Ṣé Jòhánù Arinibọmi Wà Lóòótọ́?
Àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòhánù Arinibọmi, ẹni tó wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ní Jùdíà. Ṣé ohun tí àwọn òpìtàn sọ nípa ọkùnrin yìí bá ohun tí Bíbélì sọ mu? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀ wò:
- Bíbélì sọ pé: “Jòhánù Arinibọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Jùdíà, ó ń sọ pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, torí Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 3:1, 2) Ǹjẹ́ àwọn ìwé ìtàn jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? Bẹ́ẹ̀ ni. - Òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń jẹ́ Flavius Josephus ṣàpèjúwe ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Jòhánù, tí orúkọ àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Arinibọmi,” ẹni “tó gba àwọn Júù níyànjú láti máa gbé ìgbé ayé òdodo,” kí wọ́n “ní ìtara ìsìn fún Ọlọ́run” kí wọ́n sì “wá ṣe ìrìbọmi.”—Jewish Antiquities, Book XVIII. 
- Bíbélì ṣàlàyé pé Jòhánù bá Hẹ́rọ́dù Áńtípà wí, ẹni tó jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì àti Pèríà. Júù aláfẹnujẹ́ ni Hẹ́rọ́dù, ó sì sọ pé òun ń ṣègbọràn sí Òfin Mósè. Jòhánù sọ pé bí Hẹ́rọ́dù ṣe fẹ́ Hẹrodíà, tó jẹ́ ìyàwó arákùnrin rẹ̀ kò bójú mu rárá. (Máàkù 6:18) Ohun tí Bíbélì sọ yìí bá ohun tí àwọn ìwé míì sọ mu. - Òpìtàn Josephus sọ pé ìfẹ́ Hẹrodíà “kó sí” Áńtípà lórí àti pé “kíá ló sọ fún un pé òun fẹ́ kó di ìyàwó òun.” Hẹrodíà gbà, ó sì fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bó ṣe lọ fẹ́ Áńtípà nìyẹn. 
- Bíbélì sọ pé “àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká máa ń lọ sọ́dọ̀ [Jòhánù], ó ń ṣèrìbọmi fún wọn ní odò Jọ́dánì.”—Mátíù 3:5, 6. - Josephus jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lóhun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ, ó kọ̀wé pé ńṣe ni “àwọn èrò” ń wọ́ wá láti rí Jòhánù àti pé “ohun tí Jòhánù ń kọ́ wọn wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an [tàbí, ó ru wọ́n lọ́kàn sókè] lọ́nà tó ga jù lọ. 
Ó ṣe kedere pé òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà Josephus gbà pé Jòhánù Arinibọmi ti gbé ayé rí, torí náà, ó yẹ káwa náà gbà bẹ́ẹ̀.