Monday, October 13
Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.—1 Sám. 16:7.
Tó bá ń ṣe wá nígbà míì bíi pé a ò já mọ́ nǹkan kan, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló fà wá sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Ó ń rí àwọn ànímọ́ dáadáa tá a ní táwa lè má rí, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (2 Kíró. 6:30) Torí náà, ó yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jèhófà sọ nígbà tó sọ pé a ṣeyebíye lójú òun. (1 Jòh. 3:19, 20) Ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn kan lára wa ti ṣe àwọn nǹkan kan tá a ṣì ń kábàámọ̀ ẹ̀ báyìí. (1 Pét. 4:3) Àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan náà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ìwọ ńkọ́, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ torí pé ó ti ṣe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gan-an tó bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn. (Róòmù 7:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, ó sì ti ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó sọ pé òun lòun “kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì,” òun sì ni “ẹni àkọ́kọ́” nínú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—1 Kọ́r. 15:9; 1 Tím. 1:15. w24.03 27 ¶5-6
Tuesday, October 14
Wọ́n fi ilé Jèhófà sílẹ̀.—2 Kíró. 24:18.
Ohun tá a rí kọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Ọba Jèhóáṣì ṣe ni pé ó yẹ ká yan àwọn ọ̀rẹ́ táá jẹ́ ká níwà rere, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń múnú ẹ̀ dùn. Kì í ṣe àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ nìkan la lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́, a tún lè yan àwọn tó dàgbà jù wá lọ tàbí àwọn tó kéré sí wa. Ẹ má gbàgbé pé Jèhóáṣì kéré gan-an sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jèhóádà. Tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn tí mo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára? Ṣé wọ́n á jẹ́ kí n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti òtítọ́ tó ń kọ́ wa? Ṣé wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń bá mi sòótọ́ ọ̀rọ̀ tí mo bá ṣohun tí ò dáa àbí ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé ohun tí mo ṣe dáa?’ (Òwe 27:5, 6, 17) Ká sòótọ́, táwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò yẹ kó o máa bá wọn rìn. Àmọ́ tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ọ̀rẹ́ gidi nìyẹn. Má fi wọ́n sílẹ̀ o!—Òwe 13:20. w23.09 9-10 ¶6-7
Wednesday, October 15
Èmi ni Ááfà àti Ómégà.—Ìfi. 1:8.
Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì, ómégà sì ni lẹ́tà tó kẹ́yìn. Torí náà, nígbà tí Jèhófà sọ pé òun ni “Ááfà àti Ómégà,” ohun tó ń sọ ni pé tóun bá bẹ̀rẹ̀ nǹkan, ó dájú pé òun máa parí ẹ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Ádámù àti Éfà, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́n. 1:28) Ìgbà tí Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí ni “Ááfà.” Àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn bá kún ayé, tí wọ́n sì sọ ọ́ di Párádísè ni Jèhófà máa sọ pé “Ómégà.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá “ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn” tán, ó sọ ohun tó fi hàn pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ. Ó sọ pé òun máa ṣe ohun tóun ní lọ́kàn fáwa èèyàn àti ayé ní òpin ọjọ́ keje.—Jẹ́n. 2:1-3. w23.11 5 ¶13-14