Saturday, October 25
Ṣáfánì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.—2 Kíró. 34:18.
Nígbà tí Ọba Jòsáyà pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26), ó bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà, wọ́n rí “ìwé Òfin tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀ Mósè.” Nígbà tí wọ́n ka ìwé náà fún ọba, ohun tó gbọ́ mú kó ṣe àtúnṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (2 Kíró. 34:14, 19-21) Ṣé ìwọ náà á máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé ò ń gbádùn ẹ̀? Ṣé o máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Nígbà tí Jòsáyà pé ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39), ó ṣe àṣìṣe ńlá kan tó gba ẹ̀mí ẹ̀. Ó gbára lé ara ẹ̀ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (2 Kíró. 35:20-25) Kí nìyẹn kọ́ wa? Kò sí bá a ṣe dàgbà tó tàbí bó ṣe wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Tá a bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣàṣìṣe ńlá tó máa gbẹ̀mí wa bíi ti Jòsáyà, àá sì máa láyọ̀.—Jém. 1:25. w23.09 12-13 ¶15-16
Sunday, October 26
Ọlọ́run dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, àmọ́ ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀.—Jém. 4:6.
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin oníwà rere tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì sìn ín. Wọn kì í ṣe “aláṣejù,” “wọ́n [sì] jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.” (1 Tím. 3:11) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin máa rí àwọn obìnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ìjọ wọn, tí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin, ẹ máa rí àwọn obìnrin rere nínú ìjọ yín tẹ́ ẹ lè fara wé. Ẹ máa kíyè sáwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wo bẹ́ ẹ ṣe lè láwọn ànímọ́ náà. Ó ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni nírẹ̀lẹ̀. Tí obìnrin kan bá nírẹ̀lẹ̀, ó máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà tó sọ pé orí obìnrin ni ọkùnrin. (1 Kọ́r. 11:3) A lè lo ìlànà yìí nínú ìjọ àti nínú ìdílé. w23.12 18-19 ¶3-5
Monday, October 27
Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn.—Éfé. 5:28.
Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kó máa pèsè àwọn nǹkan tó nílò fún un, kó máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ní àròjinlẹ̀, kó o máa bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ọkọ rere. Lẹ́yìn tó o bá láya, ó ṣeé ṣe kó o bímọ. Tó o bá fẹ́ jẹ́ bàbá rere, ẹ̀kọ́ wo lo lè kọ́ lára Jèhófà? (Éfé. 6:4) Jèhófà sọ fún Jésù Ọmọ ẹ̀ ní gbangba pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun sì tẹ́wọ́ gbà á. (Mát. 3:17) Torí náà, tó o bá bímọ, rí i dájú pé gbogbo ìgbà lò ń sọ fáwọn ọmọ ẹ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa, gbóríyìn fún wọn látọkànwá. Àwọn bàbá tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà máa ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí de ojúṣe yìí, bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa fìfẹ́ bójú tó àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé àtàwọn ará ìjọ, kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì mọyì wọn.—Jòh. 15:9. w23.12 28-29 ¶17-18