ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/1 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Jòhánù Arinibọmi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé Jòhánù Arinibọmi Wà Lóòótọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jòhánù Ń Dín Kù, Àmọ́ Jésù Ń Pọ̀ Sí I
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/1 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

A ha nilati tọka si Johannu ti o baptisi Jesu gẹgẹ bi “Johannu Baptisti” tabi “Johannu Arinibọmi” bi?

Orukọ oyè-iṣẹ́ mejeeji ni ó tọna ti a sì fi ẹ̀rí ti o bá Bibeli mu tì nídìí.

Ti Johannu ni lati “pese eniyan ti a mura silẹ de Oluwa,” eyi ti oun ṣe nipa ‘wiwaasu baptismu ironupiwada fun imukuro ẹṣẹ.’ (Luku 1:17; 3:3) Aposteli Matteu kọwe pe: “Johannu Baptisti wá, o ń waasu ni ijù Judea, ó sì ń wi pe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀. . . . Nigba naa ni awọn ara Jerusalemu, ati gbogbo Judea . . . jade tọ̀ ọ́ wá, a sì ń baptisi wọn lọdọ rẹ̀ ni odò Jordani, wọn ń jẹwọ ẹṣẹ wọn.”—Matteu 3:1-6.

Ṣakiyesi pe Matteu fi Johannu hàn gẹgẹ bi “Baptisti.” Matteu, ẹni ti o mú akọsilẹ rẹ̀ bá awọn Ju mu ni kedere, gbọdọ ti nimọlara pe awọn Ju yoo mọ ẹni ti “Baptisti” jẹ́. Ó lo “Baptisti” gẹgẹ bi iru orukọ àpèlé kan.a Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lo “Johannu Baptisti,” gẹgẹ bi awọn iranṣẹ Herodu ti ṣe.—Matteu 11:11, 12; 14:2; 16:14.

Ọmọ-ẹhin naa Marku rohin ìlò ti o farajọra ti “Baptisti.” (Marku 6:25; 8:28) Ṣugbọn nigba ti o ń fi Johannu hàn, Marku pè é ni “Johannu arinibọmi.” (Marku 1:4, NW) Ọ̀rọ̀ Griki ti o wà ni Marku 1:4 yàtọ̀ fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ si ti awọn ẹsẹ miiran. Marku 1:4 ni a tun lè tumọ si “Ẹni ti ń baptisi.” Marku ń tẹnumọ ohun ti Johannu ń ṣe; oun ni ó ń baptisi, arinibọmi naa.

Bi o ti wu ki o ri, kò farahan pe, a gbọdọ fi iyatọ saaarin awọn ọ̀nà wọnyi ti a gba tọka si Johannu. Ni Marku 6:24, 25 (NW), a kà nipa Salome pe: “Ó sì jade lọ ó sì wi fun iya rẹ̀ pe: ‘Ki ni emi nilati beere fun?’ Ó wi pe: ‘Orí Johannu Arinibọmi.’ Lẹsẹkẹsẹ ó wọle tọ ọba lọ pẹlu ikanju ó sì beere ibeere tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ rẹ̀, wi pe: ‘Mo fẹ́ ki iwọ fun mi ni orí Johannu Baptisti ninu àwopọ̀kọ́ nisinsinyi.’” Orukọ oyè-iṣẹ́ mejeeji ni a lò ni pàṣípààrọ̀.

Awọn kan lè lóye “Baptisti” ni ibamu pẹlu itumọ keji ninu iwe atumọ-ede: “Mẹmba kan tabi olùtòròpinpin mọ́ ẹ̀ka-ìsìn ajihinrere Protẹstanti tí a ń fi iru akoso ẹ̀ka-ìsìn ati iribọmi nipasẹ títẹ awọn onigbagbọ nikan bọ inu omi sami si.” Johannu dajudaju kìí ṣe iyẹn.

Fun idi eyi, ati “Johannu Baptisti” ati “Johannu Arinibọmi” tọna ó sì bojumu.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Opitan Ju naa Flavius Josephus kọwe nipa “Johannu, ti a pè ni orukọ àpèlé naa Baptisti.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́