nígbà tí mo sá kúrò lórílẹ̀-èdè mi tí mo sì fi ìdílé mi sílẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn bá mi, mi ò sì rẹ́ni fojú jọ. Ẹ̀rù bà mí, inú mi ò dùn, ọkàn mi ò sì balẹ̀ rárá.”—Emmanuel, Haiti.

Ṣérú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ síwọ náà? Tó bá jẹ́ pé ogun tàbí wàhálà míì ti mú kó o sá kúrò níbi tó ò ń gbé, o nílò ẹnì kan tó máa tù ẹ́ nínú, tó sì máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Báwo ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tù Ẹ́ Nínú

Àwòrán ẹnì kan tó ń ka Bíbélì, ohun tó ń kà sì tù ú nínú.

Bíbélì sọ pé: “Jèhófàc . . . nífẹ̀ẹ́ àjèjì.”—Diutarónómì 10:17, 18.

Èyí fi hàn pé ẹnì kan wà tó rí tìẹ rò. Jèhófà ló ni Bíbélì, ọ̀rọ̀ ẹ yé e, ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, ọ̀rọ̀ ẹ sì jẹ ẹ́ lógún.

Bíbélì sọ pé: “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.”—Sáàmù 145:18.

Èyí fi hàn pé tó o bá ń gbàdúrà, ó ń gbọ́ ẹ. Jèhófà máa jẹ́ kí ọkàn ẹ balẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n sì wà nínú Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú . . . Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.”—Jóòbù 34:10, 12.

Èyí fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fìyà jẹ ẹ́. Kì í ṣe pé Ọlọ́run ń fìyà jẹ ẹ́ tàbí pé ó ń máyé nira fún ẹ kó lè dán ẹ wò.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Jẹ́ Kó O Nírètí

Àwòrán ẹnì kan tó ń ronú nípa ohun tó kà nínú Bíbélì.

Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo báwọn nǹkan tí Bíbélì sọ ṣe ń fi àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì ti lé kúrò nílé lọ́kàn balẹ̀.

Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìfihàn 21:4.

Èyí fi hàn pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ìyà ò ní máa jẹ wá mọ́. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa yanjú gbogbo ìṣòro tó ń mú káyé nira fún wa.

“Ọlọ́run máa tó fòpin sí ìrẹ́jẹ àtàwọn nǹkan burúkú míì tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀ sórí ìgbà tí kò ní sí ìyà mọ́.”—Karla, El Salvador.

Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn.”—Àìsáyà 65:17.

Èyí fi hàn pé a ò ní máa rántí àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa mọ́. Ọlọ́run máa rí i dájú pé àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ ò ní máa kó ìdààmú ọkàn bá ẹ mọ́.

“Bíbélì sọ pé a ò ní rántí àwọn ohun tó ń bà wá lọ́kàn jẹ́ mọ́, ẹ̀dùn ọkàn tó bá wa torí àwọn ohun tá a pàdánù ò sì ní sí mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún wa rárá, ìrètí yìí máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo ìṣòro wa máa yanjú láìpẹ́.”—Natalia, Ukraine.

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ tí . . . ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Èyí fi hàn pé ìgbà kan ń bọ̀ tó jẹ́ pé ìjọba tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ gbé kalẹ̀ láá máa ṣàkóso ayé. Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, Ìjọba Ọlọ́run nìkan láá sì máa ṣàkóso ayé. Ìjọba yìí máa mú kí àlàáfíà tòótọ́ wà láyé, ọkàn gbogbo èèyàn á balẹ̀, ìrẹ́jẹ ò ní sí mọ́, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún gbogbo èèyàn.—Míkà 4:3, 4.

“Mo mọ̀ pé tí Ìjọba Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé láìpẹ́, kò ní sí ìníra mọ́, a ò ní ka àwọn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ, àwa èèyàn ò ní máa fura síra wa mọ́, kò sì ní sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà mọ́.”—Mustafa, Middle East.

Tọkọtaya kan tó wà níbi tí wọ́n kó àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò nílé sí jọ ń ka Bíbélì.

Jẹ́ kí àwọn ìlérí inú Bíbélì tù ẹ́ nínú

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Fún Ẹ Lọ́gbọ́n

Àwòrán ẹnì kan tó wá mọ ohun tó yẹ kó ṣe nígbà tó ń ka Bíbélì.

Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ kó o gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Á jẹ́ kó o lè fara dà á, kò ní jẹ́ kó o bọkàn jẹ́ jù nítorí àwọn nǹkan tó o pàdánù, á sì jẹ́ kó o mọ ohun tó kàn láti ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìlànà Bíbélì tó ṣèrànwọ́ fáwọn kan tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò níbi tí wọ́n ń gbé.

Bíbélì sọ pé: “Tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”—Lúùkù 12:15.

Bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀dùn ọkàn ńlá ló bá ẹ torí àwọn nǹkan tó o pàdánù. Tó o bá ronú jinlẹ̀ tó o sì fi sọ́kàn pé ẹ̀mí ló ṣe pàtàkì jù, o ò ní bọkàn jẹ́ jù.

“Ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ìní lọ. Àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn nígbà míì tó jẹ́ pé owó tàbí àwọn nǹkan ìní ò ní wúlò rárá.”—Natalia, Ukraine.

Bíbélì sọ pé: “Má sọ pé, ‘Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?’ ”—Oníwàásù 7:10.

Bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Òótọ́ ni pé nǹkan lè má rọrùn fún ẹ báyìí, àmọ́ tó o bá ń fi bí nǹkan ṣe rí báyìí wé bó ṣe rí tẹ́lẹ̀, ńṣe ni inú ẹ á kàn máa bà jẹ́.

“Nígbà tí mo gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, tí mo sì ṣara gírí, ó jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa.”—Eli, Rwanda.

Bíbélì sọ pé: “Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”—1 Tímótì 6:8.

Bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Tó o bá ti láwọn ohun kòṣeémánìí, jẹ́ kó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní máa kó ara ẹ lọ́kàn sókè, ọkàn ẹ á sì balẹ̀.

“Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ń jẹ́ kí n túbọ̀ ronú jinlẹ̀, kì í jẹ́ kí n máa ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tá a pàdánù. Inú èmi àtìyàwó mi dùn pé a wà láàyè, a sì ríbi forí pa mọ́ sí.”—Ivan, Ukraine.

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”—Mátíù 7:12.

Bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Tó o bá ń ní sùúrù tó o sì ń hùwà rere sáwọn èèyàn, o ò ní máa fi bẹ́ẹ̀ níṣòro pẹ̀lú wọn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ará ìlú tó ò ń gbé báyìí á fẹ́ràn ẹ.

“Tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ìlú tó ò ń gbé báyìí, tó ò ń hùwà rere sí wọn, tó o sì ń fi ìfẹ́ bá wọn lò, wọ́n á fẹ́ràn ẹ, wọ́n á sì sún mọ́ ẹ.”—Angelo, Sri Lanka.

Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run . . . máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.”—Fílípì 4:6, 7.

Bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ, àwọn nǹkan tó ń já ẹ láyà àtàwọn nǹkan tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè, kó o sì ní kó pèsè àwọn nǹkan tó o nílò fún ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìṣòro ẹ ò ní máa kó ẹ lọ́kàn sókè ju bó ṣe yẹ lọ, ara sì máa tù ẹ́.

“Gbogbo ìgbà tí mo bá níṣòro ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì máa ń dáhùn àdúrà mi. Àwọn nǹkan tí mo kọ́ látinú Bíbélì ló ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.”—Yol, South Sudan.

“Àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ kí n lè fara da ìṣòro mi.”—Valentina, Ukraine.

“Ọkàn mi máa ń balẹ̀ tí mo bá rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”—Emmanuel, Haiti

Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ìlérí míì tí Ọlọ́run ṣe tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń fúnni nírètí àti ìdí tó o fi lè gbà pé àwọn ìlérí náà máa ṣẹ, sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú wọn máa dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn tí Bíbélì sọ pé wọ́n di àjèjì

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò nílé. Àwọn ìtàn yẹn jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe bójú tó wọn.

  • Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run di àjèjì nílẹ̀ Íjíbítì, níbi tí wọ́n ti ń fojú pọ́n wọn. Ọlọ́run rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ wọ́n, ó sì gbà wọ́n sílẹ̀. (Ẹ́kísódù 1:13, 14; 2:23-25) Jèhófà fún wọn láwọn ohun kòṣeémánìí títí wọ́n fi dé ibi tó ń mú wọn lọ. (Sáàmù 105:40, 41) Nígbà tó yá, ó rán wọn létí bó ṣe bójú tó wọn àti bó ṣe yẹ káwọn náà máa bójú tó àwọn àjèjì tó ń gbé láàárín wọn.—Ẹ́kísódù 23:9.

  • Ìwé Rúùtù jẹ́ ká mọ̀ pé ìyàn tó mú ló mú kí Náómì àti ìdílé ẹ̀ sá kúrò nílé. Nígbà tí ọkọ Náómì àti ọmọkùnrin ẹ̀ méjèèjì kú, torí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú, ó lo Rúùtù ìyàwó ọmọ ẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́, kó sì tù ú nínú.—Rúùtù 1:1-5, 15, 16, 20, 21; 2:11.

  • Nígbà tí Jésù wà lọ́mọdé, ìyá ẹ̀ àti bàbá ẹ̀ sá lọ sí Íjíbítì kí wọ́n má bàa rí Jésù pa. Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n tètè kúrò káwọn tó fẹ́ pa Jésù tó dé, ó sì tún ràn wọ́n lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tí nǹkan ò fi rọrùn yẹn.—Mátíù 2:13-16.

Lóde òní, gbogbo ìgbà kọ́ ni Jèhófà máa ń gba àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́nà ìyanu. Àmọ́, ó máa ń tù wọ́n nínú, ó máa ń fún wọn ní ọgbọ́n kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ó sì máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Wa àpilẹ̀kọ yìí jáde, tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé, kó lè rọrùn láti máa mú kiri.

Wà á jáde

a Àjọ kan tó ń rí sí àwọn tí ogun tàbí wàhálà míì lé kúrò nílùú ìyẹn UN Refugee Agency sọ pé lára àwọn tí wọ́n lè gba ìrànwọ́ ni àwọn tó sá kúrò nílé àmọ́ tí wọ́n ṣì wà lórílẹ̀-èdè wọn àti àwọn tó sá lọ sí orílẹ̀-èdè míì àmọ́ tó jẹ́ pé lábẹ́ òfin, wọ́n lè má kà wọ́n sí àwọn tó yẹ kó gba ìrànwọ́.

b European Union Commissioner for Humanitarian Aid and Crisis Management.

c Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́